Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àìsàn Leukaemia àti jẹjẹrẹ ìsétọ̀, Prostate cancer

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọdun 2019 la mu iroyin tọ yin wa pe akẹkọbinrin kan ni Naijiria Chisom Chukwuneke ti awọn eeyan ba ṣe ajọyọ pe o gba A1 meje ninu idanwo WAEC lọdun naa padanu ẹmi rẹ.
Iroyin yi fọwọ kan ọpọ lẹmi tori ọmọ ọdun mẹtadinlogun yi lọpọ foju wo gẹgẹ bi ọmọ ologo.
Nigba ti wọn yoo ṣe iwadii ohun to ṣekupa, esi ti wọn fi sita ni pe aisan jẹjẹrẹ inu ẹjẹ leukaemia lo ṣekupa.
Aisan yi wa lara awọn aisan jẹjẹrẹ to n gba ẹmi ọpọ ni Naijiria nilẹ oni to mọ.
Loju opo ayelujara a fura si pe awọn eeyan n beere nipa asian yi ati aisan jẹjẹrẹ mii,prostrate cancer.
Njẹ ibaṣepọ kankan wa laarin awọn mejeeji ati pe ki ni o yẹ ni mimọ nipa awọn aisan jẹjẹrẹ wọnyii?
Ẹ wa nkan fidi le lati kẹkọ nipa awọn asian wọnyii.
Ki a kọkọ bẹrẹ pẹlu Prostate
Ẹya ara kekere to wa lapa iṣalẹ nkan ọmọ ọkunrin loloyinbo n pe ni Prostate.
Lede Yoruba a le pe ni isetọ tabi orisun oloje agbara atọ.
Prostate jẹ ọkan ninu awọn ẹya to wa ninu egungun ibara idi, o si jẹ ara nnkan ọmọkunrin.
Ẹya ara yii kere pupọ, debi pe ko tobi ju koro ahusa lọ.
O si wa laarin nnkan ọmọkunrin ati ile itọ, o si yi ọpa to n gbe itọ jade ninu ara ka.
Prostate yi lo ma n sẹto eroja to n pese atọ ọmọkunrin.
Bi ọkunrin ba ti n dagba si, o ṣeeṣe ki Prostate rẹ yi maa tobi ju ti tẹlẹ l.
Amọ ti kokoro aisan jẹjẹrẹ ba wọ inu rẹ, o di Prostate Cancer niyẹn.
Ohun to maa n ṣokunfa aisan jẹjẹrẹ Prostate ko lakọsilẹ ṣugbọn o ni awọn nkankan to le jẹ ki eeyan wa ninu ewu aisan jẹjẹrẹ yi.
Ko si alaye lori rẹ ṣugbn awọn ọkunrin alawọdudu lo maa n ṣaba ni aisan jẹjẹrẹ Prostate yi ju awọn alawọfunfun lọ.
Awọn ọkunrin ti baba wọn tabi ọmọ iya wọn lọkunrin ba ko aisan yi naa a maa saba ko aisan jẹjẹrẹ yi
Iwadii tun fi han pe awọn ọkunrin to ba sanra wa ninu ewu kiko aisan jẹjẹrẹ Prostate ju awọn ti ko sanra pupọ.
Awọn apẹrẹ aisan yii
Awọn apẹrẹ aisan jẹjẹrẹ yi ko pọ ni igba to ba ṣi kọkọ wa lara idi si ni pe ibi to sa pamọ si lara ko le jẹ ki eeyan tete mọ.
Die ninu awọn nkan mii taa le ri ni pe ọkunrin a maa ji tọ pupọ ni paapa loru.
O maa n ṣe eeyan to ba ni aisan jẹjẹrẹ yi bi igba pe ko sare lọ ṣe ẹyọ.
Itọ to ba n jade lara ko ni lagbara tabi ki onitọhun si maa koju inira ko to ribi tọ
Pipẹ lori itọ tabi ki o si dabi pe itọ ṣi ṣẹku ninu apo itọ lẹyin ti eeyan ba tọ tan.
Ayẹwo

Oríṣun àwòrán, others
Ayẹwo se pataki gẹgẹ bi ọna kan gbogi ti eeyan le fi tete koju aisan jẹjẹrẹ Prostate.
