Gloria Maya Musu-Scott: Adájọ àgbà Liberia gba ìdájọ ẹ̀wọ̀n gbére lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn

Aworan Maya Musu-Scott

Oríṣun àwòrán, EPA

Adajọ agba tẹlẹ ri lorile-ede Liberia, Gloria Maya Musu-Scot ti gba idajọ ẹwọn gbere lori isekupani Ibatan rẹ.

Idajọ yi lamilaaka tori pe o jẹ bi iṣubu nla fun adajọ ati oloṣelu to gbajumọ julọ to sì tun rí ara rẹ gẹgẹ bi ajafẹtọ-ọmọniyan awọn obinrin.

Musu- Scot ẹni aadọrin ọdun ti wa lẹwọn bayii to si ni ireti pe idajọ yi yoo yi pada.

Adajọ kan lo gbe idajọ yi kalẹ fun adajọ fẹyinti lẹyin ti igbimọ to n gbẹjọ da l'ẹbi iṣekupani Charloe Musa ẹni ọdun mọkandinlọgbọn

Igbẹjọ fìdi rẹ mulẹ pe Musu-Scott pẹlu awọn obinrin mẹta mii mọọmọ, f'inu fẹdọ gbimọran da ọgbẹ si ara ibatan rẹ ninu ile rẹ loṣu Kẹfà ọdun to kọja.

Musu fara ṣeṣe ni aya, apa ọtun,itan osi ati labẹ abia lẹyin ti wọn fi ọbẹ gun gẹgẹ bi iwe idajọ ṣe wi.

Adajọ agba tẹlẹ ri naa tako ẹsun yi to si ni agbanipa to gba ọna ẹyin wọle lo sẹku pa arabinrin naa nile rẹ to wa ni olu ilu ilẹ naa Monrovia.

Iyalẹnu nla lo jẹ fawọn araalu pe wọn mu adajọ yi ti ọpọ si n fi ọkan tẹle idajọ yi paapa pẹlu bi idibo aarẹ ṣe n sunmọ ni oṣu Kejila.

Tani Gloria Maya Musu-Scot?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Adajọ agba tẹlẹ ri yi jẹ ọkan lara awọn eekan agbẹjọro ẹgbẹ oṣelu aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan Joseph Boakai.

Igbimọ agbẹjọro ẹgbẹ aarẹ yi lo koju ajọ eleto idibo to fariga pe awọn ko ni ṣe afihan iwe orukọ awọn okudibo han faraye.

Niṣe l'awọn ẹbi ara ati alatilẹyin adajọ yi bu s'ẹkun nigba ti adajọ Roosevelt Z Willie gbe idajọ kalẹ lori oun ati awọn obinrin mẹta mii.

Ọjọ ori awọn ti wọn da lẹjọ yi ni ọgọrin ọdun, mẹrindinlogoji ati ogun ọdun gẹgẹ bi awọn ileeṣẹ iroyin labẹle ṣe jabọ.

O di ipo Minisita feto idajọ Liberia to sì tun jẹ adajọ agba patapata ile ẹjọ to ga julọ ni Liberia titi di igba to feyinti nidi iṣẹ lọdun 2003.

O pada dara pọ mọ oṣelu to si jẹ aṣofin ẹkun Maryland titi 2012 gẹgẹ bi oju opo ayelujara awọn obinrin Africa lẹka ìmọ ofin ṣe wi.

Ni 2012 wọn yan si ipo alaga igbimọ to n ṣe agbeyẹwo iwe ofin nigba ti Liberia n gbiyanju lati f'agbara fun ijọba awaarawa lẹyin aimọye ọdun labẹ ìjọba amunisin to waye sẹyin.

Agbẹjọro rẹ Augustine Fayiah sọ fun BBC pe awọn yoo tako idajọ yi laipẹ.

O ni itako yi yoo ka awọn aṣiṣe ti adajọ ṣe lori igbẹjọ yi.

" Igbesẹ awọn igbimọ idajọ lọwọ itojubọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ idajọ"

Lẹyìn idajọ naa loṣu to kọja agbẹjọro olupẹjọ kan láwọn eeyan gbọ to sọ pe ẹrí to lagbara lo wa nilẹ eyi toun gbagbọ pe o jẹ ki wọn gbe ojulowo idajọ kalẹ.

Ọjọ kejilelogun oṣu Kini ni wọn yoo bura wọle sipo fún arakunrin Boakai lẹyin to fidi aarẹ George Weah rẹmi ninu idibo.