Ajínigbé ń bèèrè 50m lóríi Alàgbà ìjọ Ridiimu tí wọ́n jí gbé l’Ógùn

Owo ti ko din ni aadọta miliọnu naira (50m) ni awọn ajinigbe to ji baba agba ẹni aadọrin ọdun, Alagba Adeifẹ Ifẹlaja, gbe n beere bayii ki wọn too le fi i silẹ lominira.
Alagba ni Baba Adeifẹ ninu ijọ Irapada RCCG kan n’Ijẹbu-Igbo, ipinlẹ Ogun. Ọsin ẹlẹdẹ si ni iṣẹ rẹ to n ṣe.
Gẹgẹ bi ọkan ninu awọn eeyan baba naa ti ko fẹ ka darukọ oun ṣe ṣalaye, o ni alẹ ọjọ Aiku ti 2023 pari (December 31, 2023) ni awọn ajinigbe ji Alagba Adeifẹ gbe nile rẹ, n’Ijẹbu-Igbo lasiko ti baba naa n mura lati maa lọ sibi ijọsin irekọja wọ inu ọdun tuntun.
‘’Miliọnu lọna aadọta naira ni wọn ni ka mu wa kawọn too fi baba wa silẹ.
Mo gbọ pe wọn ti n dunaa-dura ṣaa, pe o ṣee ṣe ko ma ju miliọnu mẹwaa lọ ta o pada san’’
Bẹẹ ni ọkunrin to ni ka ma darukọ oun naa ṣalaye.
Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun fidi iṣẹlẹ naa mulẹ

Oríṣun àwòrán, google
Kini olopaa Ogun n sọ?
Ọga ọlọpaa Ogun, CP Abiọdun Alamutu to fidi iṣẹlẹ ijinigbe naa mulẹ, sọ pe gbogbo ipa lawọn n sa lati ri i pe baba jade lahaamọ ajinigbe.
‘’Ni tododo, ọlọpaa n gbiyanju lati ri i pe wọn tu baba silẹ.
‘’Awọn ajinigbe yẹn tiẹ fẹẹ da nnkan ru mọ wa loju nigba ti wọn n parọ ibi ti wọn wa fun wa, ṣugbọn a ṣi n dọdẹ wọn. A maa ṣaṣeyọri lori ẹ laipẹ’’
Titi dasiko ta a pari iroyin yii, Alagba Adeifẹ Ifẹlaja ṣi wa lakata awọn ajinigbe.














