Supersports kò ní ṣàfihàn ìdíje ife ẹ̀yẹ AFCON - Muitichoice

Aworan ife ẹyẹ adulawọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ Muitichoice, to da DStv ati GOtv silẹ ti kede pe awọn ko ni safihan idije ife ẹyẹ adulawọ AFCON to n bọ lori opo wọn fun awọn onibara wọn.

Muitichoice ninu atẹjade ti wọn gbe sita salaye pe wọn ko ri aṣẹ lati safihan idije naa gba lọwọ Ajọ ere bọọlu ni Afrika, CAF.

“Supersports ko ni safihan idije ife ẹyẹ adulawọ AFCON ọdun 2023, eyi ti yoo bẹrẹ ni ọjọ kẹtala oṣu kinni , ti yoo si pari ni ọjọ kọkanla oṣu keji ọdun 2024 nitori a ko ri asẹ gba lati safihan idije naa.

“Amọ, awọn ifẹsẹwọnsẹ yii yoo wa lori opo igbohunsafẹfẹ keji wa to jẹ ọfẹ (Free to Air).

Aworan

Oríṣun àwòrán, Muitichoice

“Multichoice Africa ko yii ipinnu rẹ pada lori riri daju pe awọn ololufẹ erebọọlu kaakiri ilẹ adulawọ ni anfani lati wo ere bọọlu kaakiri lori opo wa lori DStv ati GOtv wa, paapa awọn idije bi Permier League, La Liga, Seria A, Zambia Super League ati awọn ifẹsẹwọnsẹ alayọ.”

Idije AFCON tọdun yii lo jẹ ti ẹkẹrinlelọgbọn ti yoo waye, ti tọtẹ yii yoo si waye ni orilẹede Ivory Coast.

Isọri ‘’A’’ ni Naijiria wa ninu idije naa pẹlu orilẹede Ivory Coast to yoo gbalejo idije naa ati Guinea-Bissau to fi mọ Equatorial Guinea.

Amọ, ṣe Super Eagles le jẹwọ orukọ ara wọn ki wọn si fakọyọ ni Ivory Coast?