Ibi ti wahala si wa ni tori ọpọ ni kii lọ fun ayẹwo lasiko titi ti aisan naa yoo fi ti joko si agọ ara wọn.
Ko si ayẹwo orisi kan pato bi kii ṣe pe awọn onimọ iṣegun a maa lo eyi ti wn ba ri pe yoo fun wọn ni esi ti wn ba fẹ.
Lara ayẹwo taa n wi yi leyi to niṣe pẹlu ẹjẹ,gbigba diẹ lara ẹya ara fun ayẹwo taa mọ si biopsy, ati omiran ti wọn a maa tika bọ furọ ọkunrin to ba lọ fun ayẹwo lati le ribi ti iṣetọ rẹ wa.
Awọn ayẹwo yitabi apapọ wn ni awọn oniṣegun a maa lo lati le mọ bi aisan jẹjẹrẹ yi ṣe n dagba si lara eeyan.
Iye awọn to n ba aisan yi lọ ni Naijiria
Gẹgẹ bi a ṣe salaye ṣaaju pe aisan jẹjẹrẹ Prostate yi a maa saba daamu awọn ọkunrin alawọdudu ju awọn alawọ funfun lọ.
Nilẹ Africa Naijiria ni ibi tawọn eeyan pọ si julọ toiri naa ninu awọn alawọdudu to n ba aisan yi lọ ti Naijiria ko kere.
Akọsilẹ taa ri sọ pe ida meji lo wa ninu ewu aisan jẹjẹrẹ yi.
Lọdọọdun o sọ pe eeyan ẹgbẹrun lọna ogun ni aisan jẹjẹrẹ yi maa n pa ni Naijiria
Lọpọ igba ayẹwo ile iwosan a maa fihan pe awọn ti aisan yi ti wle siwọn lara lo pọ julọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Jẹjẹrẹ inu ẹjẹ Leukaemia
Aisan jẹjẹrẹ eleyi jẹ eyi to n ṣe akoba fun ẹjẹ debi pe ko ni le koju kokoro aifojuri to n ṣakoba fun ara.
O nii ṣe pẹlu awọn sẹẹli funfun ti a si ma bẹrẹ ninu ẹgungun.
Ọpọ eeyan to ni aisan jẹjẹrẹ yi ni kii ni apẹrẹ afihan pe o wa lara wọn.
Amọ awọn apẹrẹ taa tun le ri niwọnyi:
- Oju eeyan yoo funfun ti yoo si maa tete rẹ iru ẹni bẹẹ to ba ṣe iṣẹ agbara
- Yoo maa ni ko kokoro loriṣiriṣi lẹnu,ọna ọfun
- Ara wọn a maa gbona loore koore
- Itọ titọ lemọ lemọ
- Egungun yoo maa dun ẹni to ba ni aisan jẹjẹrẹ yi
- Yoo maa bi, ko ni rina daada ori fifọ ati awọn apẹrẹ mii.
Itọju ati ayẹwo
Awọn onimọ sayẹnsi lawọn kole sọ pato ohun to n ṣokunfa aisan jẹjẹrẹ inu ẹjẹ yi.
Amọ wọn ni awọn nkankan a maa jẹki awọn eeyan wa ninu ewu lati ko aisan jẹjẹrẹ yi.
Ninu rẹ ni pe ki wọn ṣalabapade kẹmika kọ́kan bi benzene
Kokoro aifojuri bi Human T-Cell leukaemia virus naa le mu ki eeyan wa ninu ewu kiko aisan jẹjẹrẹ yi.
Bi awọn dokita ba ti fura si pe eeyan ni aisan jẹjẹrẹ yi, wọn yoo ṣe ayẹwo ẹjẹ ,gbigba ẹya ara bi mudunmudun to wa ninu egunegun eeyan,bone marrow,ayẹwo ẹrọ Xray ati ayẹwo egungun ẹyin eeyan.
Lọpọ igba itọju aisan yi a maa waye latari bi aisan jẹjẹrẹ inu ẹjẹ naa ba ṣe lagbara si.
Bi wọn ba ti ṣe kẹfin pe eeyan ni aisan yi lara naa ni wọn ti ṣalaye pe ki eeyan bẹrẹ itọju lai fi asiko ṣofo.












