Òní ni ọdún àfihàn gbogbo òrìṣà Yorùbá ni ìlú Quidal ní Benin Republic bẹ̀rẹ̀

Aworan awon eeyan Benin Republic

Ọdun gbogbo oriṣa niluu Quidal lorilẹede Benin Republic ti gberasọ lonii ọjọ Isẹgun, ọjọ kẹsan an oṣu Kinni ọdun yii.

Ọdun naa yoo waye fun ọjọ meji lati ọjọ Isẹgun si Ọjọru tii ṣe ọjọ Kẹwaa oṣu Kinni yii.

Koda, ijọba aarẹ Patrice Talon orilẹede Benin Republic gan an ti kede atilẹyin rẹ fun ọdun ọhun.

Ijọba aarẹ Talou ni igbagbọ pe irufẹ igbelarugẹ aṣa bayii dara fawọn ọmọ orilẹ ede Benin at'awọn arinrinajo afẹ lati maa wo.

Gẹgẹ bi ọrọ ti minisita aṣa ati irinajo igbafẹ orilẹ ede Benin Republic, Jean-Michel Abimbola ṣe sọ, ọdun gbogbo oriṣa ti wọn n pe ni Vodun yoo jẹ ki ọpọ eeyan wa ṣe abẹwo si Benin Republic.

Ilu Quidal jẹ ilu kan t'awọn eeyan ibẹ maa n ṣe igbelarugẹ oniruuru aṣa Yoruba bi egungun gbigbe jade.

Ilu Quidal yii ni gbogbo itan orilẹede Benin Republic wa.

Iroyin fìdí rẹ múlẹ pe gbogbo awọn nkan iṣẹnbaye t'awọn oyinbo ti ko lọ soke okun ni Aarẹ Talou ti gba pada ti o si gbe lọ si ilu Quidal bayii.

Gbogbo awọn oriṣa bii Obatala, Ṣango, Igunnu ati bẹẹ bẹẹ lọ ni yoo jade lati pitu ọwọ wọn nibi ajọdun yii.

Fun àpẹẹrẹ, awon onifa yoo ṣe akanṣe Ifa Dida fun gbogbo eeyan lati ri nibi ọdun yii.

Gbogbo awọn l'ọba l'ọba lo ti wa ni ikalẹ fun ọdun yii.