Awọn amúgbálẹ̀gbẹ́ Mohbad wọ́ Bàbá rẹ̀ lọ iléẹjọ́ fún ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́

Aworan Ilerioluwa Aloba ati Joseph Aloba

Oríṣun àwòrán, BBC/OTHERS

Awọn amugbalẹgbẹẹ gbajugbaja olorin takasufe to di oloogbe lọdun to kọja, Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad ti wọ Baba akọrin takasufe naa, Joseph Aloba lọ si Ileẹjọ fun ẹsun ibanilorukọjẹ, ti wọn si n bere fun igba milọnu naira.

Ni bi ọsẹ diẹ sẹyin ni Baba Mohbad sọ sita nigba to n kopa ninu ifọrọwerọ kan pe ọmọ oun ni akọsilẹ awọn dukia rẹ silẹ ko to di pe o jade laye.

Mohbad, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, di oloogbe ninu oṣu kẹsan an ọdun 2023, ti rẹ si da ọpọlọpọ ariwo silẹ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ninu atẹjade ti awọn amugbalẹgbẹ Mohbad fi sita lati tako ọrọ ti Joseph Aloba sọ, wọn jẹ ko di mimọ pe awọn ko fi igba kankan kede sita pe Mohbad ni akọsilẹ dukia tabi iwe akọsilẹ ogun kankan.

Wọn si rọ Baba oloogbe naa lati jina si awọn iroyin ofege ti o le ṣi araalu lọna.

Bakan naa ni wọn tun fi iwe ẹjọ ransẹ si Baba Mohbad pe ko kede sita pe oun kọ sọ bẹ tabi ko san owo to to igba milọnu naira.

Ninu iwe ti wọn fi pe ẹjọ naa, awọn alakoso naa salaye pe ko si ẹnikẹni to sọ ohunkohun nipa akọsilẹ dukia fun Baba Mohbad, ati pe n ṣe lo sọrọ naa sita lati si awọn ọmọ Naijiria lọna.

Awọn amúgbálẹ̀gbẹ̀ẹ́ Mohbad sọ̀rọ̀ lórí ìwádìí ikú àti ogún rẹ̀

Mohbad

Oríṣun àwòrán, @iammohbad

Awọn amugbalẹgbẹ olorin takasufẹ to di oloogbe, Mohbad, ti sọrọ lori lori ayẹwo iku rẹ ati lori ọrọ ogun rẹ to n lọ nigboro.

Lati igba ti ọdọkunrin naa ti jade laye ni ọpọ araalu atawọn ololufẹ rẹ ti n reti iroyin nipa ibi ti ọlọpa ba iṣẹ de.

Ọjọ kejila, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 ni Mohbad jade laye, iroyin iku rẹ si migboro titi, paapaa laarin awọn ọdọ atawọn ololufẹ rẹ.

Lẹyin iku Mohbad ni awọn eeyan n sọ pe iṣẹlẹ naa lọwọ eeyan ninu, eyii to mu ki awọn eeyan kan bii Naira Marley, Sam Larry, nọọsi to tọju rẹ, atawọn afurasi mii dero atimọle.

Ṣe lootọ ni Mohbad ti ṣeto ogun rẹ ko to jade laye?

Mohbad

Oríṣun àwòrán, Mohbad

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bii ohun ti awọn amugbalẹgbẹ naa sọ, awọn ko mọ nnkankan nipa ogun Mohbad nitori agbẹjọro rẹ ko mẹnuba ọrọ ogun kankan.

Awọn amugbalẹgbẹ oloogbe ọhun lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan loju po X rẹ.

Atẹjade naa ni “O ti to oṣu diẹ ti Mohbad ti lọ amọ bii ana lo ri loju wa.

“A mọ̀ pe ko si ohunkohun to le da pada saye mọ ṣugbọn a ti fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro lati ṣe ọfintoto bi iṣẹlẹ naa ṣe jẹ... A fẹ lo akoko yii lati sọ awọn ododo kan lati kapa awọn iroyin ofege to n lọ nigboro.

Wọn ni awọn ọlọpaa ti pari ayẹwo oku Mohbad, ṣugbọn yoo to oṣu diẹ ki wọn to kede esi ayẹwo ọhun, eyii ti wọn fi ṣọwọ soke okun.

Atẹjade naa tẹsiweaju pe “Ko si eyikeyi ninu awọn alabaṣiṣẹ Mohbad tabi agbẹjọro rẹ to sọrọ nipa ogun (gẹgẹ bii iroyin ẹlẹjẹ ti awọn kan gbe kiri) fun awọn mọlẹbi rẹ tabi araalu.

“A fẹ rọ awọn eeyan ki wọn dẹkun ati maa gbe iroyin ẹlẹjẹ nipa ogun Mohbad kiri.

Wọn pari atẹjade naa pe wọn ti gbe agadagodo si ẹnu apo iṣuna oloogbe naa lati ọjọ to ti jade laye titi di akoko yii, eyii ti awọn yoo fi iṣakoso rẹ fun awọn mọlẹbi rẹ lẹyin abajade iwadii awọn agbofinro.