Ki ló dé tí 2024 ṣe jẹ́ ọdún 'leap year' àti pé kí láwọn àṣà tó rọ̀ mọ irú ọdún báyìí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ninu ọdun yi ọjọ kan yoo kun iye ọjọ inu kalẹnda tí yoo jẹ ki ọdun naa jẹ leap year ìyẹn ọjọ 366 dipo ọjọ 365 to máa n waye tẹlẹ.
Osu to kere julọ ninu ọdun yoo fi ọjọ kan lesi to tunmọ sí pe February yoo jẹ ọjọ mọkandinlọgbọn ti awọn aṣa ati iṣẹṣe kan si rọ mọ ọjọ yi.
Leyi to máa n waye lọpọ igba ọdun mẹrin sira ni iru ọdun yi máa n ṣẹlẹ
2020 lo waye k'ẹyin ti eleyi to tun kan yoo si waye ni 2028.
Amọ iyipada a maa ṣẹlẹ ti ọrọ ko si ni ri bẹẹ mọ.
A o ṣe alaye eleyi ati awọn aṣa jakejado agbaye to so mọ ọdun ti ọjọ a maa lekun yii.
Ki lo de ti leap year fi n waye
Ninu iwe ikajọ kalẹnda, ọjọ ọọdunrun le marundinlaadọrin lo wa ninu ọdun kan.
Eyi jẹ iye ọjọ ti agbaye taa wa yoo fi yipo oorun.
Ṣugbọn iye ọjọ yi ko jẹ nọmba to panude s'oju kan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni pato ọjọ 365.242190 ni ile aye ta wa yi fi n yipo oorun.
Eleyi la mọ si 'sidereal' year.
Iru ọdun taa n pe ni sidereal yi a maa gun ju ọdun oju ọjọ kalẹnda tori naa awọn wakati iṣẹju ati iṣeju aaya to fi ju lọ la maa n mu adinku ba ki gbogbo rẹ baa le ṣe dọgba.
Nipa fifi ọjọ kan kun iye ọdun yi, a o lanfaani lati ṣe iṣiro awọn asiko to n waye ki gbogbo rẹ baa le ṣe dọgba.
Ki lawọn aṣa to rọ mọ ọdun leap year?
Orisi aṣa ati iṣẹṣe lo rọ mọ ọdun leap year.
Ayajọ awọn apọn gẹgẹ bi apẹrẹ ti wọn a tun maa pe ni asiko apọnle awọn ọlọmọge jẹ aṣa kan tawọn eeyan orileede Ireland a maa ṣe.
Ọjọ yi ni awọn obinrina a maa fi kẹnu ifẹ si awọn ọkunrin lọjọ leap year.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Baa se mọ pe lode oni ko jẹ tuntun pe ki obinrin kọ ẹnu ifẹ si ọkunrin ti wọn si le ṣe bẹẹ lọjọ to ba wu wọn, amọ aṣa yi ti pẹ ti wọn ti n ṣe lorileede naa.Igbagbọ ni pe o rọ mọ imọriri akikanju St Bridget ati Saint Patrick nigba naa lọhun.
Bridget ni wọn gbagbọ pe o lọ ba Patrick pe awọn obinrin n pẹ ki wọn to lọkọ tori awọn ọkunrin kii tete kẹnu ifẹ si wọn.Tori naa o beer igbalaye ki awọn obinrin lanfaani lati kẹnu ifẹ si ọkunrin pe ko fẹ awọn.
Bẹẹ naa ni wọn ni aṣa to rọ mọ igba ti arakunrin ba kọ lati fẹ obirin to kẹnu ifẹ si.Labẹ eleyi, arakunrin to ba ṣe bẹẹ, yoo ra ibọwọ tabi aṣọ siliki pe ko fi ṣe gba ma inu mi o fẹ ọ.
Lawọn aṣa ati iṣẹṣe ibomiran ọjọ to lewu ni wọn ka ọjọ leap year yi si.
