Eré ìdárayá abẹ̀sẹ́kùbìòjò Dambe réè tó dì ìlúmọ̀ọ́ká pẹlú ìtẹ́wọ́gbà orí adé àti ìkànnì ayélujára

- Author, Marco Oriunto
- Role, BBC Africa
Bi oorun ṣe n wọ niluu Kano bẹẹ ni imọlẹ mii n tan lọtọ ni ilu nla to tobi ṣikeji lorileede Naijiria.
Nise ni ilu Kalangu n dun kango kango ni papa iṣere ti awọn ero ti peju wa woran asekagba idije Dambe ti wọn fi pe ori Oba Ado Bayero.
Ariwo awọn ọgọrọ alatilẹyin, ti ọpọ ninu wọn ti de lati owurọ kutu, tun mu ki ariwo maa sọ papọ mọ eruku loju agbo.
Orukọ awọn meji to pegede de asekagba lo gbẹnu wọn bi idije naa ṣe n mura lati bẹrẹ.
Abdullahi Ahmed ti inagijẹ rẹ a maa jẹ Coronavirus sọ fun BBC pe "O ni ilu kan ti wọn a maa da lu lọtọ fun mi kí ija to bẹrẹ loju agbo"
O ni "ilu yi a si maa mu ki ori mi wu lati le ja daada"
"Bí mo ba gbọ ilu yi gbogbo ibẹru pata lo maa yọ kuro lọkan mi"
Ẹni ọdun mọkanlelogun yi ti ṣetán bayi lati koju akẹgbẹ rẹ ninu idije kan ti o bẹrẹ lati nkan bi ẹgbẹrun ọdun sẹyin laarin awọn ẹya Hausa.
Maxwell Kalu to jẹ oludasilẹ African Warriors to jẹ agbatẹru idije yi sọ pe "Orisun Dambe ni ohun ṣe pẹlu lilo ida ati ọkọ lati maa fi ja laye atijọ"
"O jẹ afihan igbaradi awọn ọmọ ogun láti koju ija."
Ninu ere ija yi, awọn oludije a maa fi ọwọ kan ju ẹsẹ ti wọn a si maa fi ẹlẹẹkeji dawọ ẹsẹ ti alatako wọn baa n ju luwọn.
Afojusun wọn ni lati f'ẹsẹ lu alatako wọn ṣubu.
Ṣaaju ọjọ ija yi, Coronavirus ṣe igbaradi lorisirisi ninu aaye igbaradi to wa ní Kano.
Lara ogiri ibi to ti n gbaradi yi la ti ri aworan Ronnie Coleman bo ṣe n safihan egun apa ati iṣan ara rẹ.
Inagijẹ rẹ yi wa latara bi eeyan kan se ṣapejuwe iṣọwọ bo ṣe n fi agbara ja lasiko tó lọ kopa ninu idije kan ni ilu Abuja.
O sọ pe "lati kekere la ti n gburo Dambe tori o jẹ ọkan lara awọn ere idaraya ibilẹ taa ni"
"Lati igba ewe ni mo ti bẹrẹ sii kopa ti mo si n fakọyọ ninu gbogbo ija ti mo ba ja"
Iyipada ti n de si Dambe

Laye igba kan awọn oludije a maa fi ẹrunrun igo sinu ọwọ lati le sakoba fawọn alatako wọn sugbọn wọn ko faaye gba iru isesi yi mọ.
Kalu sọ pe " Ka ma parọ mo ti ri ibi tàwọn eeyan ti farapa gidi gaan nidi ere Dambe yi."
Lara ọna ti wọn yoo fi jẹ ki Dambe tun dara ju tẹyinwa, African Warriors ṣe agbekalẹ awọn ilana tuntun to fi mọ wi pe pínpín abala ija kọọkan si oni iṣẹju mẹta ọtọọtọ.
Wọn tun sagbekalẹ ilana lilo ami ayo.
" A tun ṣe alaye lori nkan to tunmọ si wi pe eeyan fìdí alatako rẹ janlẹ. A tun jẹ kó rọrun ki awọn eeyan maa ribi wo ija yi lai si idiwọ."
African Warriors sọ pe awọn tun ṣe agbekalẹ awọn oṣiṣẹ ilera lati tọju awọn oludije ni gbogbo igba
Coronavirus mọ pataki ṣiṣọ ara ẹni loju agbo.
O sọ pe "Dambe kii ṣe ere idaraya nikan bi kii ṣe pe o jẹ ọna ijẹ ati imu lati gbọ bukaata."
O ni yatọ si ara riro diẹ ati ifarapa loju ati iwaju,ko ju bẹẹ lọ.
Khadija Ahmed to jẹ mama rẹ a maa fa tẹsuba nipa ṣíṣe adua fun ọmọ rẹ.
O mọ iru ewu to wa ninu ere idaraya yi.
"Lati kekere lo ti jẹ ẹni to lagbara.Adura mi ni pe ko lọ ọ ree ko bọ ọ ree ko o si ma kan lapa tabi ẹsẹ ko si ma farapa nibi kankan"
Itẹwọgba ori ade

Awọn alapata ati oniṣẹ ọwọ mii lo kọkọ bẹrẹ ere idaraya Dambe yi t'awọn eeyan a sí máa fi oju abuku wo wọn.
Ṣugbọn pẹlu itẹwọgba ori ade ni ọkan lara ipinlẹ to tóbi julọ ni Naijiria nkan ti n yi pada pẹlu ere idaraya yii.
Ọba Aminu Ado Bayero sọ pe "Origun pataki lo jẹ ninu aṣa wa niluu Kano"
"Gẹgẹ bi afuniṣọ aṣa ati iṣe Kano oju pataki ni mo fi wo Dambe ti maa si maa tẹsiwaju atilẹyin ko baa le laṣeyọri ninu itan ilẹ wa"
Pẹlu iranwọ oju opo ayelujara ere idaraya yii ti di ilumọọka jakejado agbaye.
Ọkan lara awọn ija Dambe tàwọn eeyan wo julọ loju opo YouTube la gbọ pe o le ni iye igba mílíọ̀nù marundinlọgbọn tàwọn eeyan ti wo.
Ẹwẹ, ọkan lara awọn agbatẹru Ultimate Fighting Championship UFC tọwọ bọ iwe adehun pẹlu African Warriors nibẹrẹ ọdun yi.
Ohun iwuri nla sí leyi jẹ fun idagbasoke Dambe.
"Ero mi ni lati fawọn olukopa ninu Dambe ni anfaani ati aaye idanimọ nla ti wọn yoo ti kopa"
Bẹẹ ni Kalu ṣe salaye.
"Yatọ si Naijiria awọn ololufẹ ere yi to wa ni Brasil ati Amẹrika nifẹ si nkan táa n ṣe"
Ẹni ba fakọyọ ni yoo gba ami ẹyẹ

Emir ti balẹ sibi idije naa ninu ọkọ ayọkẹlẹ Rolls Royce rẹ.
Awọn ẹmẹwa yi ori ade naa ka ti Emir si n ba wọn woran bi Coronavirus ati akẹgbẹ rẹ, Audun Tunga ṣe n ju ẹsẹ sí arawọn.
Idile Kuduawa ati Gurumada láwọn mejeeji n soju fún ninu awọn idile mẹta to n kopa ninu idije yìí.
"Ẹni ba fidirẹmi yoo ru igi wọ ọkọ pada sile ti ẹni to ba pegede yoo si ba baalu pada sile"
Ọrọ ẹfẹ ree to n jade lẹnu atọkun eto si awọn to wa peju woran.
Lẹyìn abala mẹta ọtọọtọ ti wọn fi koju ara wọn pẹlu ẹsẹ, oludari kede ẹni jaweolu bori.
Wọn lu ilu lẹẹkan si ti awọn to wa woran sí n pariwo.
Laipẹ wọn da ọwọ Coronavirus soke gẹgẹ bi ẹni to pegede.
O ti jaweolu bori ṣugbọn ofin Dambe sọ pe idile Arewa to gba ami julọ laarin ọjọ meji idije naa ni yoo gba ife ẹyẹ.
Won fun Coronavirus ni ₦150,000 gẹgẹ bi owo aseyori.
Iye yi ṣe deede ilọpo mẹta owó oṣù to kere julọ ni Naijiria.
Iru owo ati ẹbun ti wọn n ri gba yi tun mu ki ọpọ maa wa lati jina wa kopa ninu idije Dambe.
Mali, Burkina Faso, Cameroon ati Niger wa lara awọn orileede t'awọn olukopa ti n wa.
Coronavirus yoo pada sile pẹlu owó tó gba yi pẹlu erongba pe oun yoo fi mu igbesi aye rọrun.
O sọ pe " T'ohun ti bi mo ṣe yan iṣẹ yi laayo mọ n gbero pe ki n ri omiran to dara ju u lọ."
"Mo maa fẹyinti nidi Dambe nigba naa.Igba diẹ ni mo fi n kópa ninu Dambe"















