Mínístà tẹ́lẹ̀ rí yìí yóò fojú ba ilé ẹjọ́ fẹ́sùn ìpànìyàn àti ìfipábánilòpọ̀

Oríṣun àwòrán, EPA
Eto ti to bayii fun minista tẹlẹ fun ọrọ abẹle lorilẹ-ede Gambia, Ousman Sonko, lati foju bale-ẹjọ lorilẹ-ede Swizerland, lori awọn ẹsun to tako iwa ọmọniyan.
Sonko ni wọn fẹsun kan pe o lọwọ ninu awọn iwa bii ipaniyan, ifipabanilopọ ati ifiyajẹni.
Ọdun 2016 ni minista tẹlẹ naa sa kuro ni Gambia, to lọ si Swizerland nigba to ku diẹ ki agbara bọ lọwọ aarẹ Gambia igba naa, Yahyah Jammeh.
Iṣakoso Jammeh naa ko fun awọn araalu lominira bi akọsilẹ ṣe sọ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ajọ kan ti ki i ṣe tijọba lo fẹsun kan Sonko ti wọn si ko ẹri kalẹ, sibẹ, lọọya rẹ sọ pe ọkunrin naa kọ lọwọ ninu awọn ẹsun ọhun.
Orilẹ-ede Swizerland to fẹẹ gbọ ẹjọ naa bayii fẹẹ ṣe bẹẹ labẹ ofin to faaye gba awọn orilẹ-ede lati foju olujẹjọ ba kootu, koda bi ko ba jẹ ilu rẹ nigbẹjọ naa yoo ti waye.
Ireti awọn ajafẹtọọ ọmọniyan lori ẹjọ Sonko ni pe yoo jẹ ẹkọ fawọn alagbara ti wọn n jẹ ayekaye.
Wọn ni yoo jẹ ki wọn mọ pe ko sibi tọwọ ofin ko de.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, awọn oluwadii lati Swiss ṣiṣẹ otẹlẹmuyẹ lori ẹsun ti wọn fi kan Sonko.
Wọn ba ọpọ eeyan ti wọn kagbako ibasun, ifiyajẹni ati bẹẹ bẹẹ lọ lọwọ rẹ sọrọ, mẹsan-an ninu wọn ni yoo si jẹrii takoo ni kootu bi wọn ṣe sọ.
Sonko ni Ọlọwọ-ọtun aarẹ Yahya Jammeh lasiko iṣakoso wọn

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọgbẹni Sonko ni ọlọwọ-ọtun aarẹ Yahya Jammeh lasiko iṣakoso wọn ni Gambia, lati1996 de 2016.
Akọsilẹ awọn ajafẹtọọ ọmọniyan nipa Yahya ni pe iṣakoso rẹ faaye gba iwakiwa oriṣiiriṣii bii kawọn eeyan deede di awati.
Ipaniyan lai jẹ pe ile-ẹjọ dajọ iku fun wọn ( Extra judicial killings) ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọgbẹni Meystre, ọkan lara awọn ajafẹtọọ ọmọniyan to n gbọ ẹjọ Sonko yii, sọ pe inu awọn eeyan to jiya lọwọ minista tẹlẹ naa yoo dun, bi wọn ba ri idajọ ododo ti wọn ti n reti tipẹ.














