Nǹkan méje tí o lè ṣe láti mú ìgbé ayé rẹ dára si lọ́dún 2024

Àwọn ènìyàn tó ń rìn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, BBC FUTURE TEAM
    • Role, BBC FUTURE TEAM

Bí ọdún tuntun, ọdún 2024 ṣe wọlé dé wẹ́rẹ́, o ṣeéṣe kí o ti ní àkọ́ọ́lẹ̀ tàbí àwọn ìpinnu kan lórí àwọn nǹkan tí o fẹ́ gbé ṣe nínú ọdún tuntun yìí.

Bí ó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń ní ìpinnu kan tàbí òmíràn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún, ṣíṣe àmúṣẹ wọn kí ọdún tó kolẹ̀ ló máa ń jẹ́ ìpèníjà fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.

Ìwádìí fi hàn pé ìdá mẹ́tàdínlógún sí márùndínláàdọ́ta ènìyàn ni kò tẹ̀síwájú ju oṣù kan lọ́ láti mú ìpinnu wọn ṣẹ lọ́dún 2023.

Ìwádìí tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àárín ọdún ni ọ̀pọ̀ ènìyàn kò ti tẹ̀síwájú mọ́ láti mú ìpinnu tí wọ́n ṣe lọ́dún tó kọjá ṣẹ.

Àwọn onímọ̀ nípa ìhùwàsí ẹ̀dá ní ohun tó máa ń ṣokùnfà tí ènìyàn kò fi ní tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìpinnu rẹ̀ kò ṣẹ̀yìn ṣíṣe àwọn ìpinnu tí kò ní ṣe é ṣàmúṣẹ.

Wọ́n ní ó dára tí ènìyàn bá fẹ́ ṣe ìpinnu láti ṣe àwọn èyí tó ṣe é múṣẹ, tí ènìyàn sì lè ṣe ìgbéléwọ̀n rẹ̀ láti mọ bí òun ṣe ń ṣe sí.

Lóòótọ́ ní o lè ṣòro láti ṣe ìpinnu àti láti ṣiṣẹ́ tọ̀ ọ́, ìdí nìyí tí a ṣe gbé àwọn ìlànà mẹ́sàn-án yẹ̀wò láti fi ràn án lọ́wọ́ láti mójútó ìgbé ayé rẹ̀ pàápàá ni ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun yìí.

O lè lo ọjọ́ méje àkọ́kọ́ láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn nǹkan láti mú ìgbé ayé rẹ rọrùn lọ́dún 2024.

Àwọn ènìyàn tó ń ṣeré ìdárayá

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ṣíṣe eré ìdárayà máa ń fa ẹ̀jẹ̀ sí ọpọlọ

Ṣe àmójútó oorun rẹ

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìsùn àti fáàjì ọdún tí àwọn ènìyàn ti ṣe wọ inú ọdún tuntun, ó pọn dandan fún ọ láti ṣe àmójútó oorun rẹ.

Ní àkókò yìí, ohun tí o nílò jùlọ ni oorun láti mú kí gbogbo ara rẹ bọ̀ sípò padà, tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì náà sì ní ó ṣe pàtàkì láti sùn dáradára lásìkò yìí.

Ìwádìí kan fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ènìyàn nílò oorun nígbà ọyẹ́ ju àsìkò oru lọ àti pé àwọn ènìyàn sábà máa ń sun oorun wàkátì kan lé sí i lásìkò ọyẹ́.

Láti ri dájú pé ò ń sùn dáradára lásìkò yìí, ri dájú pé ò ń sùn ní àsìkò, kí o sì yàgò fún lílo fóònù rẹ̀ tó bá ti ku bíi wàkátì méjì tí o fẹ́ sùn.

Lásìkò tí ó bá ǹ sùn yìí, o lè máa lá àlá nípa àwọn ọ̀nà to lè fi mú ìgbé ayé rẹ̀ dára si nínú ọdún tuntun yìí.

Ṣe àmójútó ara rẹ̀

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nínú ọdún tuntun yìí, o nílò láti ṣe ipinnu lórí mímú àyípadà bá ara rẹ̀ láti lè wà ní ìlera pípé nípa ṣíṣe eré ìdárayá. Àwọn nǹkan kéékèké bíi jíju ọwọ́ àti ẹsẹ̀ máa ń ní ipá ribiribi tí wọ́n ń kó lórí ìlera.

