Ọmọ Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dáwó 'Crowdfunding' fún ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọbìnrin márùn ún táwọn agbébn jí gbé l’Abuja

Aworan baba atawọn ọmọ rẹ ti wọn ji gbe lọ

Oríṣun àwòrán, SHERIFFDEEN AL-KADRIYAR

Awọ ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si ni da owo lati doola awọn ọmọ tawọn ajinigbe gbe lọ niluu Abuja.

Lopin ọsẹ to kọja ni iroyin jade pe awọn ajinigbe gbe baba ati ẹbi rẹ eleyii ti ọmọ mẹfa wa nibẹ.

Ọrọ bẹyin yọ nigba ti awọn ajinigbe ọhun ṣekepa ọkan lara awọn naa tori ai ri owo gọbọi tawọn ajinigbe n beere san.

Ṣaaju ni iroyin fidi rẹ mulẹ pe awọn ajinigbe yabo ile ọkunrin naa lagbegbe Bwari l’Abuja lọjọ keji ọdun tuntun 2024 yii nibi ti wọn gbe ọkunrin kan atai ọmọ rẹ mẹfa lọ.

Ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu owo naira ni wọn sọ pe awọn yoo gba kawọn to tu wọn silẹ.

Eyi gan an lo jẹ kawọn ajinigbe naa fi baba silẹ ki o le wa owo lọ fun itusilẹ awọn ọmọ rẹ.

Airowo ọkunrin yii lo jẹ ki ọpọ eeyan lori ayelujara bẹrẹ si ni beere fun iranwọ owo fun baba awọn ọmọ yii ki awọn ajinigbe ba le fun awọn ọmọ rẹ toku ni ominira.

Lara awọn to dasi ọrọ naa lori ayelujara ni minisita eto ibaraẹnisọrọ tẹlẹ, Ọmọwe Ali Pantami.

Ọmọwe Pantami kede pe buọda oun ati ọrẹ oun kan gbe adọta miliọnu kalẹ fun itusilẹ awọn ọmọ naa.

Ninu ọrọ rẹ, Pantami ni ‘’emi gẹgẹ bi ẹnikan n ko faramọ sisan owo fawọn janduku ajinigbe fun itusilẹ awọn eeyan ti wọn ba jigbe.

Amọ, o ti han gbangba bayii bayii pe wọn ṣekupa ọmọdebinrin Nabeeha lanaa, wọn si maa pa awọn ọmọ marun un toku gẹgẹ bi baba ṣe sọ fun mi nigba ti mo ba a sọrọ.’’

Gbigba owo fun itusilẹ awọn eeyan ti wọn jigbe kii ṣe tuntun ni Naijiria papaa julọ lẹkun iwọ oorun ariwa atawọn apakan orilẹede Naijiria.

Amọ, iṣẹlẹ ijinigbe ko saba wọ pọ niluu Abuja ti i ṣe olu ilu Naijiria.

Ọpọ awọn akọṣẹmọṣẹ nipa ọrọ eto abo ni wọn ti kọminu lori iṣẹlẹ ijinigbe to n ṣẹlẹ ni lemọlẹmọ l’Abuja bayii.

Àwọn ajínigbé pa ọ̀kan nínú ọmọ bàbá mẹ́fa tí wọ́n jí gbé l’Abuja

Awon ajinigbe

Ọmọbinrin akẹkọọ onipele kẹrin ni Yunifasiti Ahmadu Bello (ABU), ti wọn pe orukọ ẹ ni Najeebah, ni awọn ajinigbe ti pa bayii laarin awọn aburo rẹ marun-un ti wọn jọ ji wọn gbe pẹlu baba wọn l’Abuja.

Ọjọ kẹsan-an oṣu kin-in-ni ọdun 2024 yii ni wọn ji wọn gbe.

Ẹka iroyin abẹle Punch to fi iroyin naa lede, ṣalaye pe awọn ajinigbe ọhun pada fi baba awọn ọmọ naa silẹ, wọn ni ko lọọ wa ọgọta miliọnu naira (60m) wa kawọn too le yọnda awọn ọmọ rẹ mẹfẹẹfa.

‘Wọn ke gbajare iranlọwọ owo fawọn ọmọ Naijiria, ṣugbọn owo ti wọn ri ko to nnkan’

Awọn ẹbi ti wọn ji lọmọ mẹfa gbe yii ke gbajare iranlọwọ owo fawọn ọmọ Naijiria, kowo naa le pe, ṣugbọn owo ti wọn ri ko to nnkan.

Nigba ti yoo fi di ọjọ kẹta ti wọn ti n wa owo naa, awọn ajinigbe pa Najeebah, iyẹn lọjọ kejila oṣu kin-in-ni yii, wọn si ju oku rẹ sẹba ọna ti baba rẹ yoo ti ri i lati gbe e sin.

Ṣaaju lawọn ọlọpaa ti gbọ si iṣẹlẹ ijinigbe yii, ti Alukoro wọn ni Naijiria, Ọmọọba Muyiwa Adejọbi si ti ni awọn ni lati ba awọn ẹbi tọrọ naa kan sọrọ labẹnu, yatọ si ti ori ayeluja.

Adejọbi sọ pe awọn ti n ṣiṣẹ lori ẹ, kawọn ọmọbinrin naa le gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe.

Ẹnikan torukọ ẹ jẹ @Adamu _Asiya, ti wọn ni mọlẹbi awọn Najeebah ni, sọ lori ikanni X, pe ọgọrun-un kan miliọnu (100m) lawọn ajinigbe naa n beere bayii.

O ni wọn pa Najeebah ko le jẹ ikilọ fun baba rẹ lati tete mowo naa wa ni.

Titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii, awọn ọmọbinrin marun-un yooku ṣi wa nigbekun awọn agbebọn to ji wọn gbe