Gbogbo ogun tó bá dìde sí ọ ní 2024 yóò di iyẹ̀pẹ̀ - Oluwo ti Iwo

Àkọlé fídíò,
Gbogbo ogun tó bá dìde sí ọ ní 2024 yóò di iyẹ̀pẹ̀ - Oluwo ti Iwo

Oluwo ti Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi, ti fi aṣẹ ọba wure fun gbogbo ọmọ Naijiria.

Ninu iwure ọdun tuntun ti Oba Akanbi, Telu I, ṣe pẹlu BBC, lo ti gbadura pe gbogbo aini, oṣi, adanu, aleeba ati airaanu gba yoo lọ si okun igbagbe ninu aye gbogbo eeyan.

Kabiesi gbadura pe ọdun ayọ ni 2024 yoo jẹ fun gbogbo ọmọ Naijiria.

“Gbogbo ogun to ba dide si ọ niwaju, ni yoo di iyẹpẹ.”

Bakan naa lo wure pe wn ko ni i ri ọ sunkun.

Ẹwẹ, Oba Akanbi gbadura pe ki orilẹ-ede Naijiria di awokọṣe rere, ati pe ki Ọlọrun fun Aarẹ Bola Tinubu ni ọgbọn ti yoo fi gbe Naijiria goke agba.