Kò sí ohun tó kàn mí pẹ̀lú ipò igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo - Sowore

Aworan Omoyele Sowore nibi ipade ita gbangba to ti pe fun iyọnipo Gomina Akeredolu lakoko to n ṣaarẹ

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore/Facebook

Oludije sipo aarẹ lorilẹede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC, Omoyele Sowore, lo ti wi pe oun ko ni ohunkohun ṣe pẹlu ipo igbakeji gomina nipinlẹ Ondo.

Sowore lo sọ eleyi lakoko to n ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ lori idi to ṣe fi lede loju opo Facebook pe si ẹnikẹni to n to oun ro ipo igbakeji gomina nipinlẹ naa.

Owurọ ọjọ Abamẹta ni Sowore kọ ọrọ yii soju opo facebook ti gbogbo aye si ti n woye ohun to le muu kọ irufẹ ọrọ yii sita.

Oloṣelu to tun jẹ ajafẹtọ ọmoniyan naa wi pe ni ṣe ni awọn ololufẹ oun bẹrẹ si nii pe oun laarọ ọjọ Abamẹta naa pe wọn rii ka nibi kan pe Sowore fẹẹ di igbakeji gomina nipinlẹ to ti wa.

Oludasilẹ ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters naa wi pe “ko si nkankan to kan mi pẹlu Aiyedatiwa nitori n ko tilẹ mọọ ri.

“Ija taa lọ ja nipinlẹ Ondo pe ki wọn sọ ọ di gomina kii ṣe tori pe a fẹẹ jẹ anfani kan nibẹ, amọ a fẹ ki wọn tẹle ofin Naijiria ni.

“Mo ni awọn aburo nipinlẹ Ondo to jẹ oloṣelu amọ emi ko ni nkankan ṣe pẹlu awọn ọjẹlu to n pe ara wọn ni oloṣelu.”

‘Ko si ohun tuntun kan ti Aiyedatiwa fẹ ṣe nipinlẹ Ondo’

Sowore tẹsiwaju pe oun ko nigbagbọ pe Gomina Aiyedetiwa yoo ṣe ohun ara ọtọ kan nipinlẹ naa.

“Ẹni to di gomina ni Ọjọru to lọ to ti sa lọ ile Tinubu lana, ṣe ko yẹ ki ẹ ti mọ pe aṣẹ ti Tinubu ba pa lo maa tẹle.

Bi Tinubu ba ṣe n dari Naijiria lohun naa ṣe maa dari ipinlẹ Ondo.

“Ati APC ati PDP, ko si iyatọ ninu awọn mejeeji lẹyin orukọ wọn, nitori naa, ẹ ma lero pe o ni nkan gidi kan ti gomina tuntun yii fẹẹ ṣe to maa yatọ si ohun ti Akeredolu ṣe, bẹẹ si ni ko si ohun to lee da mi pọ pẹlu awọn ẹgbẹ mejeeji.

“Akeredolu to yan Aiyedatiwa bi igbakeji mọ pe yoo maa tẹle gbogbo ohun ti oun ba n ṣe lo ṣe yan an.

“Ẹ ma si gbagbe pe idibo miran sipo gomina n bọ lọna. Gbogbo bi yoo ṣe ri owo lati pada wọle sipo gomina ni yoo maa wa.”

Aworan ohun ti Sowore kọ soju opo facebook

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore/Facebook

Njẹ awọn olugbe ipinle Ondo tiẹ le gba ki Sowore ṣe igbakeji gomina?

Ninu akọọlẹ oṣelu nipinlẹ naa, gomina ati igbakeji rẹ ni ko lee wa lati ẹkun kan naa.

Ẹkun idibo sineeti mẹta lo wa nipinlẹ Ondo, mẹtẹẹta yii ni wọn si maa n pin ipo gomina, igbakeji rẹ, ati abẹnugan ile aṣofin si.

Bi apẹẹrẹ, nigba iwalaye Gomina Akeredolu, oun wa lati ẹkun idibo ariwa, igbakeji rẹ, Lucky Aiyedatiwa jẹ ọmọ bibi ẹkun idibo guusu, abẹnugan ilẹ aṣofin tẹlẹ, Bamidele Oleyelogun ati Olamide Oladiji si wa lati ẹkun aringbungbun.

Eyi lo jẹ ilana ti awọn oloṣelu nipinlẹ ti n lo lati ibẹrẹ ijọba awaarawa ti saa yii ni 1999.

Igbagbọ awọn omwoye oṣelu npinlẹ naa si ni pe gbogbo gomina ni yoo maa tẹle ilana yii ti ko ba fẹẹ ri ibinu awọn ẹkun ti yoo yan jẹ to ba yii pada.