Báyìí ni ọmọ ṣe máa ń mú 'genotype' lára òbí
Genotype: Kí làwọn àǹfàni àti ewu tí ẹ̀yà jínótáìpù rẹ le mú bá ìgbé ayé rẹ̀
Ọpọ eniyan lo n gbe igbe aye wahala ati aisan, nitori aimọkan tabi aibikita awọn obi wọn lori jinoaipu saaju igbayawo.
Irufẹ igbesẹ bẹẹ tilẹ tun ti fa ipalara fun ọjọ ọla ọmọ wọn.
Saaju ki a to bẹrẹ alaye, ki ni awọn ohun to jẹ mọ mimọ nipa iru ẹjẹ to wa lago ara wa?
N jẹ o mọ pe ki a to dẹnu kọ ololufẹ rẹ pe ko di aya tabi ọkọ rẹ, o ni lati gbe awọn igbesẹ eto ilera to yẹ?.
Eyi lo fa ti awọn dokita onimọ iṣegun fi ma n bere pe ki eeyan se ayẹwo ẹjẹ saaju ki wọn to fi ẹjẹ silẹ fun eeyan to ba nilo rẹ ni ile iwosan.
Ki ni itumọ Genotype?
Sẹ ri Jinotaipu ti a n sọ nipa rẹ yii, ohun lo sapejuwe apapo awọn eroja inu ara to n ṣeto irufẹ ẹjẹ to wa ninu ara onikaluku.
Awọn oloyinbo n pe nnkan ni ‘Gene’ lago ara, to si jẹ pe ohun lo ma gbe awọn isesi kọkan ti eeyan yoo ni lara.
Bi apẹẹrẹ, Iru Awọ Oju, Awọ irun ori tabi boya eeyan yoo ga tabi ko kuru mọlẹ.

Orisirisi Genotype to wa.

Jinotaipu pin si orisirisi, ti wọn si tun pin si ipele lara awọn eeyan.
A ni AA, AS, SS,AC, SC ati CC.
Awọn onimọ sayẹnsi so pe obi onikalu lo ma n da ẹjẹ jọ si ara ọmọ ti wọn ba bi.
Awọn onimọ se agbekalẹ isiro bi apapọ ẹjẹ yii se ma n sọ iru ẹjẹ ‘Jinotaipu’ ti eeyan yo ni lara..
Bi o ko ba mọ iru Jinotaipu rẹ, ko to lọ fẹ iyawo tabi ọkọ, o ṣeeṣe ki ọmọ ti eeyan ba bi jẹ ọmọ foniku fọladide.

Awọn ẹjẹ Genotype wo lo le fẹ ara wọn?
Awọn to ba ni irufẹ ẹjẹ Jinotaipu AA ni anfani lati fẹ iru Jinotaipu to wu wọn nitori ko si aburu nipa ilera nibẹ.
AA ati AA lo dara ju pe ki wọn fẹ ara wọn.
AA ati AS naa ko buru ti wọn ba fẹ ara wọn
AA ati SS naa jẹ ohun ti ko mu ewu kankan dani fun awọn to ba fẹ ara wọn.
AA pẹlu AC tabi CC, iyun naa ko fa ewu dani.
Amọ ewu wa ninu ki awọn Jinotaipu yooku yatọ si AA fẹ ara wọ.
Awọn Jinotaipu bi AS, AC, SS, CC ko le fẹ irufẹ Jinotaipu wọn.
Koda ewu rẹ kọja ohun ti eeyan le salaye lọ.
Fun idi eyi, o ṣe koko ki awọn lọkọlaya, se ayẹwo ẹjẹ ki wọn to damọran igbeyawo.
















