Ìjàmbá iná ṣọṣẹ́ ní Ilọrin, omi ọkọ̀ panápaná tán, ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò

Ńṣe ni àwọn ènìyàn agbolé ilé Maigida ní àdúgbò Edun, ìlú Ilorin, ìpínlẹ̀ Kwara wà nínú ìbànújẹ́ báyìí látàrí ìjàmbá iná tó ṣọṣẹ́ ní agbolé náà.
Nígbà tí ikọ̀ ìròyìn BBC kàn sí agbolé náà ní nǹkan bíi aago mọ́kànlá kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n níṣe ni iná náà ń jò fitafita.
Gbogbo ìgbìyànjú àwọn òṣìṣẹ́ panápaná láti pa iná ọ̀hún ló já sí pàbó, tí omi inú ọkọ̀ ńlá méjì tí wọ́n gbé dé ibi ìjàmbá náà tán pátápátá láì rí iná náà pa.
Lẹ́yìn tí omi ọkọ̀ méjéèjì ọ̀hún tán náà ni àwọn ará àdúgbò náà bẹ̀rẹ̀ sí ni gbìyànjú agbára wọn kí òṣìṣẹ́ panápaná tó tún padà lọ gbé omi mìíràn láti fi dojú kọ iná náà.
Àwọn ó ṣojú mi kòró ṣàlàyé pé àwọn kò lè sọ ohun tó ṣokùnfà ìjàmbá náà ní pàtó.

Wọ́n ní ohun tí àwọn kọ́kọ́ rí ni pé èéfí ń yọ ní agbolé nínú agbolé Maigida ṣùgbọ́n àwọn rò wí pé bóyá àwọn kan ló kàn ń sun ilẹ̀.
Wọ́n ní nígbà tó yà ni àwọn ri pé iná ló ń jó tó sì ti gba ilẹ̀ kan tí gbogbo ìgbìyànjú àwọn láti pa iná ọ̀hún já sí pàbó.
Wọ́n ní èyí ló mú kí àwọn sáré pe àwọn òṣìṣẹ́ panápaná.

Wọ́n ṣàlàyé gbogbo àwọn ènìyàn, tó fi mọ́ àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ilé ọ̀hún ni wọ́n rí gbé jáde àti pé kò sí ẹnikẹ́ni tó farapa nínú ìjàmbá náà.
Àmọ́ wọ́n ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá olówó iyébiyé ló sọnú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná náà.
Ìjàmbá iná ọ̀hún tún ṣàkóbá fún àwọn ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta àwọn àga, pákó, ilẹ̀kùn àtàwọn nǹkan míì ni agbègbè náà.
Mọ́ṣáláṣì tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilé ọ̀hún náà jóná gidi.






