Peanut, adìyẹ tó dàgbà jù l’ágbàyé kú lẹ́ni ọdún mọ́kànlélógún

Oríṣun àwòrán, GRW
Ajọ Guiness World Records ti kede pe inu ohun bajẹ lati gbọ iku adiyẹ to dagba julọ ni agbaye, Peanut.
Ọjọ ọdun Keresimesi ni Peanut jade laye nile rẹ to wa niluu Michigan, orilẹ-ede United States of America, lẹni ọdun mọkanlelogun, le ni ojilerugba din meji ọjọ.
Ẹni to ni adiyẹ naa, Arabinrin Marsi Darwin, sọ ninu atẹjade kan pe ibatan to sunmọ oun pẹkipẹki ni Peanut, ti oun si n ṣe ọfọ rẹ.
“Ọdun mọkanlelogun ati aabọ sẹyin ni ọrẹ wa bẹrẹ, nigba ti mo yọ ọ jade ninu ẹyin kan.
“Lẹyin ọjọ naa ni mo mọ pe ẹlẹmi gigun ju ti awọn ẹgbẹ rẹ lọ ni.”
Bawo ni Peanut ṣe de akata olowo rẹ ati bo sẹ lo igbeaye rẹ?

Oríṣun àwòrán, GWR
Guiness World Record kọ sori ayelujara wọn pe, lẹyin ti iya to bi Peanut pa a ti, o lo ọdun meji akọkọ aye rẹ ninu àgọ̀ ẹyẹ awoko kan ninu yara ti Marsi ti n jẹun, ko to o di pe o darapọ mọ awọn adiyẹ yooku ti Marsi n sin ni ẹyinkule ile rẹ.
Nigba to wa ninu ẹyin ni iya rẹ fi silẹ sinu ibi to ye ẹyin si, to si lọ pẹlu awọn ọmọ rẹ yooku to pa ẹyin wọn.
Lẹyin naa ni Arabinrin Marsi ri ẹyin naa ti ara rẹ ti tutu, to si mu u lati ju u sinu adagun odo rẹ, nitori o ro pe o ti di obu ẹyin.
Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe lọgan lo gbọ ti adiyẹ naa ke ṣio-ṣio.
Ogunlọgọ ẹyin ni Peanut pa nigba aye rẹ, pupọ ninu awọn ọmọ ati ọmọ-ọmọ rẹ lo ṣi n gbe lọdọ Marsi.
Bo ṣe di pe o n di arugbo ni Peanut pada si ni gbe inu ile pẹlu olowo rẹ, nibi to ti wa ninu agọ pẹlu ọmọbinrin rẹ, Millie.
Ṣugbọn o jẹ ibanujẹ pe, Millie kú lọmọ ọdun mẹẹdogun. Bakan naa ni ọkan lara awọn ọrẹ ọjọ pipẹ fun Peanut, Luna, naa ku lẹyin ọjọ diẹ.
Ko tan si bẹ o, ọsẹ kan lẹyin rẹ ni akukọ kan to jẹ alajọgbele fun un, Benny, naa tun ku.
Marsi sọ pe oun gbagbọ pe ibanujẹ ọkan nipa iku awọn ọrẹ rẹ, pẹlu ọjọ ogbo, lo pa Peanut.
Lara awọn nnkan ti Marsi ko le gbagbe nipa adiyẹ naa ni bo sẹ gba ami ẹyẹ GWR gẹgẹ bi adiyẹ to dagba julọ ni agbaye.
“Mo mọ pe oju orun rẹ lo ti ku wọọrọwọ, eyi to jẹ ẹbun ikẹyin fun mi.
“Mo si mọ pe ọjọ ọla yoo pada dara. Amọ, titi lai ni aaro rẹ yoo sọ mi.”
Nigba wo ni Peanut gba ami ẹyẹ Guiness World Record?

Oríṣun àwòrán, gwr

Oríṣun àwòrán, gwr
Ọjọ kinni, oṣu Kẹta, ọdun 2023, ni Peanut, gba ami ẹyẹ GWR, gẹgẹ bi adiyẹ to dagba julọ, to ṣi wa ni aye.
Wọn sọ nigba naa pe Peanut ti lo ju ogun ọdun lọ lẹyin ti ori ko o yọ lọwọ iku nigba ti iya rẹ pa a ti.
Ọdun 2002 ni wọn bi Peanut.
Iran adiyẹ ti wọn n pe ni Bantam – eyi to jẹ iru awọn adiyẹ to wọpọ ni orilẹ-ede Belgium, ni Peanut.
Ẹni to pada tọju rẹ dagba, Arabinrin Marsi jẹ akọṣẹmọsẹ alamojuto ile iyawe-kawe.
Ki wọn o to o fun Peanut ni ami ẹyẹ, dokita ẹranko, Julia Parker, fidi ọjọ ori rẹ mulẹ.
Ọdun mẹjọ akọkọ ninu igbe aye rẹ ni Peanut fi ye ẹyin, eyi to fi ọdun meji yatọ si nnkan to wọpọ laarin awọn adiyẹ.
Ni ọjọ ogbo rẹ, oorun ati ounjẹ jijẹ nikan ni Peanut ṣe lojoojumọ.
Bakan naa lo fẹran lati ma a wo tẹlifisan pọ pẹlu ọmọ rẹ obinrin, Milli.
Olowọ rẹ sọ pe o ma n dahun nigbakugba ti wọn ba pe orukọ rẹ.
Arabinrin Marsi sọ pe fifun adiyẹ ni ounjẹ aṣaraloore, ati fi fun wọn ni aaye lati ṣe ere idaraya, ni ọna kan gboogi lati jẹ ki adiyẹ ni ẹmi gigun.
O fikun ọrọ rẹ pe oun ma n fun adiyẹ naa ni vitamin D mọ omi wara to n mu, ati pe oun tun ma n fun un ni eso ati ewebẹ tutu ni ẹkọọkan

Oríṣun àwòrán, gwr
Ṣaaju Peanut, adiyẹ kan, Muffy, ti kọkọ gba ami ẹyẹ gẹgẹ bi adiyẹ to dagba julọ ni aye.
Ẹni ọdun mẹtalelogun ati aabọ ni Muffy nigba to ku.












