Wo bí àwọn ọkùnrin India tó fẹ́ ṣiṣẹ́ ẹni tó lè fún obìnrin lóyún ṣe bọ́ sọ́wọ́ gbájúẹ̀

Aworan oloyun

Oríṣun àwòrán, GETTY IMAGES

Ko fẹẹ si iru ọna t'awọn ọmọ jibiti ko tii lo tan lati fi gba owo lọwọ awọn eeyan.

Amọ eleyi taa mu wa fun un yin lati India pakasọ.

Oju opo Facebook, loṣu Kejila, ọdun ni Mangesh Kumar (a yi orúkọ rẹ pada) wa to ti salabapade fidio lati ọwọ ileese kan "All Pregnant Job Service" pade.

O yẹ iṣẹ naa wo to sì jẹ iyalẹnu iru owo to rọ mọ ọ.

Ki si ni wọn ni yoo ṣe?

Fun obìnrin loyun ko si gba owo tabua ni wọn sọ pe iṣẹ ti wọn fẹ ki ọdọkunrin yii ṣe fun wọn.

Baa ṣe n sọrọ yi owo oṣu ẹni ọdun mẹtalelọgbọn yii ko ju nkan bi 15,000 rupees owo India to ṣe deedee ($180; £142)

Awọn gbajuẹ to polowo iṣẹ to ri yi ti gba owo to ju ẹgbẹrun merindinlogun Rupee lọwọ rẹ, ti wọn si tun n beere owo si.

O tumọ si pe owo to padanu ti ju owo oṣu rẹ lọ si ọwọ a\won to fẹ fun loyun

Ṣe nkan ko wa de bayii?

Ṣugbọn Mangesh nikan kọ lo to f'ori ko o lọdọ awọn onijibiti yii.

Igbakeji ọga ọlọpaa, Kalyan Anand, to n dari ẹka to n koju awọn gbajuẹ sọ pe aimọye arakunrin ni wọn ti fi ẹtan gba owo rẹ ni ireti owo tabua lẹyin to ba gba lati ni Ibalopọ pẹlu obinrin to ni iṣoro ọmọ bibi.

O ni ìkọ awọn ti mu awọn ọkunrin mẹrin tawon sí ti gba foonu mẹsan an ati ẹrọ itẹwe lọwọ wọn ti awọn sí n wa awọn mẹrindinlogun mii to na papa bora

Kini ọlọpaa tun sọ?

Sugbọn a ti ri awọn to padanu owo wọn yi ba soro diẹ.

''O ti to ọdun kan tawọn gbajuẹ yi ti n siṣẹ a si gbagbọ pe wọn ti lu ọkẹ aimọye eeyan ni gbajuẹ sugbọn ko si ẹni to yọju sita pe oun ko si wọn lọwọ nitori itiju''

BBC lanfaai lati ba eeyan meji sọrọ ninu awọn to ko sọwọ awọn gbajuẹ yi.

Ọkan sọ pe pe oun padanu 799 rupees ṣugbọn ko sọ ju bẹẹ lọ.

Mangesh lo tiẹ ba wa sọrọ daadaa to si ba wa sọrọ lẹyin ọpọ ipe lori aago, nipa bi oun ṣe ko si ọwọ awọn onijibiti yi.

O ni '' ẹyin iṣẹju mẹwaa ti mo wo fidio ipolowo iṣẹ yi tan ni foonu mi dun.

Arakunrin to ba mi sọrọ ni si ki n san 799 rupees ti mo ba fẹ forukọ silẹ fun iṣẹ yi.''.

Iwe ayederu iwe adehun ọmọ bibi ti wọn gbe le Mangesh lọwọ

Sandeep lorukọ ẹni to ba sọrọ lori foonu to si sọ fun pe yoo maa ba ileeṣẹ kan ṣiṣẹ ni Mumbai.

O fi kun un pe kete to ba ti forukọsilẹ lawọn yoo fi iroyin nipa obinrin ti yoo fun loyun sọwọ sii.

Wọn ni awọn yoo san owo to fẹẹ to owo oṣu rẹ nilọpo mẹta ko kan fi ni ibalopọ pẹlu obinrin ti ko rọmọ bi.

Wọn tun sọ fun un pe obinrin naa ṣeleri lati san 800,000rupees fun to ba file finu ṣoyun.

Mangesh ṣalaye pe iya owo n jẹ oun tori naa lo ṣe jẹ ki oun gba wọn gbọ.

Laarin ọsẹ meji lẹyin ti wọn pade, Mangesh bẹrẹ si ni fowo ranṣẹ si wọn diẹdiẹ titi ti owo naa fi pe ẹgbẹrun lọna mẹrindinlogun rupees,16000.

IO fi gbogbo iwe ẹri ayederu ti wọn gbe le lọwọ.

Lara ọkan ninu iwe yi ni wọn kọ ọrọ ''Iwe adehun ibimọ'' si.

Ọkan lara ẹri ibuwọlu to wa labẹ iwe naa jọ ti gbajugbaja atọkun eto America nii, Oprah Winfrey

Aworan awọn gbajuẹ ti ọwọ ọlọpaa tẹ

Aworan awọn obinrin ni wọn fi de Mangesh mọlẹ

Awọn alaburu yi fi aworan awọn obinrin lorisii de Mangesh mọlẹ ti wọn si ni ko ṣa eleyi to ba wu u lati fun loyun ninu wọn.

Aworan naa to meje si mẹjọ.

''Wọn sọ fun mi pe awọn yoo gba iyara nile itura nilu ti mo wa ti maa si pade obinrin naa nibẹ''

Nigba ti Mangesh ko sinmi lati maa beere owo ti wọn jọ ṣe adehun fun, wọn fi ayederu iwe ẹri kan ranṣẹ si i pe awọn ti san 512,400 rupees sinu akanti rẹ.

Kini ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ naa?

Ọga ọlọpaa to n ṣe iwadii ọrọ yi ni pe awọn gbajuẹ wọnyii pupọ wọn lo kawe daadaa.

O ni wọn mọ ayinike ori foonu daadaa, koda, laptop ati awọn irinṣẹ igbalode mii.

DSP Anand sọ pe amọ awon to n ko si wọn lọwọ jẹ talaka ti ọpọ ko si mọ nipa awọn nkan wọnyii.

Amọ Mangesh sọ pe ko jọ pe gbajuẹ ni wọn fẹ ṣe fun oun titi ti ọjọ fi lọ.

O ni ''ṣe aworan ori DP foonu wọnyi ko jọ tootọ ni?

Abi kii ṣe kaaadii idanimọ to ṣafihan pe ọga ologun ni wọn fi han mi ni?

Ta ni yoo ri ti yoo ro pe irọ ni wọn n pa?''