PDP Ondo Crisis: Ọ̀rọ̀ Alága PDP tí wọ́n dá dúró nípínlẹ̀ Ondo fi orí àgbà méjì gbá ara wọn
Ọ̀rọ̀ Alága PDP tí wọ́n dá dúró nípínlẹ̀ Ondo fi orí àgbà méjì gbá ara wọn

Oríṣun àwòrán, Nigerian Tribune
Olu ile ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ti sọ pe alaga ẹgbẹ osẹlu naa nipinlẹ Ondo, Fatai Adams ti awọn kan da duro ko ni bii re.
Akọwe apapọ ẹgbẹ naa, Debo Ologunagba sọ ninu atẹjade kan peAdams ṣi ni alaga PDP l’Ondo.
Ọgbẹni Ologunagba sọ pe awọn to ni ki Adams kuro nipo alaga PDP ko lẹtọọ lati ṣe bẹẹ lai jẹ pe wọn gba aṣẹ lọwọ igbimọ amuṣẹṣe, National Working Committee, gẹgẹ bi iwe ofin ẹgbẹ PDP ṣe la a kalẹ.
Akowe apapọ PDP naa tẹsiwaju, pe ẹgbẹ to ni ilana ati ofin ni PDP, ko si saaye fun abala kan awọn eeyan lati maa da aṣe pa tabi da gbe igbesẹ.
"Fun idi eyi, ofege ati otubantẹ ni igbesẹ awọn to ni awọn ni wọn yọ Fatai Adams nipo alaga PDP Ondo. Fatai ṣi ni Alaga tẹgbẹ fọwọ si."
Irọ ni, a ti rọ Alaga loye, ipinnu Akọwe apapọ ko ba tẹgbẹ mu

Oríṣun àwòrán, Other
Kete ti Akọwe apapọ sọ ero ọkan rẹ di mimọ ninu atẹjade ni Kennedy Ikantu Peretei, Akọwe ẹgbẹ PDP l’Ondo ti da a pada fun un pe irọ ni, awọn ti rọ Fatai Adams loye, aṣẹ si ni.
O ni itiju lo jẹ fun PDP Ondo bi Akọwe Apapọ ẹgbẹ naa ṣe n lodi si ofin ti ẹgbẹ la kalẹ.
‘’Fun awọn ti ko ba mọ, gbogbo ẹka ẹgbẹ lo l'agbara lati fiya jẹ ọmọ ẹgbẹ to ba tasẹ agẹẹrẹ.
"Ko baa jẹ ni wọọdu, ijọba ibilẹ, ipinlẹ abi lẹlẹkun-jẹkun., ọmọ ẹgbẹ igbimọ amuṣeṣe ni Fatai Adams naa, ẹgbẹ si lẹtọọ lati ba a wi to ba ṣẹ."
Ọgbẹni Peretei sọ pe mẹsan-an ninu mọkanla awọn ọmọ igbimọ amuṣeṣe lo buwọ lu u pe ki wọn o da Alaga duro na.
O ni iyẹn nikan ti to o sọ pe alaga naa ko wulo f’ẹgbẹ awọn mọ.
Akọwe PDP yii sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe f'eti si nnkan ti Ologunagba n wi.
O ni ni ti Fatai Adams, gbogbo ẹgbẹ sọ pe o ti lọ, ati pe ero ọkan Ologunagba to gbe jade ko ṣee tẹle, ofin ko fọwọ si i nibikibi.
Igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, nipinlẹ Ondo ti kede sita pe awọn ti sọ fun alaga egbe naa, Fatai Adas lọ rọọkun nile.
Igbimọ naa fẹsun kan alaga pe o lọwọ ninu awọn iwa to tako ofin ati ilana ẹgbẹ oṣelu naa.
PDP ipinle Ondo sọ eyi ninu atẹjade kan ti won sọwọ si awọn akọroyin lọjọ Isẹgun, ọjọ keji, oṣu Kinni, ọdun 2024.
Atẹjade naa ti ọmọ ẹgbe mẹsan-an buwọlu salaye pe igbimọ oluwadi ri pe Adams jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.
Awọn omo ẹgbẹ naa sọ pe igbesẹ awon ba ofinati ilana ẹgbẹ mu.
“A gba Adams ni imọran pe ko farahan niwaju igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ fun ifọrọwerọ laarin ọsẹ kan ti aṣẹ yii jade.
“Ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ondo, ko ni i fi aye silẹ fun iwa to tako ofin ati ilana ẹgbẹ."
Nigba to n fesi si bi won ṣe da a durọ, Ọgbẹni Fatai Adams so fun iwe iroyin The Punch pe, ọrọ ko ribẹ rara.
O ni awọn eeyan kan lo n gbiyanju lati da alaafia ẹgbẹ naa ru.
O jẹ ko di mimọ pe oun si ni alaga ẹgbẹ oṣelu naa.
“Eyi ko ri ẹsẹ mulẹ rara, a mọ ohun ti a n sọ. Erongba wọn ni lati yọ mi nipo lati fun wọn ni anfani lati sisẹ ọwọ wọn, ṣugbọn ko ni waye.”

Oríṣun àwòrán, PDP















