Wo àwọn ọ̀nà to lè gbà láti mọ̀ bóyá ilé ẹ̀kọ́ tàbí ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní òǹtẹ̀ ìjọba

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ní ọjọ́ kejì, oṣù Kìíní, ọdún 2024 ni ìjọba Nàìjíríà dá ètò bíbuwọ́lu ìwé ẹ̀rí ilé ẹ̀kọ́ gíga láti orílẹ̀ èdè Benin Republic àti Togo.

Ìgbésẹ̀ náà kò ṣẹ̀yìn ìjábọ̀ iléeṣẹ́ ìròyìn kan tó ní òun gba ìwé ẹ̀rí pé òun lọ sí ilé ẹ̀kọ́ kan ni orílẹ̀ èdè Benin láàárín oṣù méjì láì kúrò ní kọ̀rọ̀ yàrá rẹ̀.

Èyí ló mú ìjọba Nàìjíríà kéde pé àwọn kò ní fàyè gba àwọn ìwé ẹ̀rí láti àwọn orílẹ̀ èdè Benin àti Togo fún ìgbà kan ná.

Lẹ́yìn ìkéde yìí ni àwọn ènìyàn míì ń sọ pé yàtọ̀ sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ ilẹ̀ òkèrè yìí, pé ọ̀pọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ ló wà ní Nàìjíríà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ àmọ́ tí ìjọba kò buwọ́lu ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń ṣe.

Ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà, NANs nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi léde ní ó yẹ kí ìjọba ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí ìjọba kò fún láṣẹ tàbí buwọ́lu àwọn ètò ẹ̀kọ́ kan ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ wọn àmọ́ tí wọ́n ń ṣètò ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ pa ni.

Èyí ló ṣokùnfà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn fi ń bèèrè pé báwo ni àwọn ṣe fẹ́ dá àwọn ilé ẹ̀kọ́ àtàwọn ètò ẹ̀kọ́ tí ìjọba fi òǹtẹ̀ lù mọ̀.

Kí ni "Accreditation?

Gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga yálà fásitì, pólì tàbí ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni, tí ìjọba tàbí aládàni ló gbọ́dọ̀ ni ìwé ẹ̀rí pé ìjọba buwọ́lù wọ́n láti máa ṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́.

Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí ló ní ìlànà àti àwọn ètò tí wọ́n nílò láti tẹ̀lé àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ ní àwọn ohun èlò kan kí wọ́n tó lè gbà òǹtẹ̀ ìjọba pé wọ́n pegedé láti máa ṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gba òǹtẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ ni wọ́n nílò láti òǹtẹ̀ lórí gbogbo ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n bá fẹ́ máa ṣe nílé ẹ̀kọ́ náà.

Ní ìgbà dégbà sì ni ètò àyẹ̀wò yìí máa ń wáyé láti mọ̀ bóyá àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà kò yẹ̀bá pẹ̀lú ìlànà tí wọ́n fi lélẹ̀.

Ṣíṣe "Accreditation" ṣe pàtàkì nítorí ohun ló máa fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ń pèsè ètò ẹ̀kọ́ tó pójú owó àti pé àwọn tó bá lọ sílé ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ yóò pegedé lẹ́nu ẹ̀kọ́ wọn.

Gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ ló máa ń fẹ́ kí ìjọba fi òǹtẹ̀ jan ilé ẹ̀kọ́ wọn pé wọ́n pegedé àmọ́ tí àwọn mii máa ń fẹ́ gba ọ̀nà ẹ̀bùrú nígbà tí wọn kò bá ní àwọn ohun èèlò tó yẹ.

Báwo lo ṣe lè mọ̀ pé ìjọba kò buwọ́lu ilé ẹ̀kọ́ tàbí ètò ẹ̀kọ́ tí ò ń ṣe?

  • Ṣíṣe àyẹ̀wò ìtàkùn àgbáyé (website) ilé ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀
  • Ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ní òǹtẹ̀ ìjọba ni wọ́n máa ń fi sórí ayélujára wọn láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀.
  • Ní ẹgbẹ́ kan lápá òkè tàbí ìsàlẹ̀ orí ìtàkùn àgbáyé bẹ́ẹ̀ ni ìtàkùn tí yóò gbé èèyàn lọ sí ojú òpó ibi òǹtẹ̀ náà ni ó sábà máa ń wà.
  • Ọ̀pọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tó gba òǹtẹ̀ pé wọ́n pegedé máa ń fi àsíá àjọ tó buwọ́lù wọ́n sórí ayélujára wọn láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn gba òǹtẹ̀.
  • Àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó bá ní orúkọ tó fara pẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tó bá gbajúmọ̀ jẹ́ èyí tó yẹ kí o ṣe ìwádìí lórí rẹ̀ dáradára láti mọ̀ bóyá wọ́n ní òǹtẹ̀ láti máa kọ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́.
  • Tí àwọn ènìyàn tàbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tó wà ní agbègbè ibi tí ilé ẹ̀kọ́ kan bá wà kò bá mọ́ nípa rẹ̀, ṣe ìwádìí dáradára kí o tó bẹ̀rẹ̀ ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀.
  • Bákan náà tí orúkọ àjọ tí wọ́n bá ní ó ṣe àyẹ̀wò àwọn kìí se orúkọ tó gbajúmọ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n má ì tíì ní ìwé ẹ̀rí pé ilé ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ pegedé.
  • Ọ̀pọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ní òǹtẹ̀ ìjọba ni wọ́n máa ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìròyìn nípa wọn bíi iye akẹ́kọ̀ọ́, àwọn yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ní ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sórí ayélujára, tí èyí kò bá rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ilé ẹ̀kọ́ tí o fẹ́ lọ sanwó sí, gbé e yẹ̀wò dáadáa.

Ọ̀nà míràn láti tún mọ̀ bóyá ilé ẹ̀kọ́ fásitì tí o fẹ́ lọ, ní òǹtẹ̀ ìjọba ní pé kí o yẹ ìtàkùn àgbáyé àjọ National University Commission, NUC, wò.

Àjọ nàá ló n mójútó ìdásílẹ̀ àwọn fásitì, ìfòrúkọ sílẹ̀ wọn, bíbuwọ́ lu àwọn ètò ẹ̀kọ́ wọn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.