Dey play, Idan, Floating Berries, àti àwọn àṣà ṣajẹ tó milẹ̀ tìtì ní 2023

Oríṣun àwòrán, others
Oriṣiriṣi iṣẹlẹ lo ṣẹlẹ ni Naijiria lọdun 2023.
Bi iṣẹlẹ kọọkan, ninu eyi ta a ti ri idibo gbogboogbo, ọwọn gogo Naira, ati awọn mii ni ẹka amuludun, ṣe waye, ni wọn fi awọn nnkan iranti silẹ.
Oriṣiriṣi ṣajẹ lo jade lati ara awọn iṣẹlẹ naa, ati lati ọdọ awọn amuludun, eyi ti awọn ọmọ Naijiria, paapaa awọn ọdọ ti sọ di aṣa ti wọn n da nigboro bayii.
A ṣe agbeyẹwo diẹ lara awọn to wọpọ ninu awọn ṣajẹ to milẹ titi lọdun 2023.
Dey Play
Awọn ọdọ Naijiria lo ṣa ba ma n da aṣa yii. O jẹ na ti wọn fi ma n sọ fun eeyan lati ye e tan ara rẹ jẹ tabi fi akoko rẹ ṣofo lori nnkan ti ko ṣe e ṣe. Fun apẹẹrẹ, boya eeyan kan sọ pe
Idan
Botilẹ jẹ pe idan jẹ ọrọ kan ninu ede Yoruba paapaa ninu iṣẹ awọn pidanpidan, ọrọ naa tun gba ọna ọtọ si gbajumọ laarin awọn ọmọ Naijiria lọdun 2023.
Idan di aṣa lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubi lo o, lasiko ti ipolongo ibo ọdun 2023 waye.
Itumọ ti Idan gẹgẹ bi aṣa ni, ni ẹni to jẹ akinkanju, to n sẹ nnkan ara t tabi to ni agbara.
You go explain taya, no evidence
Gbajugbaja akọrin takasufe, Burna Boy, lo kọkọ lo aṣa No Evidence yii. Eyi tumọ si pe ko si bo ṣe mọ ẹjọ ro to, tabi ṣe alaye to, awọn eeyan ko ni i gba nnkan to n sọ gb lai ni ẹri lati fi gbe ẹjọ rẹ l’ẹsẹ.
Let the poor breathe

Oríṣun àwòrán, others
Yatọ si Idan, aṣa ‘Let the poor breathe’ tun ti ẹnu Aarẹ Tinubu jade.
Aarẹ Tinubu lo aṣa naa lasiko ipolongo ibo lati rawọ ẹbẹ si awọn olori Naijiria pe ki wọn o jẹ ki awọn alaini lawujọ o rimu mi, paapaa nigba ti wọn ba n ṣe awọn ofin tabi ilana iṣejọba tuntun, to le fun okun mọ awọn mẹkunnu lọrun.
Ni bayii, awọn ọmọ Naijiria n lo aṣa ‘Let the poor breathe’ tabi ‘Let the singles breathe’paapaa lasiko ti awọn ololufẹ kan ba fi aworan tabi fidio ara wọn sita. Eyi tumọ si pe, ki awọn ololufẹ naa ma fi ifẹ yan awọn ti ko ni ololufẹ loju.
On colos
Colos jẹ adape ọrọ fun oogun oloro Colorado. Ọrọ naa di aṣa ni Naijiria lọdun 2023, pẹlu bi awọn ọdọ ṣe ma n lo o fun ẹni ti iṣe, iwa tabi isọrọ rẹ ko ba ti araye mu. Eyi jẹ ọna lati tka si pe boya oogun oloro lo jẹ ki ẹni naa hu iwa tabi sọrọ bẹẹ.
Groceries ati floating berries

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọrọ yii ni awọn ọdọ Naijiria fi n ṣe adape fun isẹ ati oṣi eyi ti wọn n pe ni ‘Sapa’.
Wn n fi groceries pe Gari – awọn alakọwe lo ma n lo groceries fun awọn oriṣiriṣi nnkan jijẹ ati minu ti wọn n ra ni awọn ile itaja nla.
Awọn ọdọ n lo floating berries fun ẹpa ti a fi n mu gari- sẹ ẹ mọ pe ẹpa ma n lefo si ori gari ni.












