Wọ́n lu Báyọ̀ pa nítorí ìyàwó ẹ̀ nípìnlẹ́ Ògùn

Oríṣun àwòrán, Platform Times
Ọjọ karun-un, oṣu kin-in-ni, ọdun 2024 yii ni iku ojiji pa ọmọkunrin kan, Bayọ Ibikunle, ẹni ọdun mejilelogun (22), lẹyin to ka iyawo rẹ, Christiana mọ ọdọ ale, l’Abule Ajipatutu, nijọba ibilẹ Ewekoro, ipinlẹ Ogun, ti ale naa atawọn ikọ rẹ si lu ọkọ iyawo pa.
SP Ọmọlọla Odutọla, Alukoro ọlọpaa Ogun to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ṣalaye pe ayẹyẹ ọdun tuntun lo n waye lọjọ naa labule Ajipatutu, nibi ti Adebayọ n gbe pẹlu iyawo rẹ.
Odutọla sọ pe lojiji ni Bayọ ko ri iyawo re mọ loju agbo, to si bẹre si i wa a kiri.
Ile kẹta sibi ti wọn n gbe ni Bayọ ti pada ri iyawo rẹ, ẹnikan ti wọn n pe ni Wasiu,ọrẹ ẹgbọn iyawo naa lo si n ba a lo pọ lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Platform Times
Ọkọ iyawo binu, ija ṣẹlẹ
Gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe fidi ẹ mulẹ, ọkọ to ka iyawo rẹ mọdọ ale yii binu, o si bẹrẹ si i ba Wasiu ja, o ṣe e leṣe pẹlu.
SP Odutọla sọ pe, ‘’ Wasiu sa jade ninu yara naa lẹyin ti Bayọ ṣe e leṣe, o si lọọ ko awọn kan jọ ti wọn jọ dena de Bayọ ninu igbo.
‘’Wọn le e wọnu igbo lọ, wọn fi igi oriṣiiriṣii lu u, wọn gba a lẹṣẹẹ, wọn wọ ọ nilẹ titi to fi ku mọ wọn lọwọ.
‘’Aṣọ rẹ ti wọn faya mọ ọn lara paapaa, wọn ko o lọ ni.’’
Awọn eeyan Bayọ pada gbe e lọ sileewosan ijọba to wa niluu Ifọ lẹyin ikọlu naa, ṣugbọn dokita sọ pe o ti ku.
Ọwọ ti ba awọn to lu Bayọ pa
Yatọ si Wasiu, awọn mi-in ti wọn tun darukọ pe wọn lọwọ ninu ikọlu to pa Bayọ ni
Solomon Olukunle ati Dọtun Olukunle, ọwọ ofin si ti ba wọn bawọn ọlọpaa ṣe sọ.
Gbogbo igi ti wọn fi na oloogbe lawọn ọlọpaa ti ko sọdọ gẹgẹ bi ẹri, Christiana ti ọkọ tori rẹ ku naa ko si ṣai foju kan gbaga.












