'Àwọn agbébọn n gbà tó 300,000 owó orí lọ́wọ́ wa nípìnlẹ̀ Niger'

Awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn olugbe ni awọn agbegbe kan nipinlẹ Niger ṣi n sa kuro ni ile wọn, nitori ibẹru awọn janduku agbebọn to n beere owo ori lọwọ wọn.

Iroyin to tẹ BBC lọwọ fihan pe awọn ilu bii Dagon-dawa, Kurigi, Kangerawa, Mangoro, ati awọn miran ni ọrọ naa kan.

Awọn eeyan kan ni awọn ilu naa sọ fun BBC pe awọn agbebọn ọhun n fi ipa mu awọn lati san owo ori lori ounjẹ, igboke-gbodo ọkọ ati awọn nnkan ere oko wọn.

Ẹnikan ti n gbe ni ilu Dogon Dawa, ṣugbọn ti a fi orukọ bo ni aṣiri sọ pe awọn atipo gbọdọ sanwo fun awọn agbebọn ki wọn o to le kuro niluu.

“Ọrọ naa ti buru pupọ debi pe awọn to wa ni ibudo ogunlende paapaa n san owo ori ki wọn o to le fi awọn ibudo naa silẹ.”

O ni awọn onikupani ẹda naa ti sọ awọn ilu ọhun di ti wọn, ti wọn si n ba iṣẹ wọn lọ lai si ibẹru.

Diẹ lara awọn araalu sọ fun BBC pe owo ti awọn agbebọn ma n beere lọwọ ọkọ to ba ko awọn to n kuro niluu wa laarin ẹgbẹrun lọna igba si ọọdunrun Naira. Nigba miran, wọn ma n ko ọkọ mẹta pọ, ti wọn o si beere miliọnu kan Naira lọwọ wọn.

“Ni ọjọ Aiku to kọja, miliọnu mẹta aabọ Naira ni a ko ranṣẹ si wọn, lati gba itusilẹ awọn ọkọ kan to ko dukia awọn eeyan. Idi ni pe awọn agbebọn naa sọ pe wọn ko ni i kọja, lai san owo naa.”

Ẹlomiran tun sọ fun BBC pe “ọkọ mọkandinlọgbọn to ko ounjẹ ati ire oko, ni wọn da duro ti wọn si n beere ẹgbẹrun lọna igba Naira lori ikọọkan wọn - a si fun wọn.”

BBC gbiyanju lati ba awọn alaṣẹ nipinlẹ Niger sọrọ, ṣugbọn ko so eso rere.