MC Oluomo ṣetán láti fipò alága NURTW Eko sílẹ̀ lẹ́yìn oṣù kan tó wọlé sáà kejì

MC Oluomo

Oríṣun àwòrán, kingmcoluomo/INSTAGRAM

Alága ẹgbẹ́ àwọn ọlọ́kọ̀, NURTW, tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Eko, Alhaji Musiliu Akinsanya tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ sí MC Oluomo ti ní òun ti ṣetán láti fipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alága náà.

Nínú fídíò kan tí MC Oluomo fi sórí Instagram rẹ̀ ló ti kéde ọ̀rọ̀ náà.

Oluomo nínú fídíò náà ní òun ti ṣetán láti fi ipò òun sílẹ̀ fún ẹni tó jẹ́ akápò ẹgbẹ́ àwọn, Mustapha Adekunle tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Sego sì gba ipò náà lẹ́yìn tí òun.

Ó ṣàlàyé pé òun ti ṣetán láti lọ díje sípò ààrẹ àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ NURTW ní èyí tó máa wáyé ní oṣù Kìíní ọdún 2024.

Ó ní kí oṣù Kìíní ọdún 2024 ni Sego máa gba ipò náà lẹ́yìn tí òun bá ti wọlé sípò ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn.

Oluomo

Oríṣun àwòrán, kingmcoluomo/INSTAGRAM

Ní ọjọ́ Àìkú ni MC Oluomo àtàwọn lẹ́nulọ́rọ̀ ẹgbẹ́ NURTW àti ẹ̀ka ètò ìrìnnà ní ìpínlẹ̀ Eko ṣèpàdé pẹ̀lú gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu láti fòpin sí láàsígbó tó ń wáyé láàárín wọn.

Àwọn kan tó wà níbi ìpàdé náà sọ wí pé àwọn kan ló ní kí MC Oluomo lọ díje du ipò náà látàrí pé ààrẹ igun NURTW kan, Tajudeen Agbede ń ṣe àárẹ̀.

Wọ́n ní àìsàn rọpárọsẹ̀ ni ó ń bá Agbede fínra.

Yàtọ̀ sí Sanwo-Olu, olórí òṣìṣẹ́ ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Eko, Tayo Ayinde, Kọmíṣọ́nà fún ètò ìrìnnà ìpínlẹ̀ Eko, Oluwaseun Osiyemi àtàwọn míì ló wà níbi ìpàdé náà.

Níṣe ni ìkùnsínú ti ń wáyé nínú ẹgbẹ́ NURTW ìpínlẹ̀ Eko láti bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn nígbà tí àwọn kan ní àwọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú Oluomo mọ́ gẹ́gẹ́ bí alága wọn lẹ́yìn tó wọlé fún sáà kejì.

Wọ́n ní Oluomo gbà láti fipò rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn èèkàn kan ní ìpínlẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ náà pé kó fi ipò rẹ̀ sílẹ̀.

Ìròyìn ní ọ̀pọ̀ àwọn alága ní ẹkùn káàkiri ni kò ti san owó tí wọ́n ń pa sápò ẹgbẹ́ fún Oluomo mọ́.

Ẹ ó rántí pé ní nǹkan bíi oṣù mẹ́rin ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Oluomo padà sínú ẹgbẹ́ NURTW lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣáájú fòfin dè é lórí ẹ̀sùn pé ó fẹ́ jẹ alága ẹgbẹ́ NURTW ní gbogbo ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà.