Murphy Afolabi, Fadeyi Oloro, Mohbad àtàwọn èèkàn amúlúdùn tó jáde láyé ní 2023

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ti a ba n sọrọ nipa ka mu inu awọn eeyan ọkan gboogi ni agbo ere idaraya lorilẹede Naijiria, paapa awọn to jẹ ti Yoruba ti wa.

Sugbọn iku mu ọpọ wọn lọ ni ọdun 2023.

BBC se akojọpọ awọn eekanlu ati gbajugbaja osere tiata ti wọn jade lọdun 2023.

Murphy Afolabi

Aworan Murphy Afolabi

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Ni owurọ ọjọ Aiku, ọjọ Kẹrinla oṣu Karun un ni Murphy Afolabi jade laye lẹni ọdun mọkandinlaadọta.

Nigba to n fidi iku Murphy Afolabi mulẹ fun BBC Yoruba, alaga ẹgbẹ TAMPAN, Bolaji Amusan tí ọpọ mọ si Mr Latin lo kede ìṣẹlẹ naa.

Latin ni ohun ti o ṣe okunfa iku Murphy Afolabi ko i tii yeni bayii amọ gbajumọ oṣere naa ti papoda.

Ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ lo ti n fi ìroyìn naa soju opo wọn lori ayelujara Instagram tí onikaluku wọn sì ti n ṣe idaro rẹ.

Murphy Afolabi jẹ oṣere tiata Yoruba to gbajumọ fun ipa to saba maa n ko.

Ní ọjọ Karun-un, oṣu Karun-un ọdun 1974 ni wọn bi saye ni ìlu Osogbo, ipínlẹ Osun.

Ile ẹkọ gbogbonìṣe Iree, ipinlẹ Osun lo ti kẹkọọ nipa imọ ere tiata to sì kẹkọọ gboye lọdun 2021.

Ilerioluwa Aloba

Aworan Ilerioluwa Aloba

Oríṣun àwòrán, MOHBAD

Ilerioluwa Oladimeji ti ọpọ mọ si Mohbad jẹ ọkan lara ọmọ lẹyin gbajugbaja olorin takasufe, Azeez Fashola ti ọpọ si Naira Marley.

Oniṣowo orin, Ovie, lo kede iku rẹ loju opo X rẹ lọjọ Kejila oṣu kẹsan an ọidun 2023 ni ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn.

Ọpọ awuyewuye lo ti waye lẹyin ipapoda olorin takausfe naa.

Lara awọn orin rẹ to milẹ titi julọ ni Ponmo, Feel Good, ati KPK ‘Ko Por Ke,’ eyii to gbe jade pẹlu Rexxie, ti wọn si fa kalẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn orin to ta lẹnu julọ fun ami ẹyẹ Headies lọdun 2022.

Ọdun 2020 lo kọkọ gbe awo orin rẹ ‘Light EP’ jade lẹyin orin rẹ ‘Ponmo’to milẹ titi, eyii to ṣe pẹlu Naira Marly ati Lil Kesh.

Lọdun 2021, o wa lara awọn olorin ti awọn eeyan gbọ julọ lori Audiomack ni ẹka orin Afrobeat.

Ojo Arowosafe (Fadeyi Oloro)

Aworan Ojo Arowosafe

Oríṣun àwòrán, Others

Ariwo sọ lori ayelujara lalẹ ati oru mọjumọ Ọjọ keje oṣu kẹta ọdun 2023 lẹyin ti gbajugbaja oṣere tiata, Ojo Arowosafe, ti ọpọ mọ si Fadeyi Oloro jade laye lẹyin aisan ọlọjọ ọlọjọ pipẹ.

Aisan naa ṣee fun nnkan bii ọdun mẹta eyi to sọ ọ di ero ile wosan.

Ko to ku, Fadeyi Oloro rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ orilẹede Naijiria pe ki wọn ran oun lọwọ lori ọwo ti yoo fi ṣe itọju ara rẹ ni ile wosan.

