Ta ni Betta Edu? Minista ti wọn da duro nitori ẹsun 585.18m

Beta Edu

Latigba ti awuyewuye ti n ja ran-in nipa minista fun eto iboju-aanu wo araalu ni Naijiria, Betta Edu, lori 585.18 to yọ ọ nipo lawọn eeyan ti n sọ oriṣiiriṣii ọrọ nipa rẹ ati ẹni to jẹ gan-an.

Eyi lohun ti a mọ nipa ọdọbinrin oloṣelu naa.

Betta Chimaobim Edu gan-an lorukọ rẹ, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹwaa ọdun 1986 ni wọn bi i nijọba ibilẹAbi, ipinlẹ Cross River.

Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (37) ni bayii.

O di oṣu kẹwaa ọdun yii ko too pe 38.

Ọdun 2001 lo pari ileewe Girama Federal Government Girl’s College,Calabar.

Yunifasiti Calabar lo ti kẹkọọ gboye ninu iṣegun oyinbo ati iṣẹ abẹ (Medicine and Surgery) lọdun-un 2009.

Betta Edu tun tẹsiwaju nipa gbigba iwe-ẹri Diploma ni London School of Hygiene& Tropical Medicine.

O gba ti dokita olutọju awujọ (Doctor of Public Health) ni Yunifasiti Texila, l’Amẹrika.

tAwọn ipo oṣelu ti Betta Edu ti di mu ri

Beta

Ni 2015, Beta Edu ni ọdọ to kere ju ti wọn yan sipo Oludamọran pataki fun gomina lori eto ilera alabọọde. Gomina Benedict Ayade ti Cross River lo yan an nigba naa

Ni 2020, o di alaga to n ri si ọrọ Korona ni Cross River.

*Olori awọn obinrin ẹgbẹ oṣelu APC lapapọ (APC National Women Leader). Osu kẹta ọdun 2022 titi di oṣu kẹjọ 2023 lo fi dipo naa mu.

*Kọmiṣanna feto ilera ipinlẹ Cross River Oṣu kejila, ọdun 2019 titi di oṣu kẹta 2002 to kọwe fipo naa silẹ.

*Alaga apapọ fawọn kọmiṣanna eto ilera ni Naijiria.

*Minista fun eto iboju-aanu wo araalu ati lile-̀iṣẹ́ wọgbẹ. Ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹjọ, 2023 lo gba ipo naa, kijọba too da a duro lọjọ kẹjọ oṣu kin-in-ni ọdun 2024.

Awuyewuye to ti koju Betta Edu ri

Ni 2020, lasiko ti Korona gbode, ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria, ẹka tipinlẹ Cross River, fẹsun kan Beta Edu pe o ṣafihan ayederu afẹfẹ eemi (Ventilator) lori ayelujara.

Ẹgbẹ naa sọ pe awọn ko nigbagbọ ninu Beta mọ pẹlu iwa ailootọ rẹ.

Ṣugbọn obinrin naa sọ pe awọn ọta ilọsiwaju ninu oṣelu lo wa nidii ibajẹ oun.

Ni 2022, wọn tun fẹsun kan Beta pe iwa rẹ tabuku ipo olori awọn obinrin APC to n dije fun nigba.

Ni 2024, Beta Edu bẹrẹ ẹsun lori 585M ti wọn lo ni ki wọn san sakanti ti ki i ṣe tileeṣẹ to n bojuto. Eyi to fa idaduro rẹ bayii.

tAwọn ami ẹyẹ ti Betta Edu ti gba

Beta Edu

Oríṣun àwòrán, google

*Obinrin to ṣee wo awokọṣe rẹ ni Naijiria Nigeria Quintessential Woman Award (2020).

Ami ẹyẹ iperegede ( Award of Excellence) (2020).

Dokita to peregede julọ ni 2020 (Medical Expert of the year 2020.

Ami ẹyẹ eni to n ko awọn obinrin mọra (2023).