Mọ̀ nípa ìlú kan tó jẹ́ pé àwọn èèyàn ibẹ̀ kìí rántí nǹkan

Landais Alzheimer, ni guusu iwọ-oorun orilẹede France, jẹ abule kan to da yatọ - gbogbo awọn eeyan abule naa ni ko ki ranti nnkan.
Gbogbo awọn eeyan niluu Abule yii lo ni aisan Dementia.
Gẹgẹ bi iwadi BBC se sọ, ẹni to dagba ju ni abule naa le ni ọgọrun ọdun, ti ẹni to kere ju si jẹ ẹni ogoji ọdun.
Ile itaja ti o wa ni aarin gbogbo to n ta awọn ounjẹ ṣugbọn ko ki n gba owo, nitori na ko si ẹnikan ti o ranti mu apamọwọ wọn dani.
Wọn da abule silẹ lọdun 2020, eyi to jẹ irufẹ rẹ keji, to si ti jẹ ibi kan ti ọpọ eeyan lagbaye fẹ mọ nipa, paapa awọn to n wa ọna abayọ si aisan dementia.
O to eeyan ọgọfa to n gbe abule naa
Ki gan an ni a n pe ni Dementia?
Dementia jẹ ipo ailera kan ti ko ki n jẹ ki eeyan ranti nnkan.
A ko le pe aarun sugbọn o ni se pẹlu bi eeyan se ma gbagbe kan, riroun, iwuwasi ati okun lati se ohun ti o yẹ ki eeyan se lojumọ.
Apẹẹrẹ Dementia ni ki eeyan ma gbagbe nnkan, aile roun, nipa lati sọ ede, yiyi iwa pada lairo.
Awọn agbalagba ni Dementia ma mu ju.
"Dementia jẹ ki a sumọ ara wa ni abule"
Ni abule yii, ibasepọ awọn eeyan yii danmọran pupọ, ọpọ eeyan lo fẹ ri awọn arawọn lati jọ fọwọsowọpọ se nnkan.
Pẹlu bi Aisan n gboro, awọn eeyan yii n ri itọju to yẹ lati nitori o jẹ aisan ti ko gbọ oogun.
Ọpọ awọn olugbe abule yii lo ba BBC sọrọ lori igbesi aye wọn ati bi wọn se n gbe igbe ni abule.
Akọroyin BBC se abẹwo si abule, to si ọpọ awọn araalu sọrọ pe bi awọn se jọ ni aisan yii jẹ ki awọn sunmọ arawọn pupọ.
Ti tẹsiwaju
Agbẹ tẹlẹri Francis n ṣaajọ iwe iroyin ojoojumọ rẹ nibẹ - mo daba pe ki a lọ mu kọfi ni ẹnu-ọna keji. ni ile ounjẹ to n pese ounjẹ fun awọn araalu abule naa.
Mo beere Francis bi o se ti ri lara rẹ nigba ti dokita sọ fun un pe o ni aisan Alzheimer.
O miri, mu ara rẹ pada si akoko yẹn, lẹyin idaduro diẹ, o sọ pe: "O le gan."
Baba rẹ tun ni Alzheimer's - ṣugbọn Francis ko bẹru.
“Emi ko bẹru ti iku, nitori yoo ṣẹlẹ ni ọjọ kan,” o sọ.
“Ni bayii, Emi yoo gbe igbesi aye mi laibikita aisan yii.
“Mo wa nibi lati gbe aye, bo tilẹ jẹpe kii ṣe bakan naa.
"Ti o ba fi ara rẹ silẹ, o ti ni. Nitori naa ma tẹsiwaju, pẹlu gbogbo agbara rẹ."

Yatọ si lilọ ile itaja ati ile ounjẹ, awọn ara abule yii wọn tun ma rọ lati lọ wo sinima ati lati kopa ninu ọpọ nnkan.
Philippe ati Viviane sọ fun mi pe wọn tẹsiwaju lati gbe igbe aye wọn ni deede bi wọn ṣe le tẹle ayẹwo Aisan dementia.

"A ma n rin," Philippe sọrọ, lati ọna jijin.
Nigba ti mo beere boya inu wọn n dun, o yi ori rẹ pada lẹsẹkẹsẹ pẹlu ẹrin lẹnu rẹ, o sọ pe: "Bẹẹni inu wa dun- nitotọ."
Lẹyin naa, ti wọn ti pari kọfi wọn, ti wọn si wọ asọ wọn to dena otutu, tọkọtaya naa pada di ibudokọ.
Abule naa jẹ ibi kan ti wọn mojuto ni pẹkipẹki - Ọjọgbọn Hélène Amieva sọ pe awọn abajade esi daba pe eyi lo jẹ ki asian ni ipa.
“Ohun ti a ma rii nigba ti awọn eniyan ba wọ ile ẹkọ kan jẹ ohun to fa idinku – ti ile ẹkọ ko se akiyesi” o sọ.

Iya rẹ, Mauricette, ẹni ọdun 89, joko ninu yara rẹ, Dominique sọ pe: “Mo ni alaafia ọkan, nitori Mo mọ pe iya mi wa ni alaafia ati pe ko si ewu kankan.”
Laisi awọn wakati abẹwo, awọn eniyan wa bi o ba ṣe fẹ. Dominique si sọ pe oun ati awọn aburo rẹ ko ni reti pe itọju yoo dara tobẹẹ.
"Nigba ti mo ba fi silẹ, ara mi balẹ. Nigba ti mo ba de, o dabi pe mo wa ni ile rẹ - Mo wa ni ile pẹlu iya mi," o sọ.
















