Tírélà kọlu ọkọ̀ akérò ni Kwara, èèyàn mẹ́wàá kú, mẹ́wàá míì farapa yánnayànna

Beeyan ba jori ahun, bo ba ri bi ẹran awọn eeyan kan ṣe ja wẹlẹwẹlẹ, to si ri bawọn oṣiṣẹ alaabo ojupopo, ‘Federal Road Safety Corps’ (FRSC) ṣe n fa oku awọn kan yọ labẹ mọto, ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ to waye naa yoo bomi loju.
Ijamba naa sẹlẹ laaarọ kutukutu ọjọ Aje, Monde, ọjọ kẹjọ, oṣu Kin-in-ni yii, lagbegbe Iyemọja, Oko-Olowo, n'ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ni nnkan bii aago mẹfa owurọ.
BBC Yoruba gbọ pe mọto akero Toyota Hiace kan ati tirela Volvo kan lo rọ lu rawọn, lo ba di gbamu. Awọn kan farapa yannayanna bẹẹ si ni awọn kan jade laye loju ẹsẹ.
Gbogbo awọn ero to farapa ninu ijamba naa pata ni wọn ti ko lọ sileewosan tijọba Jẹnẹra to wa niluu Ilọrin, nigba tiwọn tun ko gbogbo awọn to padanu ẹmi wọn lọ si mọṣuari ileewosan yii kan naa.
Lara awọn o soju mi koro, to ni ka fi orukọ bo oun laṣiri to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe, ‘‘O ṣe ni laaanu pe awọn eeyan mẹwaa ni wọn ku ti mẹwaa miiran si farapa yannayanna sinu ijamba ọkọ kan to waye ni nnkan bii aago mẹfa aarọ ọjọ Aje, Monde, ọsẹ yii, lagbegbe Iyemọja Oko-Olowo, Ilọrin ipinlẹ Kwara".
O ni iwadii fi han pe ere buruku ti ọkan lara awọn dẹrẹba ọkọ meji ọhun n sa bọ lo ṣokunfa iṣẹle naa.
Ọkunrin mẹẹdogun, obinrin mẹrin ati ọmọ kekere kan lo wa ninu ọkọ ọhun, mẹwaa fara pa gidi ninu iṣẹlẹ naa, nigba tawọn ọkunrin marun-un, obinrin mẹrin ati ọmọ kekere kan ku lasiko ijamba yii.
"Lasiko ti dẹrẹba ọkọ tirela naa n sare lo lọọ kọ lu ọkọ akero naa, to si fa ki ọpọ ẹmi ṣofo báyìí" .
O ni, wọn ti ko gbogbo awọn to farapa lọ si ileewosan Jẹnẹra tiluu Ilọrin, fun itọju nigba ti wọn ko awọn oku lọ si mọsuari ileewosan yii kan naa.
Alukoro ajọ FRSC nipinlẹ Kwara, Ọlayinka Basambo, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
O ni ọkọ akero ọhun lo n lọ lati ilu Eko lọ si Sokoto ti tirela naa si nbọ lati oke Ọya lọ si Eko.
O fi kun un pe, ajọ FRSC nipinlẹ Kwara yoo ma sa ipa wọn lati dẹkun ijamba ọkọ ni ipinlẹ naa.













