Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Adedeji Aderemi ‘Olofa Ina’ tó jáde l'áyé

Oríṣun àwòrán, Other
Gbajumọ eekan osere tiata, Oloye Adedeji Aderẹmi ti ọpọ mọ si Ọlọfa ina ti jade laye.
Baba Ọlọfa ina jade laye ni aṣalẹ Ọjọbọ, ọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2024.
Eni odun metalelaadorin ni agba òoṣere naa ki ọlọjọ to de.
Lara awọn eekan oṣere sinima to ti fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ loju opo ayelujara wọn ni Ojopagogo ati Saidi Balogun,

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Adedeji Aderemi ‘Olofa Ina’

Oríṣun àwòrán, others
Wọn bi Adedeji Aderemi ni ọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 1950, ni agboole Jagun-Olukosi niluu Ede, nipinlẹ Osun.
Baba Olofa Ina lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ St. Peters Anglican Primary School.
Lẹyin naa lo lọ si ile ẹkọ girama Baptist Modern Secondary School.
Ṣaaju ko to o di oṣere, o kọ iṣẹ gbẹnagbẹna, ti wọn n pe ni Carpentry ni ede Gẹẹssi lọdun 1965 si 1970.
Bakan naa ni Olofa Ina ṣiṣẹ gẹgẹ bi oṣiṣẹ ijọba ni ileeṣẹ to n ṣe awọn akanṣe iṣẹ ati igbokgbodo ọkọ niluu Ibadan. O sẹ iṣẹ naa laarin ọdun 1970 si 1977.
Iroyin sọ pe ni gbogbo asiko yii ni oloogbe Aderemi ti n ṣe ere ori itage diẹdiẹ. Nigba to di ọdun 1972, o da ẹgbẹ osẹre rẹ, Olofa Ina Theatre Group silẹ pẹlu awọn oṣere mii.
Ẹgbẹ oṣere Olofa Ina ma n ṣe awọn ere ori itage to n sọ nipa itan awọn jagunjagun nilẹ Yoruba.
Wọn ṣe awọn ere to ni i ṣe pẹlu itan Basorun Ogunmola, Balogun Ibikunle, Ogedengbe Agbogungboro, Aarẹ Kunrunmi, Kakanfo ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ori amohunmaworan Nigerian Television (NTV) niluu Ibadan si ni wọn ti ma n ṣe afihan awọn ere naa.
Awọn ere ti Olofa Ina ṣe nigba aye rẹ
Oloogbe Aderemi kopa ninu awọn gbajugbaja ere bii
- Ija Omode
- Idaamu Otunba
- Ewe Orun
- Kabiyesi Olodumare
- Mayegun, Ejo Ngboro
- Lisabi Agbongbo Akala, ati awọn mii.












