Ọwọ́ tẹ afurasí ọkùnrin tó jí ọmọ ọdún mẹ́jọ sínú àpò l'Ondo

Oríṣun àwòrán, Amotekun Ondo
Ọdọkunrin kan, Usman Bello, ọmọ ọdun mẹrinlelọgbọn, to mura bi ẹni to n ṣa ilẹ ni ọwọ ti tẹ nibi to ti ji ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹjọ kan gbe nilu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo.
Ọkunrin afurasi naa ni wọn wi pe o gbe ọmọdebinrin naa sinu apo to n ṣalẹ si to si fẹẹ maa gbe e lọ.
Ẹwẹ, ẹkun ọmọdebinrin naa lo mu ki iya-baba rẹ jade lati wo ohun to n ṣẹlẹ ki o to rii pe inu apo lo ti n sunkun.
Adari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Akogun Adetunji Adeleye, wi pe ọkunrin ọhun na ọmọdebinrin naa loogun, to si sare ju u sinu apo to mu lọwọ ki ọwọ palaba rẹ to segi.
Ojulowo ajinigbe ni ọkunrin naa - Amotekun

Oríṣun àwòrán, Amotekun Ondo
Adeleye wi pe ni ṣe ni ọkunrin fi ọgbọn mura bi ẹni to n ṣa ilẹ kiri adugbo, amọ to jẹ ojulowo ajinigbe.
“Nigba ti a fi ọrọ waa lẹnu wo, a rii pe ajinigbe pọnbele ni ọkunrin naa, ati pe o ti pẹ diẹ lẹnu iṣẹ naa.
“Iwadii wa ṣi tẹsiwaju tori pe a fẹẹ mọ awọn to ran an niṣẹ ati ohun to fi awọn ọmọ to ti jigbe tẹlẹ ṣe.
“Ohun idunnu ni pe ọmọ ọdun mẹjọ wa lalaafia, ti iya-baba rẹ ti ajinigbe naa fi ogunna lu si n gba itọju nileewosan wa.”
Adeleye, to tun jẹ olugbaninimọran pataki fun gomina ipinlẹ Ondo lori eto abo waa rọ awọn obi lati moju to awọn ọmọ wọn ti wọn ba n ṣere layika ile.
O wi pe pupọ ninu awọn to n ṣalẹ kiri adugbo yii lo jẹ adigunjale tabi ajinigbe ti wọn fi ọgbọn wo agbeegbe ti wọn yoo ti ṣọṣẹ, abi ki wọn jẹ agbodegba fun awọn ti yoo waa ṣe iṣẹ laabi naa.
O fikun pe ọkunrin naa ni yoo foju ba ileẹjọ lẹyin ti iwadii ba pari.
‘Iyaa mi ni ko jẹ ko ri ọmọ naa gbe lọ’

Oríṣun àwòrán, Amotekun Ondo
Baba ọmọdebinrin ti wọn fẹẹ jigbe ọun, Bose James, to jẹ ọmọ ọgbọn ọdun ṣalaye pe ọjọ Iṣegun, ọjọ kẹsan, oṣu kini ọdun yii ni iṣẹlẹ naa ṣẹ.
Gẹgẹ bi o ṣe wi, o ni aṣọ loun n fọ lasiko naa, ti iya ohun si n wo ẹrọ amohunmaworan ninu ile.
“Ọmọ taa wi yii waa bami pe oun fẹẹ ṣe igbọnsẹ lẹyinkule, mo si ni ko maa lọ.
“Ẹkun rẹ ti iyaa mi gbọ lo mu ki wọn jade sita ki wọn too rii pe ọkunrin aboki kan taa ri to n ṣalẹ ti gbe ọmọ mi sinu apo to n ṣalẹ si.
“Bi iya mi ṣe figbe ta ni ọkunrin naa ti fi ogunna dabira sii lara ki n too de'bẹ.
“Bi mo ṣe rii ni mo di ṣokoto rẹ mu, amọ to n doju ija kọ gbogbo ẹni to ba fẹẹ gba ọmọ naa lọwọ rẹ.
“Ọlọkada kan to n kọja lọ lo sare lọọ pe awọn Amọtẹkun wa lorita Maronu ti wọn fi waa mu ọkunrin naa.”
James wi pe inu oun dun pupọ fun bi awọn ikọ Amọtẹkun naa ṣe de ni kia lati gba ọmọ oun silẹ ti wọn si fi ṣikun ofin mu afurasi ọdaran naa.