Isẹlẹ yii waye lẹyin ọsẹ mẹta ti Pasitọ kan lati London, Tunde Adeboyega fun un ni miliọnu mẹta lẹyin ti o ṣalabapade fidio rẹ lori ayelujara.

Femi Ogunrombi

Aworan Femi Ogunrombi

Oríṣun àwòrán, WAP TV

Ọjọ kẹrinla oṣu kinni ọdun 2023 ni gbajugbaja osere tiata Femi Ogunrombi ti gbogbo eniyan moͅ si Papa Ajasco jade laye.

Papa Ajasco lo jeͅ ilumoͅoͅka onifiimu ati elere itage nitori ipa to ko ninu ere Papa Ajasco ti ileesͅeͅ reͅ gbe jade.

Femi Ogunrombi lo ko ipa Papa Ajasco laarin ọdun 2005 si 2006.

Arakunrin Femi Ogunrombi ti oͅpoͅ moͅ si Papa Ajasco keͅkoͅ imoͅ orin ati ere tiata jade ni fasiti Oͅbafeͅmi Awolowo University ti Ile-Ifeͅ, ni ipinleͅ Osun.

Papa Ajasco moͅ nipa orin, onkoͅrin ni, oͅmoͅwe ni, to si n dari ere fiimu, to tun n koͅ awoͅn eniyan ni orin.

Mukaila Adedigba

Aworan Mukaila Adedigba

Oríṣun àwòrán, Others

Ni owurọ ọjọ Abamẹta, ọjọ Kẹtala, oṣu Karun-un ni ariwo ẹkun tun sọ ni agboole ere tiata Yoruba.

Gbajumọ oṣerekunrin, Mukaila Adedigba ni oun naa tun jẹ Ọlọrun ni pe.

Kunle Afod ninu awọn atẹjade kan to fi sori Instagram rẹ lo ti kede iku agba oṣere naa.

Sunday Akinola

Aworan Sunday Akinola

Oríṣun àwòrán, Others

Agba oṣere ọhun ni o jẹ ilu mọka lọdun 1980 ati 1990- pẹlu gbajugbaja ere sinima ọsẹsẹ, Feyikọgbọn.

Gbajugbaja oṣere tiata, Sunday Akinola, ti ọpọ mọ si Baba Feyikọgbọn ti jade laye ni ẹni ọgọrin ọdun.

Baba Feyikogbọn jade laye lọjọ Aje Ọjọ kẹsan an oṣu kinni ọdun 2023.

Oluyemi Adeyemi

Aworan Oluyemi Adeyemi

Oríṣun àwòrán, @ADEROJU_ADEYEMI

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Oluyemi Lawrence Adeyemi, ti ọpọ eeyan mọ si Suara naa pẹlu awọn ilumọka to jade laye lọdun 2023.

Ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinlelogun, ọsu Kẹsan an, ọdun 2023 ni oloogbe naa jade laye gẹgẹ bii atẹjade kan ti ọmọ rẹ, Adetoun Adeyemi, fi lede.

Atẹjade naa ni “Pẹlu ibanujẹ ọkan ati ibọwọ fun Ọlọrun ni a fi kede iku baba, ọkọ, baba-baba, ẹgbọn ati ibatan wa, Oluyemi Layrence Adeyemi (suara)....”

Nnkan bii ọdun 2001 ni irawọ Suara bẹrẹ si n milẹ titi lagbo tiata Yoruba.

Ọpọ eeyan bẹrẹ si n mọ orukọ rẹ si ‘Suara’ lẹyin to kopa ninu ere ‘Oh Father, Oh Daughter’ ti ileeṣẹ Wale Adenuga gbe jade.

Lara awọn to ti ba ṣiṣẹ pọ ni Sola Sobowale, Bukky Wright, atawọn agba ọjẹ oṣere mii.