Wo ìdí tí EFCC ṣe fẹ́ ẹ́ wádìí mínísítà fún ìtọ́jú aráàlú lásìkò ìjọba Buhari

Aworan Sadiya Farouk

Oríṣun àwòrán, Channels

Àkọlé àwòrán, Sadiya Umar- Farouk

Ajọ EFCC ti ṣetan lati fọrọ wa Sadiya Umar Farouk, minista fun itọju ọmọniyan ati idagbasoke awujọ ninu iṣejọba Muhammadu Buhari, lẹnu wo loriii N37.1b to dawati nipasẹ rẹ ni ileeṣẹ ijọba to ṣoju fun.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ajọ EFCC ranṣẹ pe Sadiya lọsẹ to kọja lati ṣalaye nipa owo nla ti wọn ni wọn ṣe mọkumọku lasiko to n bojuto ileeṣẹ ijọba ọhun.

Iroyin sọ pe Ṣadiya ati agbaṣẹṣe kan torukọ ẹ n jẹ James Okwete, ni wọn jọ mọ bi N37.1 billion ṣe dohun ti wọn ko ri mọ.

A gbọ pe aago mẹwaa aarọ ni wọn ni ki minista tẹlẹ yii de ọfiisi awọn EFCC to wa ni Jabi, l’Abuja, ṣugbọn ko ti i yọju si wọn ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.

Ẹnikan to fidi iroyin naa mulẹ sọ pe EFCC ti ranṣẹ sawọn eeyan yooku ti wọn ba Sadiya ṣiṣẹ ni minisiri naa lati waa sọ tẹnu wọn pẹlu, lorii bi wọn ṣe dari ẹka to wa fun aanu ọmọniyan ati biba wọn koju iṣoro.

Tẹ ẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni Aarẹ Bọla Tinubu da Halima Shehu to jẹ alakooso ajọ NSIPA to n ri si idokoowo araalu, duro lẹnu iṣẹ, to si fi Akindele Egbuwalo, rọpo rẹ.

Lẹyin iyọnipo naa ni iwadii sun kan Sdiya Farouk bayii.

Ara mi ti ko ya ni ko jẹ ki n yọju sawọn EFCC- Sadiya Farouk

AWORAN SADIYA_FAROUQ/X

Oríṣun àwòrán, @SADIYA_FAROUQ/X

Lati tan imọlẹ si ọrọ yii, oṣiṣẹ ajọ EFCC kan to ba BBC sọrọ, sọ pe Sadiya ṣalaye pe ara oun ti ko ya ni ko jẹ koun yọju sawọn ajọ EFCC nigba ti wọn pe oun lori ẹsun naa.

Nigba to n tẹsiwaju ninu alaye to ṣe fun BBC, oṣiṣẹ ajọ EFCC yii sọ pe Sadiya pada beere fun isunsiwaju asiko ipe naa, nitori o ni ara oun ko le to lati yọju si wọn lasiko yii.

Oṣiṣẹ EFCC naa sọ ọ di mimọ, pe minista yii ko gba ipe ajọ EFCC, niṣe lo sọ fun wọn pe ara oun ko ya, ki wọn ba oun sun ọjọ ipe naa siwaju.

O ni EFCC duro de Sadiya fun ọpọlọpọ wakati lọsẹ to kọja lọfiisi wọn, ṣugbọn iya yii ko yọju, bẹẹ ni ko sọ idi kankan ti ko fi jẹpe wọn nigba naa.

Bakan naa ni wọn reti rẹ l’Ọjọruu ọsẹ yii titi tasiko fi lọ pata.

Nibẹrẹ ọsẹ to kọja ni Sadiya Farouk kọ ọrọ kan soju opo X rẹ, nibi to ti ṣalaye pe awọn eeyan n sọ oriṣiiriṣii nipa oun atẹni kan ti wọn n pe ni James Okwete, o loun ko tiẹ mọ ẹni to n jẹ bẹẹ rara.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post