NSIPA: Ààrẹ Tinubu so ètò ìrànwọ́ fún aráàlú pátá rọ̀,àlàyé réè

Aworan aarẹ Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Iroyin to n tẹwa lọwọ sọ pe aarẹ Naijiria Bola Ahmed Tinubu ti paṣẹ idaduro gbogbo eto iranwọ ti ijọba rẹ n ṣe faraalu Naijiria labẹ akoso ileeṣẹ to n ṣeto wọn taa mọ si National Social Investment Programme Agency (NSIPA).

O ni igbesẹ yi di dandan lati le jẹ ki iwadii tẹsiwaju lori ẹsun magomago ti wọn fi kan awọn adari eto nileeṣẹ yi.

Atẹjade to fìdi ọrọ yi mulẹ tẹwa lọwọ lati ọfisi akọwe ijọba apapọ Naijiria.

Segun Imohiosen to jẹ oludari eto ibanisọrọ ọfisi yi sọ lorukọ akọwe ijọba pe ọsẹ mẹfa ni wọn yoo fi kọkọ so awọn eto mẹrin to wa labẹ akoso ileeṣẹ yi rọ.

Awọn eto naa ni eto N- Power , Conditional Cash Transfer Programme,eto iranwọ owo fun awọn alaini,Government Enterprise and Empowerment Programme, eto iranwọ fawọn ileeṣẹ ati Home school Feeding Programme,eto ipese ounjẹ fawọn akẹkọọ Naijiria.

Atẹjade yi sọ pe Aarẹ Tinubu tun ti kọminu lori ''kudiẹ kudiẹ to wa ninu isakoso awọn eto yi ati aiṣedede to waye nipa sisan owo to yẹ fawọn to yẹ ko jẹ anfaani eto yí"

Aarẹ gbe igbimọ iwadii kalẹ

Aworan Halima Shehu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Halima Shehu

Gbogbo igbesẹ taa n ri lẹka ipese iranwọ faraalu yi bẹrẹ lẹnu ọjọ mẹta yi.

Ko sí sẹyin ẹsun oriṣi to kan awọn alakoso eto wọn yi.

Bi a ko ba gbagbe, laipẹ yi ni wọn ni ki oludari ileeṣẹ NSIPA Halima Shehu kọkọ lọ rọọkun nile ti Efcc si bẹrẹ iwadii lori rẹ to ní ṣe pẹlu ẹsun ṣiṣe owo eto iranwọ kumọkumọ.

Iroyin eleyi ko tii balẹ tan lara araalu ti a tun fi bẹrẹ si ni ri iroyin nipa ẹsun magomago ti wọn fi kan Minisita feto iranwo awọn ti ara n ni, Dr Betta Edu.

Ko tan sibẹ aarẹ Tinubu sọ pe ko lọ rọọkun nile ti Efcc si bẹrẹ si ni f'ọrọ wa lẹnu wo.

Ni bayii tíli aarẹ ti ni kí wọn da awọn eto iranwọ duro ki igbimọ iwadii sí bẹrẹ iṣẹ ìrètí ni pé iyipada yoo waye nibi isakoso awọn eto iranwọ ni Naijiria.

Gẹgẹ bi atẹjade taa ri lati ọfisi akọwe ijọba apapọ ṣe wi, gbogbo eto NSIPA to nise pẹlu owo sisan,eto, ajọṣepọ ati iforukọsilẹ pata ni ìjọba ti so rọ.