Ó dára láti máa ṣe eré ìdárayá lásìkò ọyẹ́ èyí tí àwọn onímọ̀ ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó dára fún ẹ̀yà ara tó sì lè mú kí ènìyàn dín ọ̀rá ara kù.

Lásìkò tí o bá ń ṣeré ìdárayà yìí, o tún lè gbìyànjú láti fi ẹ̀yìn rìn.

Àwọn onímọ̀ ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé fífi ẹ̀yìn rìn máa ń jẹ́ kí ènìyàn dín ọ̀rá ara kù ju kí ènìyàn máa rìn bó ṣe yẹ lọ àti pé ó máa ń mú kí ẹran àti egungun ẹ̀yìn ènìyàn nà dáradára.

Bákan náà ni wọ́n máa ń sọ fún àwọn ènìyàn tó bá ìṣòro pẹ̀lú orúnkún wọn láti máa fi ẹ̀yìn rìn nítorí ó máa ń ra egungun ibẹ̀ lọ́wọ́, tó sì tún máa ń ra ọpọlọ lọ́wọ́.

Ó tún ṣe pàtàkì láti ṣe ìtọ́jú àwọ̀ ara wa nítorí òhun ni ẹ̀yà ara tó pọ̀ jùlọ tí ṣíṣe ìtọ́jú rẹ̀ sì ṣe pàtàkì fún ìlera tó péye.

Tí àwọ̀ ara bá gbẹ tàbí ní àìsàn kan tó ń bá fínra, ó ṣeéṣe kí kòkòrò àìfojúrí kan máa jáde láti ara rẹ̀, tó sì lè ṣe àkóbá fún àwọn ẹ̀yà ara mìíràn bíi ọpọlọ àti ọkàn.

Ṣíṣe àmójútó àwọ̀ ara nípa lílo ìpara tó dára àtàwọn ìpara tó ń dín agbára oòrùn kù máa ń mú kí èèyàn máa kéré lójú si.

Mójútó ọkàn rẹ̀

Ṣíṣe ohun tuntun jẹ́ ọ̀nà kan tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní ó máa ń mú kí inú ènìyàn dùn tó sì máa ń dín bí ènìyàn ṣe ń ṣe wàhálà kù.

Kíkọ́ nípa àwọn nǹkan tuntun àti bíba àwọn àjòjì sọ̀rọ̀ jẹ́ ọ̀nà láti mú ìtanijí bá ènìyàn.

Ẹni tó ń wòye àwọn nǹkan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bákan náà ni o nílò láti máa sọ fún ara rẹ ní gbogbo ìgbà pé ọmọdé ní ẹ tí o sì lè ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan.

Èyí yóò fún ẹ ní ìwúrí láti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tí o rò wí pé o ò lè ṣe.

Orin kíkọ náà jẹ́ ọ̀nà láti mú inú ènìyàn dùn.

Kọ ìhà tó dára sí ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú àwọn èèyàn

Níní àwọn ọ̀rẹ́ tó dára máa ń mú ìgbésí ayé ènìyàn dùn tó sì máa ń ṣokùnfà ìlera pípé.

Irú ọ̀rẹ́ tí ènìyàn bá máa ń yàn máa sọ irú ìgbésí ayé tí ènìyàn máa gbé sí dada tàbí búburú.

Ohun tó fojúhàn ni pé irú ìgbé ayé tí àwọn tó bá wà ní àyíká ènìyàn bá ń gbé máa ń sọ irú ìwà tí ènìyàn yóò hù àti ìgbé ayé tí yóò gbé.

Ìmúra àti ìhà tí ó bá kọ sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ náà jẹ́ ohun tó lè ṣokùnfà irú àwọn ènìyàn tí o lè bá rìn.

Bákan náà fífi orí jin àwọn tó bá hu ìwà tí kò tọ́ sí ènìyàn jẹ́ ọ̀nà láti gbé ohun ńlá kúrò lọ́kàn tó sì lè mú ìgbé ayé rẹ rọrùn si lọ́dún tuntun yìí.

