AFCON 2023: Ivory Coast f’àgbà han Guinea-Bissau pẹ̀lú àmì ayò méjì s’ódo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹ-ede Ivory Coast to n gbalejo idije ere bọọlu ilẹ Afrika (AFCON) fun ti ọdun 2023, ti fagba han Guinea -Bissau pẹlu ami-ayo meji si odo, eyi to wa waye ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ idije naa.
Atamatase Seko Fofana lo ṣide aṣeyọri naa fun ikọ agbabọlu Elephant lati Ivory Coast, nigba to gba bọọlu sawọn lai ti i ju iṣẹju mẹrin ti ayo naa bẹrẹ lọ.
Diẹ lo ku ko tun ju ami-ayo keji sawọn ki wọn too pari ipele akọkọ ifẹsẹwọnsẹ ọhun, bi ko ba jẹ ti Ouparine Djoco to kapa rẹ ni.
Jean-Philippe Krasso lo pada gba ami-ayo keji sawọn fun Ivory Coast lẹyin ti wọn jọ gera wọn daadaa pẹlu igun agbabọolu Guinea Bissau.
Oṣu mẹfa ti wọn fi sun Idije AFCON yii wọ 2024 nídìí

Oríṣun àwòrán, @Google
Ọdun 2023 lo yẹ ki idije AFCON yii ti waye, wọn sun si oṣu kin-in-ni ọdun 2024 yii ti ki i ṣe asiko ojo ni.
Ibẹru asiko ojo ni Iwọ-Oorun Afika to ṣee ṣe ko di eto naa lọwọ ni wón ṣe gbe e si oṣu akọkọ ninu ọdun 2024.
Bi wọn ṣe sun akoko idije naa siwaju lo waa pada jẹ anfaani nla fun orilẹ-ede Ivory Coast lati parii gbogbo eto to yẹ.
Owo ti wọn yoo fi gbalejo naa le ni biliọnu kan owo dọla ($1bn.)
Ọdun 1992 ATI 2015 ni orilẹ-ede Ivory Coast ti gba ifẹ-ẹyẹ AFCON gbẹyin, wọn ti bẹrẹ iṣẹ lati ri i gba lọdun yii naa, bo tilẹ jẹ pe Sebastien Haller ti i ṣe ẹlẹsẹ ayo wọn ti fara ṣẹsẹ ti ko si le kopa.
Aago meji ọsan oni, Sannde ọjọ kẹrinla oṣu kin-in-ni ọdun 2024, ni ikọ agbabọọlu Naijiria yoo koju Equatorial Guinea, iyẹn ni ipin A keji, nigba ti Egypt to ṣepo keji ninu ife-ẹyẹ AFCON ni 2021 ati Ghana to ti gba a lẹemẹrin, yoo koju ara wọn ni ipin B keji lonii, Sannde kan naa.














