Iléeṣẹ́ ológun bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ẹ̀sùn aṣemáṣe tí sójà obìnrin fi kan àwọn ọ̀gá rẹ̀ nítorí kíkọ̀ láti bá a lòpọ̀

Àwọn ológun

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN ARMY/FACEBOOK

Iléeṣẹ́ ológun orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti fèsì sí fídíò kan tó gba orí ayélujára.

Nínú fídíò náà ni obìnrin kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ológun Nàìjíríà ti fẹ̀sùn kan àwọn ọ̀gá kan ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ológun ti ìpínlẹ̀ Eko pé wọ́n ń fúngun mọ́ òun lẹ́nu iṣẹ́.

Àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ ológun fi sórí ẹ̀rọ ayélujára wọn lọ́jọ́ Kẹtàlá oṣù Kìíní ọdún 2024 ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí àwọn ẹ̀sùn tí obìnrin náà fi kan àwọn ọ̀gá rẹ̀.

Wọ́n ní àwọn máa gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ ní kété tí àwọn bá ti parí ìwádìí àwọn.

Èsì iléeṣẹ́ ológun yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ní ó pọn dandan fún wọn láti ṣe ìwádìí àwọn ẹ̀sùn tí ọmọbìnrin náà fi kan àwọn ọ̀gá rẹ̀, kí wọ́n bà le fi ìdí òótọ́ múlẹ̀.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Kí ni ọmọbìnrin sójà náà sọ nínú fídíò rẹ̀?

Ọmọbìnrin tó jẹ́ òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ ológun náà kò sọ orúkọ ara rẹ̀ nínú fídíò tó gbé jáde àmọ́ tí orúkọ tó wà lórí Tiktok rẹ̀ ń jẹ́ @ogumleyeruthsavage1 sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ìlàkàkà tó ń kojú lẹ́nu iṣẹ́.

Ó kọminú lórí bí àwọn ọ́gá kan lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ tó pe orúkọ wọn ní Ọ̀gágun I.B. Abdulkareem, ọ̀gágun G.S. Ogor àti ọ̀gágun I.B. Solebo.

Ó ní àwọn ọ̀gá náà ń mú ìgbé ayé nira fún òun láti ìgbà tí wọ́n ti gbé òun lọ sí ẹ̀ka Cantonment Medical Centre, tó wà ní Ojo ní ìpínlẹ̀ Eko láti ọdún 2022 nítorí òun kọ̀ láti gbà kí wọ́n bá òun sùn.

Ó ní tí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ sí òun àwọn ọ̀gá náà ni kí àwọn ènìyàn fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà kọ́ lọ́rùn.

Nínú fídíò náà ló ti ṣàlàyé pé ọ̀gágun Abdulkareem ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti fìyà jẹ òun, ó ní ó fún òun ní abẹ́rẹ́ lọ́nà àìtọ́, tó sì lé òun kúrò ní ilé tí òun ń gbé.

Bákan náà lọ ṣàlàyé pé gbogbo ọ̀nà tí òun gbà láti gbara òun kalẹ̀ ló já sí pàbó àti pé tí àwọn ènìyàn bá fẹ́ ran òun lọ́wọ́, ọ̀gágun Abdulkareem ma sọ fún wọn pé òun ní ààrùn ọpọlọ.

Ó ní èyí ló mú kí wọ́n tí òun mọ́ ilé ìwòsàn tí wọ́n ti máa ń tọ́jú àwọn tó bá ní ààrùn ọpọlọ fún oṣù kan.

Ó fi kun pé ọ̀gá náà kò fẹ́ kí òun gòkè lẹ́nu iṣẹ́ nítorí kò gba òun láàyè láti jẹ́ kí òun lọ fún àwọn ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ tí yóò ran òun lọ́wọ́ gòkè lẹ́nu iṣẹ́ òun.

Skip TikTok post
Allow TikTok content?

This article contains content provided by TikTok. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read TikTok cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites. TikTok content may contain adverts.

End of TikTok post

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Ní ọdún 2022 ni wọ́n gbé mi lọ sí ẹ̀ka Cantonment Medical Centre, Ojo níbi tí mo ti pàdé ọ̀gágun I.B. Abdulkareem, ẹni tó kọ ẹnu ìfẹ́ sí mi tí mo sì kọ̀ jálẹ̀.

“Láti ìgbà náà ni ó ti máa ń fúngun mọ́ mi , tó sì máa ń sọ pé òun máa ri dájú pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ mi.

“Ó wá lémi kúrò ní ilé tí mò ń gbé, tó sì rán ènìyàn kan láti wá dúnkokò mọ́ mi, mo ní àwọn ẹ̀rí tí mo lè fi gbe àwọn ẹ̀sùn yìí lẹ́sẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni mo ní àwọn ènìyàn tó lè jẹ́rìí mi.

“Ọ̀gágun yìí máa ń fẹ̀sùn kàn mí pé mo ní ààrùn ọpọlọ nígbà tí mo bá bá àwọn ọ̀gá mìíràn sọ̀rọ̀ láti ràn mí lọ́wọ́.”

“Láti inú oṣù Kejì ọdún 2023 ló ti gbẹ́sẹ̀ lé owó oṣù mi, tí mi ò rí oṣù gbà mọ́.”

Ó tẹ̀síwájú pé bàbá òun ti fẹ́ bá òun dá sí ọ̀rọ̀ náà àmọ́ ọ̀gágun náà sọ fún bàbá òun pé àfi kí òun ṣe ohun tí òun ń fẹ́.

Ó ní òun mọ̀ pé fídíò tí òun ń ṣe náà yóò ṣe àkóbá fún òun àmọ́ òun kò kọ ohun tó máa ti ẹ̀yìn rẹ̀ jáde nítorí òun kò lè mú ìṣẹ̀lẹ̀ náà mọ́ra mọ́.

Ó wá rọ gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ran òun lọ́wọ́, kí wọ́n yọ òun ní ìgbèkù àwọn ọ̀gá ọ̀hún.

Kí ni iléeṣẹ́ ológun sọ?

Iléeṣẹ́ ológun nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi sórí ẹ̀rọ ayélujára X wọn ṣàlàyé pé àwọn ní ìfarajìn sí ìgbáyegbádùn àwọn òṣìṣẹ́ àwọn.

Wọ́n ní àwọn máa ṣe ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí àwọn sì máa gbé ìgbésẹ̀ tó tọ́ lórí rẹ̀.

Wọ́n rọ àwọn ọmọ Nàijíríà láti ṣe sùúrù pẹ̀lú àwọn kí àbọ̀ ìwádìí àwọn fi jáde.

Ṣáájú ni agbẹnusọ iléeṣẹ́ ológun, Nwachukwu Onyema ti kọ́kọ́ fi léde pé sójà náà kò fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó àwọn ẹ̀ka tó yẹ létí kó tó di pé ó ṣe fídíò tó gbé jáde.

Àmọ́ ó ní àwọn ti wà lórí ọ̀rọ̀ náà tí àwọn yóò sì fi ìdí òótọ́ múlẹ̀.