Pásítọ̀ kó sí gbaga ọlọ́pàá l'Ogun lórí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ pẹ̀lú ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ pasitọ kan ọmọ ọdun mẹtalelogoji, Clinton John lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹrindilogun lopọ ni agbegbe Agbado nipinlẹ naa.
Ọgbẹni John ti a gbọ pe oun ni pasitọ ìjọ Mega Healing Ministry ni wọn fẹsun kan wi pe o fipa ba omobinrin naa lopọ loṣu Kọkanla ọdun 2022.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Omolola Odutola ni awọn ọlọpaa mu okunrin naa lẹyin ti ẹbi kan lati agbegbe Giwa Agbado mu ẹsun naa wa si àgọ ọlọpaa.
"Ẹbi naa sọ pe orisiirisii arun kokoro ni omobìnrin awọn ti n gba itọju fun eleyii to jẹ ki wọn fura pe o ṣeeṣe ki ẹnikan ti ni Ibalopọ pẹlu rẹ.
Amọ, ọmọbinrin yii kò fẹ sọ ẹni to ni Ibalopọ pẹlu rẹ fawọn obi rẹ.
Ṣugbọn nigba ti wọn tẹ ẹ ninu daadaa ni o jẹwọ wi pe John ni o ni Ibalopọ pẹlu oun.
O ni pasitọ naa ti n ni ibalopọ pẹlu oun fun ọpọ igba lati oṣu Kọkanla ọdun 2022.
Ọmọbinrin yii sọ pe pasitọ naa sọ fun oun pe iku ni yoo gbẹyin oun ti oun ba le sọ fun ẹnikẹni," Odutola ṣalaye.
Agbẹnusọ ọlọpaa ni pasitọ naa jẹwọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pe lootọọ loun ba ọmọbinrin naa ni Ibalopọ lọpọ igba.
Odutola ni ọmọbinrin naa ti lọ si ile iwosan fun itọju ara rẹ ati ayẹwo.
O ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo gbe pasitọ naa lọ si Eleweran fun iwadii kikun.