Mójútó àwọn nǹkan tí ò ń jẹ

Àsìkò ọdún, pàápàá àsìkò ọdún kérésì jẹ́ ìgbà tí ènìyàn kìí lè yunra oúnjẹ nítorí ọ̀pọ̀ oúnjẹ aládùn ló máa ń kúnlẹ̀ fún ènìyàn.

Èyí sì máa ń mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ oúnjẹ ju bí ó ṣe yẹ lọ àmọ́ ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń mú nǹkan tí wọ́n yóò máa jé nínú ọdún tuntun ní òkúnkúndùn.

Tí o bá ṣì ní oúnjẹ tí ẹ sè lásìkò ọdún nílé, ó dára kí ẹ jẹ́ ju kí ẹ fi ṣòfò ló àmọ́ ó dára láti ṣe ìtọ́jú rẹ̀ kí ó má ba à bàjẹ́ àti láti ri pé àwọn ohun èèlò tó ń ṣara lóore ṣi wà nínú rẹ̀.

Àwòrán kọfí

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Kọfí dára fún ìlera tí ènìyàn bá mu ún ni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì

Jíjẹ àwọn oúnjẹ tó ń ṣara lóore dára fún àgọ́ ara. Ìwádìí fi hàn pé jíjẹ àwọn oúnjẹ àhejẹ bíi súwìtì kò dára fún àgọ́ ara.

Àwọn èso àti ẹ̀fọ́ ni ìwádìí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé bí wọ́n ṣe dára fún àgọ́ ara náà ni wọ́n dára ọpọlọ pípé, tó sì tún lè mú àdínkù bá níní àìsàn ọkàn.

Mímu kọfí ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì le mú àdínkù bá àìsàn ọkàn, jẹjẹrẹ àti rọpárọsẹ̀.

Ṣíṣe eré ìdárayá

Ṣíṣe eré ìdárayá jẹ́ ọ̀nà láti dín ọ̀rá kù, tí yóò sì mú kí ènìyàn ní okun nínú àmọ́ bí ó ṣe dára tó láti máa ṣe, èèyàn kò gbọdọ̀ fi àṣejù si.

Ṣíṣe eré ìdárayá ní ìwọ̀nba ti tó fún ìlera pípé.

Bákan náà ló dára kí ènìyàn mọ àsìkò tó yẹ fún òun láti máa ṣe eré ìdárayá fún ṣíṣe èyí tó bá ènìyàn lára mu.

Gbájú mọ́ àwọn nǹkan tí ó fẹ́ràn láti má a ṣe

Bákan náà ló dára kí ènìyàn mọ àsìkò tó yẹ fún òun láti máa ṣe eré ìdárayá fún ṣíṣe èyí tó bá ènìyàn lára mu.

Ṣíṣe àwọn nǹkan tí o fẹ́ràn

Jíju ara ènìyàn sílẹ̀ láti fi ronú fún ìṣẹ́jú díẹ̀ máa ń bí àwọn nǹkan tó máa ń yani lẹ́nu tí ènìyàn kò ti ẹ̀ lérò tẹ́lẹ̀.

Àwọn ènìyàn tí nǹkan kìí pẹ́ sú ni wọ́n sábà máa ń ṣe àwọn nǹkan tí wọn kìí lè fi sílẹ̀ bọ̀rọ̀ mọ́ bíi títẹ fóònù èyí tí àwọn onímọ̀ ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó ń dákún bí àwọn ènìyàn ṣe ń ní ìpèníjà ọpọlọ.

Ṣíṣe àwọn nǹkan tí ènìyàn bá fẹ́ràn máa ń mú ọpọlọ jí pépé si tó sì máa ń mú kí ènìyàn ṣe ohun tuntun tó sì máa ń mú àdínkù bá ìrònú nígbà tí ènìyàn bá dá wà.

Bákan náà ní kíka ìwé dára fún ọpọlọ pípé àti pé àwọn tó sábà máa ń ka ìwé máa ń ṣe dada nínú gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ṣe ju àwọn tí kìí ṣe bẹ́ẹ̀ lọ.