'Èmi ní àwọn ajínigbé ní kó yan mẹ́ta lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ mi fún pípa'

Àkọlé fídíò, Ẹ̀dá aláyè kan kò le mọ ibi tí àwọn ajínigbé kó wa wọ̀, àfi ẹni tí wọ́n bá mú wọ ibẹ̀
'Èmi ní àwọn ajínigbé ní kó yan mẹ́ta lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ mi fún pípa'

Ẹgbẹ akọrin Juju, De Jombo Beats, to ṣẹṣẹ moribọ ni akata awọn ajinigbe ti sọ bi iriri wọn.

Omooba De Jombo Beats ati awọn elegbe rẹ ko sọwọ awọn ajinigbe ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu kejila ọdun 2023.

Nigba ti wọn ba BBC sọrọ ninu ifọrọwanilẹnu wo, awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin naa sọ pe ọjọ mẹfa ni awọn lo ni ahamọ awọn ajinigbe naa.

Ẹni to jẹ olori ẹgbẹ, Ọgbẹni Adebukoye Samuel Omooba, sọ pe ilu Itakete-Isao nipinlẹ Kogi ni awọn ti lọ ọ kọrin nibi ayẹyẹ oku, ki wọn o to kagbako awọn ajinigbe nigba ti wọn n pada silu Abuja.

O ni ni nnkan bi aago marun-aabọ irọlẹ ti awọn sẹtan ni agbo ariya ni awọn pinnu lati pada sile, amọ ahamọ ajinigbe ni wọn yọri ọjọ naa si.

Ni akata awọn ajinigbe, awọn ọmọ ẹgbẹ De Jombo Beats ṣalaye fun akọroyin BBC pe miliọnu mẹwaa Naira ni wọn kọkọ beere fun itusilẹ ẹnikọọkan, ko to o di pe wọn dinku si miliọnu meje Naira.

Ọgbẹni Adebukoye sọ pe nigba ti owo naa n pẹ ki awọn to o ri san-an, ọga awọn ajinigbe ni ki oun tọka si mẹta ninu awọn ọmọ ẹgbẹ ti awọn le pa.

“Igbesẹ naa nira fun mi lati gbe. Mo ba sọ fun un pe ki wọn o jẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin mi ma a dele layọ, ṣugbọn ki wọn pa emi dipo wọn.

“Ti mo ba na ọwọ si ẹnikẹni ninu wọn, awọn ẹbi wọn yoo bi mi, bẹẹ ni emi gan-an o le gbadun aye mi lailai nitori igbesẹ naa.”

Ẹwẹ, ikọọkan awọn ọmọ ẹgbẹ Jombo Beats sọ pe oriṣiriṣi ewe ti awọn ko jẹ ri, ni awọn fi ṣe ounjẹ ninu igbo.

Ẹnikan lara wọn ni, itọ idi oun ni lo n fi ṣe omi mu.

Lẹyin ọjọ kẹfa ni wọn to o gba ominria, nigba ti awọn ajinigbe naa tka oju ọna to ja si opopona nla fun wọn.

Kikuro ti wọn kuro ni ahamọ, abule kekere kan ti wọn jade si ni wọn ti fun wọn ni Garri ati omi ti wọn mu.

Ọgbẹni Adebukoye sọ pe nitori iriri ti awọn ni, awọn ko ni i gba iwe ipe lati kọrin ni ilu ti ko ba ti ni papakọ ọkọ ofurufu mọ.