Owó tí Alao-Akala san fún mi lásìkò ìpolongo ìbò ni mo fi lu àlùyọ - Taye Currency

Alao Akala ati Taye Currency

Oríṣun àwòrán, Others

Gbajugbaja olorin Fuji ti o tun jẹ ọmọ ilẹ Ibadan, Alhaji Taye Adebisi ti ọpọ eeyan mọ si "Taye Currency" ti ṣe alaye bi Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ọyọ, oloogbe Christopher Alao-Akala ṣe mu ki oun lu aluyọ.

O ni miliọnu mọkandinlọgọrun naira(99M) ti gomina tẹlẹ ri ọhun san, lẹyin ti oun kọrin nibi ipolongo ibo rẹ lọdun 2011 lo ṣe bẹbẹ laye oun.

Taye Currency ṣe alaye ọrọ naa nibi ode ariya kan ti o ti ṣe ere opin ọdun fun awọn ololufẹ rẹ ni agbegbe Oshodi niluu Eko, ti fọnran ọrọ naa si ti bẹrẹ sini ja rain-rain kaakiri ori ayelujara.

Olorin naa ṣe alaye wi pe ẹni ti wọn fi ṣe akoso awọn olorin lati polongo ibo fun Alao Akala ko fi owo jiṣẹ gẹgẹ bi wọn ṣe fi ran an, eyii lo mu ki oun lọ si ile Akala lati lọ fi ẹhonu han.

Ni ibi to ti lọ fi aidun inu rẹ han nile Akala lo si ti ṣe oriire, nitori Gomina tẹlẹri naa baa pade, o si ni ki aya rẹ, Arabinrin Kemi Akala bẹrẹ sini mojuto bi wọn ṣe n san owo olorin fuji naa.

Lẹyin eyii lo gba miliọnu mọkandinlọgọrun naira fun orin ipolongo ibo ti o kọ lẹyin Ọtunba Alao-Akala jakejado ijọba ipinlẹ mẹtalelọgbọn to n bẹ n'ipinlẹ Ọyọ.

Taye Currency ni, "lọjọ naa, mo wa ni ile gomina tẹlẹri naa. Nigba ti o jade sita, mo bẹrẹ sini pariwo pe wọn ko san owo iṣẹ ti mo ṣe.

"Mo si pinnu pe mi o ni ṣiṣẹ fun wọn mọ.

"Alao-Akala wa pe mi lati mọ iredi ti mo fi n pariwo.

Mo ṣe alaye wi pe awọn alakoso ipolongo ibo naa n jẹ mi ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira(#500,000), mi o si ri owo mi gba.

Pẹlu iyalẹnu ni Alao-Akala fi ke si aya rẹ, Arabinrin Kẹmi Alao-Akala lati bẹrẹ sini san owo fun mi lati akoko naa lọ".

Lẹyin eleyii ni Taye Currency gba milliọnu mọkandinlọgọrun Naira, ti o si jẹ ere ọgọta milliọnu naira lẹyin ti o san gbogbo gbese to wa lọrun rẹ tan.

Taye Currency ni oun ti fi iru igboya naa ba eekan oloṣelu nilẹ Ibadan, oloogbe Oloye Lamidi Adedibu sọrọ ri nigba aye rẹ nitori lẹyin ti oun ṣiṣẹ orin fun oloṣelu naa, awọn ti wọn fi owo ran si oun kọ lati fi owo jiṣẹ.

Igba akọkọ kọ niyii ti awọn olorin yoo maa fọn rere oloogbe Alao-Akala lori ayipada to mu ba aye wọn.

Gbajugbaja olorin, Yinka Ayefẹlẹ naa ti ṣe alaye ti o pọ lori oore ti Alao-Akala ṣe. Yatọ ọrọ ti Ayefẹlẹ fi lede nipa oloogbe naa, o tun kọ orin fun Alao-Akala.

Ninu iroyin kan ti a gbe jade ninu oṣu Kinni, ọdun 2022, lẹyin iku gomina tẹlẹri naa, Yinka Ayefele sapejuwe iku Otunba Adebayo Alao Akala, gẹgẹ bi adanu nla fun oun gẹgẹ bi ẹnikan ati idile oun.

O ni, "ko si bi mo ṣe le kọ nipa itan igbesi aye mi laye ti mi o ni kọ nipa Otunba Adebayo Christopher Alao Akala".

Ninu atẹjade kan to fi sita, Ayefele sọ pe lara awọn oluranlọwọ kadara oun ni Alao Akala wa, to si tun jẹ ẹbun Ọlọrun fun ipinlẹ Oyo ati Naijiria lapapọ.

Ayefele ni oun dupẹ fun bi oloogbe naa ṣe ṣe atọna bi oun se n kọrin fun àwọn olokiki ati awọn eniyan nla, to fi mọ ileesẹ aarẹ, paapaa igbakeji aarẹ tẹlẹ, Atiku Abubakar ati awọn mii.