A ń fi dáa yín lójú pé àwọn jàndùkú kò ní rí agbègbè kan gbà l'ọ́dún 2024- Iléeṣẹ́ ológun

Oríṣun àwòrán, Others
Olori awọn osisẹ ẹsọ alabo, Ọgagun Christopher Musa ni oun yoo ri pe oun le awọn janduku kuro ni agbegbe to n koju idojukọ awọn janduku lorilẹede Naijiria.
O seleri yii nigba to n ba Ileeṣẹ iroyin Channel TV sọrọ lonii ọjọ kinni oṣu kinni ọdun 2024
O rọ awọn araalu lati dide iranlọwọ fun wọn lati koju awọn janduku yii.
Bẹẹ ba gbagbe ọpọ eeyan lo dero ọọrun lẹyin ti awọn janduku kan se ikọlu si agbegbe kan nipinlẹ Plateau.
“A n sisẹ pọ pẹlu awọn ijọba ipinlẹ lati mọ awọn agbegbe ti awọn ikọlu yii ti n waye,
"Lọdun yii pẹlu aṣẹ Ọlọrun, a ri pe awọn janduku ko ni anfani lati gba agbegbe kankan”.
Omije ati ibanujẹ ọkan bale ọpọ ọmọ Naijiria ni Keresimesi ku ọla nipinlẹ Plateau nigba ti awọn janduku kan yabo ijọba ibilẹ Bokkos ati Barkin Ladi, ti wọn si sekupa ọpọ awọn eeyan ni agbegbe naa, ti awọn mii si farapa yanayana.
Ko pẹ ni awọn agbebọn tun ya bo agbegbe mii ti wọn situn sekupa Baba ati Ọmọ rẹ ọkunrin
Ọgagun Musa ni gbogbo igbiyanju awọn janduku yii fi iwọsi lọ ijọba ko le da bi pe wọn ko mọ se.
“Mo ro pe idi ti awọn janduku fi n se nnkan yii ni lati sọ ijóba di omugọ, ẹnikẹni to lọwọ ninu isẹlẹ gbọdọ mọ pe ọwọ wa ko ni pẹ tẹ nibi ti sa si.
“A ko le wa nibi gbogbo, ibi ti isẹlẹ naa ti waye ki i se agbegbe kekere.”















