Ààrẹ Tinubu pàṣẹ kí Mínísítà Betta Edu lọ rọ́ọ́kún nílé lórí ẹ̀sùn màgòmágó ₦550m

Oríṣun àwòrán, BBC
Aarẹ orileede Naijiria Bola Tinubu ti pa lasẹ pe ki Minisita feto iboju aanu wo araalu,Dr Betta Edu lọ rọọkun nile titi ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.
Agbẹnusọ aarẹ Ajuri Ngelale lo fi ọrọ yi sita lorukọ aarẹ ninu atẹjade kan lọjọ Aje.
O ni aarẹ gbe igbesẹ yi ki ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra Efcc le ṣe iwadii ẹkunrẹrẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an yi.
Minisita Betta Edu sọ pe oun ko lọwọ ninu makaruru kankan ati pe awọn to fẹ ba orukọ oun jẹ lo wa nidi ọrọ yi.
Jakejado Naijiria ni ariwo ti pọ lori ẹsun yi t'awọn eeyan si ti n foju sọna lati mọ igbesẹ ti ààrẹ fẹ gbe lori ọrọ yi.
Ẹsun ti wọn fi kan Minisita naa da lori fifi ọna ti lodi si ofin f'asẹ si sisan owó sinu akoto ọlọdani.
Iye owo naa si jẹ ₦585.189m ti wọn ni Minisita Betty Edu san sinu akoto owo Bridget Mojisola Oniyelu kan.
Lati ilẹ naa ni awọn araalu ti n sọ pe ohun tó tọ ni ki aarẹ pàṣẹ ki Minisita rẹ yẹra si ẹgbẹ kan ki iwadii to poju owo baa le waye.
Idanwo lati mọ boya aarẹ faaye gba ajẹbanu lo de yi
Awọn onwoye Naijiria ri ìṣẹlẹ ẹsun ti wọn fi kan Minisita yi gẹgẹ bi idanwo lati le mọ iru iha ti ijọba aarẹ Bola Tinubu kọ si ajẹbanu.
Ati alatako ati ẹni ti ko tiẹ jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu lo n fi ọkan ba ìṣẹlẹ bọ lati le mọ ibi ti yoo kangu si.
Farouk Kperogi to jẹ afi gege dara ati onwoye ti sọ ni nkan bi ọjọ meloo kan sẹyin pe ko ni jẹ nkan daada ti aarẹ Tinubu ko ba gba iṣẹ lọwọ Dr Betta Edu.
Loju opo Twitter X lo fi ọrọ yi si.

Oríṣun àwòrán, @farookkperogi
Minisita to fipo silẹ ṣaaju Betta Edu naa yọju si Efcc

Oríṣun àwòrán, @Sadiya_farouq/XCopyright
Lọjọ Aje kan ṣoṣo ti atẹjade wa lati ọdọ aarẹ Tinubu naa ni Minisita to di ipo ti Dr Betta Edu wa lori rẹ tẹlẹ Sadiya Farouq yọju si ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra Efcc.
Labẹ ijọba aarẹ Muhammadu Buhari ni Sadiya Farouq ti di ipo kanna ti Edu wa lori rẹ mu.
Loju opo rẹ Sadiya Farouq sọ pe oun finu fẹdọ lọ sọdọ Efcc ni lati lọ dahun ibeere lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Lọsẹ to kọja ni ajọ Efcc kọwe pe Sadiya si ọọfisi wọn to si kọ lati yoju.
Ẹsun ti wọn ni ko wa yanju da lori ajẹbanu aimọye biliọnu Náírà owo ti ijọba ni ki wọn fi mu irọrun ba araalu to wà nipo ìnira kan tabi omiran labẹ ijọba to kọja.
Minisita tẹlẹ rí yi ko oriṣi awawi kalẹ titi ti Efcc fi fohun sílẹ pe ti ko ba yọjú laarin ọjọ mẹta awọn yoo kede orúkọ gẹgẹ bi ọkan lara awọn to sa mọ agbofinro lọwọ.