Ni orileede Greece wọn ni igbagbọ pe ko da ki eeyan ṣe igbeyawo lọjọ alekun ọun taa mọ si leap year yi tabi lasiko kankan ninu ọdun naa bi iru ọdun taa wa ninu rẹ yi.Igbagbọ ni pe eyikeyi igbeyawo to ba waye ninu ọdun yi yoo fori ṣanpọn ni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni Scotland, awọn eeyan a maa nigbagbọ pe ọjọ leap day jẹ ọjọ tawọn ajẹ a maa kora jọ lati ṣe awọn eeyan laburu.
Bẹẹ naa lawọn kan to jẹ ọmọ ilẹ naa gbagbọ pe ọjọ abami ni ki eeyan bi ọmọ lọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Keji ọdun leap year.

Oríṣun àwòrán, Getty
Nibomiran awọn eeyan a maa ka ọjọ yi si ọjọ to lamilaaka ti ọjọ ibi eeyan ba se dede rẹ.
Awọn aworawọ kan gbagbọ pe ti ọjọ ibi rẹ ba ṣe deede ọjọ leap day, eeyan yoo jẹ ẹni abiyi.
Ki lo de ti leap day yi fi bọ si inu oṣu Keji February?
Itan fi han pe ṣiṣa oṣu keji lẹṣa fun ọjọ leap year yi ko ṣẹyin iyipada ti ọba Julius Caesar mu ba kalẹnda laye awọn eeyan Roomu nigba atijọ.
Caesar lo ṣe ifilọlẹ kalẹnda Julian Kalẹnda ti o si fi ọdun ti ọjọ rẹ le ọkan kun ki o baa le wa ni ibamu pẹlu onka ọdun oju ọrun.
Koda lẹyin igba ti kalẹnda yi pada kuro ni ti Julian to di ti Gregorian ni 1582,wọn ko gbagbe aṣa fifi ọjọ kan kun ọdun loṣu keji ọdun taa mọ si leap year.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki ni yoo ṣẹlẹ ti ko ba si leap year ninu onka ọdun?
Ti a ko ba ni leap year taa si faaye silẹ fun alekun akoko ti o wa laarin kalẹnda kan si omiran, awọn asiko ọdun yoo bẹrẹ si ni sun jina si arawọn.
Bi a ba wo bi apẹrẹ laarin ọdun ẹẹdẹgbẹrin,asiko ẹrun ni agbegbe ariwa agbaye yoo bẹrẹ si ni waye ni oṣu Kejila dipo oṣu Kẹfa to n waye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ eeyan lo gbagbọ pe laarin ọdun mẹ́rin si arawọn ni leap year a maa waye ṣugbọn ko ri bayii ni gbogbo igba.
Idi si ni pe iyatọ to wa laarin ọdun siderel ati awọn ọdun ọjọ kalẹnda mii laarin ọdun mẹrin si arawọn ko ṣe deede wakati mẹrinlelogun.Bi a ba foju wo wakati mẹta le logun le diẹ lo jẹ iyẹn, 23.262222 hours.
Tori naa a gbọdọ mu alaye wa ti eleyi fi ri bẹẹ
Ni akọsilẹ ofin, ọdun taa baa pe ni leap year gbọdọ jẹ eyi ti a le fi nọmba 4 pin ti ko si ni ṣẹku nkankan.
Awọn ọdun ti ko tẹle ofin yi lawọn eyi taa le fi ọgọrun nọmba pin.
A kii kawọn kun ọdun leap year..
Am ọ bi ọdun ba ni nọmba odindi ti a ba fi irinwo, 400 pin tan, a ṣi le ka ọdun bẹẹ pe o jẹ ọdun leap year.
O ti fẹ maa daru mọ yin loju abi?Ẹ jẹ ki a fi alaye tan imọlẹ si ọrọ naa.
Ọdun 2000 jẹ lepa year tori pe a le fi nọmba 4 ati 400 pin ti ko si ni ṣẹku.
Sugbọn ọdun 1700,800 ati 1900 jẹ eyi taa le fi 4 pin amọ ti ko ṣe fi 400 pin.
Tori naa wọn kii ṣe ọdun leap year.
Igba ti a o tun fo kika ọdun leap year mi yoo jẹ ọdun 2100.












