Nitori Kọlẹra to n pa awọn eeyan nigboro, Aarẹ Zambia ni ki wọn kọri sabule

ZAMBIA

Oríṣun àwòrán, ZAMBIA PRESIDENCY FACEBOOK

Arun Onigbameji toyinbo n pe ni Kọlẹra ti pa to ọọdunrun eeyan (300) lorilẹ-ede Zambia bayii, eyi lo si fa a ti Aarẹ wọn, Hakainde Hichilema, ṣe ni yoo da bi awọn kan ba le fi igboro silẹ, ti wọn gba abule lọ.

L’Ọjọruu ọsẹ yii ni Aarẹ Hichilema ṣabẹwo sibudo itọju awọn alaisan naa ti i ṣe Heroes Stadium Cholera Treatment Centre.

Eeyan to le lẹgbẹrun kan ni wọn n gbatọju lọwọ nibẹ ni Lusaka, olu ilu Zambia.

Nibẹ ni Aarẹ ti sọ pe, ‘’ Awọn ọdọ kan fẹsẹ gbalẹ wa sigboro lai si nnkan pato ti wọn fẹẹ waa ṣe, eyi to fi yẹ ki wọn lọọ mulẹ loko ki wọn maa dako lọ bii rẹrẹ.

" Ilẹ pọ rẹpẹtẹ labule, omi to mọ geere wa nibẹ.

A le kọle to daa s’abule, nibi ti ero ko ti pọ rẹpẹtẹ bii tigboro’’

Aarẹ Mozambique ko ṣai sọ pe ijọba yoo nilati gbe awọn igbesẹ kan ti yoo lagbara diẹ lati koju iṣoro omi to mọ ti ko si, to n fa iṣoro arun Onigbameji.

O ni ijọba yoo tun awọn agbegbe ti ko bojumu ṣe, wọn yoo si gbegi dina itankalẹ awọn agbegbe to dọti.

O fi kun un pe aini imọtoto lo n fa kọlẹra to n bẹ silẹ lawọn agbegbe to laju, bi wọn yoo ba si din apọju ero ku, afi kawọn kan gba abule lọ gẹgẹ bo ṣe sọ.

Omi ti ko mọ abi ounjẹ ti wahala kan ti wa ninu ẹ lo n fa aisan Onigba meji

HHICHILEMA

Igbọnsẹ gbuuru ati eebi ni apẹẹrẹ tẹni to n ba ja yoo maa ri.

Bi wọn ko ba tete kapa ẹ, ẹni ti Kọlẹra mu le dero ọrun alakeji laarin wakati perete.