Gbogbo àwọn èrò láti ba orúkọ mi jẹ́ yóò já sí asán - Betta Edu

Oríṣun àwòrán, Twitter/Betta Edu
Minisita fun eto iboju-aanu-woni, Dokita Betta Edu ti ni gbogbo ero lati ba orúkọ oun jẹ lawujọ ko ni wa si imusẹ.
Ọrọ yii lo jade lẹyin ti iwe lu sori ayelujara eyi to safihan bi Minisita ṣe dari pe ki olusiro owo agba Naijiria san owo ₦585.189m si akoto owo Bridget Mojisola Oniyelu kan.
Àṣẹ lati san owo yii lo jade ninu iwe kan to lu ayelujara, eyi to ni iwe naa jade ni Ogunjọ oṣu Kejila ọdun 2023.
Nigba to lori opo ayelujara X rẹ, Edu ni oun ko mọ nnkan nípa rẹ.
"Ṣíṣe isẹ ni ilana to ba ofin ni mo n fi darí ẹka ìjọba fun eto iboju-aanu-woni, ko si ẹnikẹni ti yoo kowo ìjọba jẹ bí ti tẹlẹ mọ.
"Gbogbo ero lati ba orukọ mi jẹ ati isejọba yii yoo jasi asan."
Ohun tí a mọ̀ lórí ìdí tí àwọn kan fi ní kí Ààrẹ Tinubu yọ Mínísítà Betta Edu nípò rèé

Oríṣun àwòrán, Others
Iléeṣẹ́ Ààrẹ Nàìjíríà ni àwọn tí bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí bí wọ́n ṣe fi akoto owó aládàni gba owó ₦585.189m tó jẹ́ owó ìrànwọ́ tó wà fún àwọn ènìyàn kan ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom, Cross River, Ogun àti Eko.
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn àjọ kan ti ń sọ fún ìjọba àpapọ̀ láti gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Mínísítà tó ń rí sí ètò ìbòjú-àánú-woni àti pípa òṣì rẹ́, Dókítà Betta Edu fẹ́sùn pé ó buwọ́lu sísan owó ètò náà sí akoto aládàni.
Àwọn àjọ náà ní kò yẹ kí Ààrẹ fi ààyè gba irú ìwà báyìí, pé níṣe ló yẹ kí Tinubu yọ ọ́ nípò, kó sì lọ wí tẹnu rẹ̀ níwájú àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu ìyẹn EFCC.
Olùdámọ̀ràn Tinubu lórí ètò ìròyìn àti ọgbọ́n inú, Bayo Onanuga sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn Daily Trust pé ìwádìí ti ń lọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí iléeṣẹ́ náà fi síta lọ́jọ́ Àìkú.
Onanuga ní àwọn máa gbé ìgbésẹ̀ tó tọ́ ní kété tí àwọn bá ti parí ìwádìí àwọn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ṣáájú ni ìwé kan ti lu sórí ayélujára èyí tó ṣàfihàn bí Mínísítà náà ṣe dárí pé kí olùṣirò owó àgbà Nàìjíríà san owó ₦585.189m sí akoto owó Bridget Mojisola Oniyelu kan.
Ìwé náà ṣàfihàn pé wọ́n san owó náà sí akoto owó Oniyelu.
Mínísítà Betta Edu nínú àtẹ̀jáde kan tí agbenusọ rẹ̀, Rasheed Zubair fi léde lọ́jọ́ Ẹtì ní owó náà tẹ̀lé gbogbo ìlànà tó yẹ kí wọ́n tó san án sí akoto owó aládàni.
Zubair nínú àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé ìdí tí Mínísítà fi ní kí wọ́n san owó náà sí akoto Oniyelu ni pé òun ni olùṣirò owó fún ètò pínpín owó ọ̀hún fún àwọn ènìyàn tí kò rí já jẹ tí wọ́n fẹ́ san owó náà fún.
Ó ṣàlàyé pé ohun tó tọ̀nà lábẹ́ òfin ni fún òṣìṣẹ́ ìjọba láti gba owó fi ṣe ohun tó bá fẹ́ fi ṣe kí wọ́n sì kó ìwé ẹ̀rí máa jẹ́ mi ǹ ṣó padà lẹ́yìn tí wọ́n bá parí ètò wọn.
Ọ̀pọ̀ àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ni wọ́n ti ń pè fún gbígbé ìgbìmọ̀ tí yóò ṣèwádìí Betta Edu dìde lórí ẹ̀sùn náà.
Wọ́n ní sísan irú ọ̀bítíbitì owó bẹ́ẹ̀ tó wà fún ará ìlú sí akoto owó aládàni jẹ́ ìwà àjẹbánu nítorí ó lòdì sí òfin ìwà àjẹbánu Nàìjíríà.
Bákan náà ni wọ́n ní àtẹ̀jáde tí iléeṣẹ́ olùṣirò owó àgbà Nàìjíríà gbé jáde pé àwọn kìlọ̀ fún lórí ìgbésẹ̀ náà tó fún EFCC láti fi ṣe ìwádìí Betta Edu.















