Ohun tí a mọ̀ nípa fíforúkọ́sílẹ̀ fún ìwé ìrìnnà lórí ayélujára tí yóò bẹ̀rẹ̀ lónìí rèé

Oríṣun àwòrán, Others
Minisita fun ọrọ abẹle, Olubummi Tunji Ojo yoo se ifilọlẹ opo ayelujara akọkọ fun ifiorukọsilẹ fun iwe irinna lori ayelujara.
O ni ọjọ Aje, Ọjọ keje, oṣu kinni, ọdun 2024 ni ifilọlẹ naa yoo waye niluu Abuja.
O sọ eyi lasiko to n ṣe ayẹwo opo ayelujara naa pẹlu Ọga agba fun ajọ irinna lorilẹede Naijiria, Caroline Adepoju.
Gẹgẹ bii Tunji ṣe ti salaye, iwe irinna ori ayelujara lo wa fun awọn to ba fẹ fi orukọ silẹ ni orilẹede Naijiria ati loke okun.
Saaju ni Minisita tí kede pe ninu oṣu Kejila ọdun 2023 pe ìjọba apapọ n sisẹ lati ri pe ori ayelujara ni ọpọ yoo ti ma ṣe iforúkọ fun iwe irinna wọn lorilẹede Naijiria
Tunji salaye pe awọn to ba forukọ silẹ fun iwe irinna oni iwe mejilelọgbọn tí yoo lo fun ọdun mẹwaa yoo san ẹgbẹrun mẹdọgbọn naira, ti awọn to nifẹ si iwe irinna mẹrinlelọgọfa fun ọdun mẹwaa yoo san ẹgbẹrun aadọrun naira.
Bakan naa ni awọn to ba fẹ forukọ silẹ lati oke okun fun iwe irinna oni iwe mejilelọgbọn yoo san $130 ọwọ dọla ti awọn to nifẹ si iwe irinna oni ọdun mẹwaa yoo san oni ọwọ dọla $230.
Oju opo ayelujara ti awọn eeyan yoo ti ni anfani lati forúkọ silẹ ni https://passport.immigration.gov.ng















