Ọlọ́pàá Canada pa akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàìjíríà, àjọ Nidcom fọnmú

Afolabi Stephen

Oríṣun àwòrán, Nidcom

Ìjọba Nàìjíríà ti ṣèlérí láti ri dájú pé ọmọ Nàìjíríà tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní orílẹ̀ èdè Canada tí àwọn ọlọ́pàá orílẹ̀ èdè náà pa rí ìdájọ́ òdodo gbà.

Alága àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà nílẹ̀ òkèrè, Abike Dabiri-Erewa ló jẹ́jẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ yìí.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ àjọ náà, Abdur-Rahman Balogun fi síta lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrin oṣù Kìíní ọdún 2024 ni wọ́n ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Abike Dabiri-Erewa ní ṣíṣekúpa Afolabi Stephen ní Manitoba, orílẹ̀ èdè Canada jẹ́ ìwà tó burú jáì, tó sì bu omi tútù sí ènìyàn lọ́kàn.

Alága ọ̀hún ṣèlérí pé àwọn máa ri dájú pé àwọn wádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kúlẹ̀kúlẹ̀ tí àwọn yóò sì gba ìdájọ́ òdodo lórí ikú rẹ̀.

“Ìyàlẹ́nu ńlá ni ìròyìn náà jẹ́ fún wa àti pé a ti ń bá iléeṣẹ́ Nàìjíríà tó wà ní Ottawa sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa pé ìjọba Canada ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ohun tó ṣokùnfà tí ọlọ́pàá fi yìnbọn pa akẹ́kọ̀ọ́ náà.”

Dabiri-Erewa bá ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ Afolabi kẹ́dùn lórí ikú rẹ̀ tó sì gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ sáfẹ́fẹ́ rere.

Atẹjade lati ọd ileeṣẹ ọlọpaa Canada

Oríṣun àwòrán, Winnipeg Police

Kí ló ṣokùnfà ikú Afolabi Stephen?

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí àjọ Nidcom fi léde, wọ́n ní àwọn ọlọ́pàá orílẹ̀ èdè Canada ló yìnbọn pa Afolabi Stephen, ẹni ọdún mọ́kàndínlógún lọ́jọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá ọdún, 2023 nílùú Manitoba.

Wọ́n ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan kò ì tíì yé ẹnikẹ́ni, Winnipeg, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Manitoba nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi sórí ayélujára wọn ní àwọn gba ìpè pé ọ̀dọ́mọkùnrin kan ń ṣe wérewère.

Àwọn ọlọ́pàá náà ní gbogbo ìgbìyànjú àwọn láti ri dájú pé àwọn fi Afolabi lára balẹ̀ ló já sí pàbó, pé ohun tó fà á tí àwọn fi yìnbọn mọ́ ọn nìyẹn.

Wọ́n ṣàlàyé sójú òpó wón náà pé ìbọn tó bà á ọ̀hún ló ṣokùnfà ikú rẹ̀.

Ikú Afolabi Stephen ló ti ń fa awuyewuye lórí ayélujára tí ọ̀pọ̀ sì ń sọ̀rọ̀ lórí ààbò tó wà fún àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà nílẹ̀ òkèrè.

Lára ohun tí àwọn ènìyàn ń ṣo ni pé kí ló mú àwọn ọlọ́pàá lo ìbọn láti fẹ́ fi pẹ̀tù sí ẹni tí ara rẹ̀ kò balẹ̀ lọ́kàn.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí àwọn ọmọ Nàìjíríà pàdánù ẹ̀mí wọn nílẹ̀ òkèrè

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí àwọn ọmọ Nàìjíríà yóò máa pàdánù ẹ̀mí wọn nílẹ̀ òkèrè fún ìdí kan tàbí ìkejì.

Ní ọsù Kejì ọdún 2022 ni akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà kan ní orílẹ̀ èdè Ukraine, Fadlullah Agboluaje pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú yàrá rẹ̀ ní ọjọ́ kejì lẹ́yìn tó dé orílẹ̀ èdè náà.

Nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 ni akẹ́kọ̀ọ́ kan náà kú sí inú ọkọ̀ òfurufú nígbà tó ń lọ sílẹ̀ òkèrè fún ètò ẹ̀kọ́.

Toyosi Remilekun kò dé ilẹ̀ òkèrè tó ń lọ tó fi pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí wọ́n ní ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàárẹ̀ nínú ọkọ̀ òfurufú.