Ṣé lóòótọ́ ni Gómìnà Aiyedatiwa da gbogbo àwọn adelé alága ìjọba ìbílẹ̀ dúró?

Aworan Gomina Ondo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Lucky Aiyedatiwa

Gomina ipinlẹ Ondo Lucky Orimisan Aiyedatiwa ti salaye ohun to sẹlẹ lori iroyin to gbode pe ijọba rẹ gbe iwe lọ rọọkun nile le awọn alaga fidihẹ mejidinlogun lọwọ ni ipinlẹ naa.

Yatọ si awọn yii, iroyin naa tun sọ pe Aiyedatiwa ni ki awọn adari agbegbe idagbasoke ibilẹ mẹtalelọgbọn mii naa lọ fidirẹmi titi asiko ti ọrọ yoo to kan wọn.

Agbẹnusọ Gomina, Ebenezer Adeniyan, sọ fun BBC pe Gomina Aiyedatiwa ko gbaṣẹ lọwọ alaga kankan bi kii ṣe pe ile ẹjọ lọ ni kí wọn lọ rọọkun nile titi asiko ti wọn yoo fi yanju ẹjọ to rọ mọ iṣakoso wọn.

O ni ijọba rẹ kan n fidi aṣẹ ti ile ẹjọ pa ṣaaju rinlẹ ni.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọrọ yi ko sẹsẹ bẹrẹ.

"A ti wa lẹnu rẹ tipe lasiko igba ti gomina lonii fi n dele gẹgẹ bi Gomina. Aiyedatiwa ko gbaṣẹ lọwọ alaga kankan. Ko si ootọ ninu iroyin naa"

Aworan Gomina Ondo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Lucky Aiyedatiwa

Kini idajọ ile ẹjọ da lori.

Oṣu Kẹjọ ọdun 2023 l'awọn alaga ìjọba ibilẹ ni ipinlẹ Ondo pari saa wọn ti ijọba si ni ki wọn fipo silẹ.

Nigba naa lọhun, Lucky Aiyedatiwa lo buwọlu iwe ti o paṣẹ pe ki wọn jọwọ akoso ijoba fawọn to yẹ labẹ ofin.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Idibo sipo lo yẹ ko waye ṣugbọn wọn sun idibo yi bi ẹmeelo kan eyi to mu ki ipo awọn alaga ṣofo.

Nigba ti Gomina Akeredolu pada de lati ilẹ okere to ti lọ fun itọju, o ṣe afikun iye awọn ijọba ibilẹ nípa idasilẹ awọn ijọba ibilẹ agbegbe mii taa mọ si Local Council Development Authority.

Mẹtalelọgbọn ni iye awọn LCDA to da silẹ yi.

Kaka ki idibo waye lapapọ ijọba kede awọn ti yoo maa darí awọn ijọba ibilẹ wọnyii amọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party gba ile ẹjọ lọ pe ki adajọ pàṣẹ idaduro ibura wọle sipo fawọn alaga fidihẹ wọnyii.

Lọjọ ti adajọ gbe idajọ kalẹ pe ki wọn ma ṣe burawọle fawọn alaga fidihẹ yi ki wọn si lọ rọọkun nile gẹgẹ bi aṣẹ ile ẹjọ, l'awọn kan sọ pe iburawọle ti waye ṣaaju ki idajọ yi to de.

Eyi taa ribi fìdí rẹ múlẹ ni pe Gomina Akeredolu ati Adele nigba naa Lucky Aiyedatiwa ko sí níbi iburawọle yi.

Eyi tunmọ si pe ọrọ naa ko lọwọ Akeredolu ati Aiyedatiwa ninu.

Ibeere ti ko foju han ni pe ta lo ṣeto iburawọle fawọn alaga yi ati pe nigba wo ni wọn ṣe iburawọle naa ?

Ibi ọrọ de duro

Agbẹnusọ Gomina Aiyedatiwa to ba BBC sọrọ salaye pe idajọ ile ẹjọ ni Gomina n tẹlẹ kii ṣe pe o le ẹnìkankan kuro lẹnu ipo alaga fidihẹ.

O ni awọn kan ti kuro nipo ninu awọn alaga fidihẹ yi ati pe iwe ti alakoso eto ijọba ibilẹ fi ṣọwọ jẹ bi irannileti ati ifidi rinlẹ idajọ ile ẹjọ gíga lori lilọ rọọkun nile awọn alaga fidihẹ.

Ninu ọrọ rẹ, ko sọ pato asiko ti idibo yoo waye eleyi to jẹ ohun to mu ki ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party fi pe ẹjọ lori iyansipo awọn alaga fidihẹ ti wọn l'awọn tapa si.

Aworan iwe ti adari ijọba ipinlẹ kọ si awọn adele alaga ìjọba ibilẹ