"Òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ni T.B. Joshua, èyí ó wù ẹ wí," èrò ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ìròyìn BBC

Aworan TB Joshua

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lati ọjọ Aje ọjọ kẹjọ oṣu Kini ọdun yii ti BBC ti gbe iṣẹ iwadii ti wọn ṣe lori oludasilẹ ile ìjọsìn Synagogue Church of All Nations(SCOAN), pasitọ T.B. Joshua to ti di oloogbe, l'awọn eeyan ti n sọ ero wọn nipa iroyin naa.

Ogunlọgọ awọn ọmọ ile ijọsin Synagogue Church of All Nations tẹlẹ rí - Ọmọ ilẹ Gẹẹsi marun un - fi awọn ẹsun bí ifipanilopọ ati fifi tipa tipa ṣẹ oyun kan Olusọ aguntan to ti di oloogbe TB Joshua lati orilẹ-ede Naijiria.

Ero awọn eeyan ṣe ọtọọtọ lori iroyin ọhun eyi t'awọn ọmọ ijọ SCOAN tẹlẹ ti fẹsun kan pasitọ naa pe o fipa bawọn lopọ, o si tun ṣẹ oyun fawọn.

Awọn mii sọ pe T.B. Joshua huwa ipa s'awọn, bakan naa l'awọn kan ninu awọn ọmọ ijọ rẹ tẹlẹ sọ pe o lu awọn bii kuku bii yiye.

Ọpọ eeyan to ka iroyin naa lori ikanni BBC Yoruba lo sọ pe o yẹ kí BBC ti gbe iroyin yii jade nigba ti T.B. Joshua wa laye.

Ero wọn ni pe TB Joshua ko lanfaani lati sọ ti ẹnu rẹ mọ bayii lori gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an tori o ti wa ni isalẹ ilẹ.

Awọn kan tiẹ sọ pe ibanilorukọjẹ ni iroyin naa jẹ tori eeyan Ọlọrun ni TB Joshua jẹ.

Awọn mii tiẹ sọ pe irọ ni wọn pa mọ TB Joshua.

Ola Johnson to jẹ ọkan lara awọn to ka iroyin naa loju opo Facebook BBC Yoruba ni "ojiṣẹ Ọlọrun tootọ ni TB Joshua jẹ, eyi owu ẹ kan n ba a lorukọ jẹ ni.

Eyi kii ṣe tuntun, ẹ jẹ ki Olorun da onikaluku lẹjọ."

Aworan ero omo Naijiria
Aworan ero omo Naijiria
Aworan ero omo Naijiria
Aworan ero omo Naijiria

Bakan naa ni awọn kan gbagbọ pe ko si iyatọ ninu ki BBC gbe iwadii wọn lori TB Joshua jade yala nigba to wa laaye tabi lẹyin iku rẹ.

Olaniyi Omotoso sọ ni tiẹ pe TB Joshua lo agbara to ni nigba aye rẹ lati yọ oniroyin ileeṣẹ refio FRCN n'isẹ niluu Ibadan.

Ti ẹ o ba gbagbe gbajugbaja sọrọsọrọ, Kolawole Olawuyi ṣe eto kan to lamilaaka lori TB Joshua nile iṣẹ redio ọhun.

Aworan ero omo Naijiria
Aworan ero omo Naijiria