Wo ọjọ́ tí Lent àti Ramadan yóò bẹ̀rẹ̀ àti àwọn ọjọ́ ìsìnmi tí ìjọba yóò kéde lọ́dún 2024

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Baa ṣe n wọ inu ọdun 2024 wẹrẹ wẹrẹ ki a maa fi to yin leti pe awọn ọjọ ìsinmi kan wa ti ọmọ Naijiria yoo jẹ anfaani rẹ.
Yatọ si awọn eleyi ti ijọba yoo kede awọn miiran wa to ṣe pe ikede kankan ko ni waye lori wọn sugbọn awọn eeyan yoo ṣami wọn tori pe ọjọ pataki ṣi ni wọn jẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ọjọ pataki ti ijọba yoo kede wọn lọjọ isinmi ree:

Oríṣun àwòrán, Getty Images
January 1
Ọjọ Aje tii ṣe ọjọ kinni inu ọdun 2024 jẹ ọjọ isinmi.Ohun ni wọn fi ṣami iṣipo kuro ninu ọdun 2023 to pari si ọdun 2024.
March 29
Lọdun 2024 yii, ayajọ Good Friday bọ si ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣù Kẹta.
Isinmi fun awọn ọmọ lẹyin Kristi lọjọ yi jẹ.
Wọn fi ṣe isami kikan Jesu sori agbelebu ati iku rẹ lori oke Calvary.
April 1
Easter Monday
Ayajọ ọdun yi bọ si ọjọ kinni, oṣu Kẹrin.
O si jẹ ọjọ keji Ajinde ti ọpọ orileede lagbayema n ṣami rẹ pẹlu isinmi l'ẹnu iṣẹ.
April 10
Ojọru ni ọjọ yi bọ si ni 2024 to si ṣe e ṣe ko jẹ ọjọ ayajọ ọdun Eid il fitr.
Ijọba a maa kede ọjọ yi ni ọjọ isinmi kete ti wọn ba ti ri oṣu oju ọrun ti oṣu Shaban.
April 11
Ọjọbọ tii ṣe ọjọ Kọkànlá oṣù Kẹrin ṣeeṣe ko jẹ ọjọ keji ọdun Eid il Fitr.
Ọjọ isinmi naa ni ọjọ yi yoo jẹ ti ijọba ba kede rẹ.
May 1
Ọjọ kinni, oṣu Karun-un lagbaye jẹ ayajọ awọn oṣiṣẹ taa mọ si International Workers Day.
Ijọba maa n kede ọjọ yii fun awọn oṣiṣẹ lati fi sinmi.
Wọn a maa fi ọjọ yi ṣe imọriri pataki igbiyanju awọn oṣiṣẹ lagbaye.
June 12
Democracy Day
Ayajọ ijọba awaarawa lọjọ yii jẹ ni Naijiria.
Wọn a maa fi ṣe iranti bi Naijiria ṣe bọ kuro labẹ ijọba ologun si ijọba awaarawa lọdun 1999.
June 17
Id el Adha
Ayajọ ọdun Musulumi yii le bọ si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfà.
Oṣù oju ọrun ni wọn fi n ka ọjọ ọdun yi.
Sibẹ sibẹ ìjọba Naijiria yoo kede ọjọ yi ni ọjọ isinmi fawọn Musulumi lati ṣami ọdun Ileya.
June 18
Ọjọ Iṣẹgun ọjọ Kejidinlogun oṣù kẹfà yii naa le jẹ ọjọ keji isami ọdun Ileya.
Isinmi yoo wa lọjọ yi.
September 16
Ni ọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan-an, ijọba yoo kede isinmi ayajọ Id el Maulud, ti awọn Musulumi kan a máà fi ṣe ayajọ ọjọ ibi Anọbi Muhammad.
October 1
Ayajọ ominira Naijiria bọ si ọjọ Iṣẹgun oṣu Kẹwa ọdun 2024.
Ijọba Naijiria a si ma fun araalu ni isinmi isami ọjọ yii.
Pataki ọjọ naa wa ninu ṣiṣe iranti bi Naijiria ṣe bọ kuro lọwọ ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi lọdun 1960.
December 25
Ọjọ yi ni ayajọ ọdun Keresimesi to sì jẹ ọjọ ìsinmi lẹnu iṣẹ ni isami ayajọ ọjọ ibi Jesu Kristi fawọn Kristẹni.
December 26
Boxing Day jẹ isinmi, ọjọ keji ọdun Keresimesi.
Awọn ọjọ mi ti ijọba ko kede ni isinmi ṣugbọn ti awọn araalu a maa ya si ọtọ.
February 14
Ọjọru ni ọjọ kẹrinla, oṣu Keji bọ si ni 2024.
Ayajọ ololufẹ ni wọn mọ ọjọ yi si.
Ijọba kii kede rẹ amọ araalu a maa kopa ninu eto isami ayajọ naa lọwọ arawọn.
Ọjọ Kẹrinla yi naa tun jẹ ayajọ Ash Wednesday.
Awọn Kristẹni yoo ṣe ayajọ ọjọ yii lati fi ṣami ibẹrẹ awẹ lẹnti ọdun 2024.
March 8
Lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ni ayajọ awọn obinrin lagbaye International Women Day.
Kii sí ọjọ isinmi lọjọ yii, amọ lagbaye awọn eeyan ma n lo o lati ṣe afihan awọn àṣeyọrí obìnrin lagbaye.
March 11
Oṣù Ramadan le bẹrẹ lọjọ yi ni ibamu pẹlu ẹsin Islaamu.
Ọjọ naa ṣe pataki nitori pe o tọka si ọjọ akọkọ ti ooṣu Ramadan ti awẹ ti n waye yoo bẹrẹ.
A ko le sọ ni pato pe awẹ yoo bẹrẹ ni ọjọ yii, nitori pe igbimọ to n mojuto ọrọ ẹsin Islaamu lo maa n kede ọjọ ti awẹ yoo bẹrẹ.
O le jẹ ọjọ yi tabi ọjọ miran.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
May 27
Children's Day
Ọjọ kẹtadinlogbon ni awọn ọmọde ma fi n ṣe ayajọ ti wọn naa ni agbaye, eyi ti ko yọ Naijiria silẹ.
Ijọba kii kede isinmi lati fi ṣami ọjọ yii, amọ wọn mọ riri pataki ọrọ ọmọde gẹgẹ bo ṣe ri l'awọn orileede mii lagbaye.















