Èèyàn márùn ùn pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú ní Japan

Oríṣun àwòrán, Reuters
Eeyan marun-un ti ku ninu ijamba ọkọ ofurufu to waye ni orilẹ-ede Japan lọjọ Iṣẹgun, ọjọ keji, oṣu Kinni, ọdun 2024.
Iroyin sọ pe baalu meji lo fi ori sọ ara wọn nigba ti wọn fẹ ẹ balẹ - baalu ero ati ti awọn ẹṣọ alaabo ori omi.
Igbagbo ni pe ọkọ ofurufu kekere kan to jẹ ti awọn ọmọ ogun to n sọ ibode ori ọmi n ṣeto lati gbe ounjẹ lọ s'awọn agbegbe ti ilẹ riri ti sakoba ni lasiko to kọlù baalu akero kan ti ileeṣẹ ọkọ ofurufu Japan Airlines naa bo ṣe n balẹ sori papa.
Gbogbo eeyan to wa ninu ọkọ ofurufu akero to kọlù ni wọn ribi moribọ.
Ileeṣẹ ọkọ ofurufu Japan Airlines so pe eeyan 379 lo ribi sa asala fun ẹmi wọn.
Lẹyìn ti wọn ribi sa kuro ni ọkọ ofurufu naa gbina,to si jo raurau.
O s'oju mi koro salaye fun BBC
Arinrinajo kan Josh Coultas Tones ni papakọ ofurufu Haneda Airport ti ijamba yi ti ṣẹlẹ ṣapejuwe bi ìṣẹlẹ naa ṣe ri lọkan rẹ nigba to gburo nkan to ṣẹlẹ.
O sọ fun BBC pe " nkan to d'ẹru ba eeyan ní bá ṣe n wo ti gbogbo papakọ ofurufu pa lọọlọ"
O ni ọrẹ oun loun duro de ni papakọ ofurufu to n ba baalu mii bọ wa si papakọ ofurufu Haneda.
" O jẹ nkan to dun mi, nitori pe o ṣeeṣe ki ọrẹ mi ba ọkọ ofurufu yi de ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ."
"Gbogbo irinna wọlé jade ọkọ ofurufu si papakọ ofurufu yii ni wọn ti wọgile bayii. Mi o ro pe yóò ribi de lonii."
O fí kun pe "pẹlu ilẹ riri ati Tsunami ati ijamba baalu, fihan pe ibẹru bojo ni 2024 fi bẹrẹ ni Japan"
Olootu ìjọba ni ki wọn yara ṣe iwadii ipa ijamba to waye
Olootu ijọba ni Japan, Fumjo Kushida sọ loju opo X (Twitter) rẹ pe oun fẹ ki awọn alaṣẹ ti ọrọ kan tete jabọ fún oun lori ipa ti ijamba to waye, ni.
O ni ọfisi oun "yoo sapa lati ri pe awọn fi iroyin to peye to araalu leti lori ijamba to waye yii "












