Bílíọ̀nù lọ́nà ọgbọ̀n náírà(N30bn) làwọn aṣòfin fẹ́ẹ́ fi tún ilé ìgbìmọ̀ wọn ṣe

Oríṣun àwòrán, National Assembly Abuja/Facebook
Ko din ni biliọnu lọna ọgbọn naira (30b)mi-in ti ile igbimọ aṣofin apapọ Naijiria ti ya sọtọ bayii gẹgẹ bi afikun owo ti wọn yoo fi tun ile igbimọ wọn ṣe.
Ninu aba eto iṣuna owo ọdun 2024 yii ni afikun owo naa wa.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, biliọnu lọna ọgbọn naira yii wa lara 344. 85bn ti wọn ya sọtọ fun ile igbimọ yii, lẹyin ti wọn gbe e kuro ni N197.93bn to wa tẹlẹ.
Ọjọ akọkọ ninu ọdun 2024 ni Aarẹ Bọla Tinubu buwọ lu owo yii, oun si ni owo to pọju tile igbimọ kankan ti gba ri.
Pẹlu afikun owo yii, o ti di biliọnu lọna ọgọta naira (N60bn) ti wọn yoo fi tun ile igbimọ aṣofin Naijiria ṣe.
Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba, Godswill Akpabio, ti sọ lọdun to kọja, pe atunṣe ṣi n ba gbogbo ile igbimọ aṣofin yii lọwọ, nitori awọn nnkan to nilo atunṣe nibẹ.
O ni afi bi wọn ba pari rẹ tan pata, ti Aarẹ Bọla Tinubu si waa ba awọn ṣi i.
Ọdun to kọja ni wọn fẹẹ pari rẹ tẹlẹ, ṣugbọn iṣẹ ọhun ṣi n lọ lọwọ titi dasiko yii.














