A ti tú gbogbo oríkò Hamas tó wà ní àríwá Gaza ká - Israel

Àwọn ibi tí àdó olóró ti bàjẹ́ ní Gaza

Oríṣun àwòrán, Reuters

Iléeṣẹ́ ológun orílẹ̀ èdè Israel ni àwọn ti ba gbogbo ibùdó ikọ̀ Hamas tó wà ní àríwá Gaza jẹ́ pátápátá.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ológun Israel, Daniel Hagari sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé àwọn alákatakítí Palestine ni wọ́n ń ṣọṣẹ́ láì ní ibùdó tàbí olórí kan báyìí.

Ó ní àwọn agbéṣùmọ̀mí tí iye wọn tó bí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ti àwọn ti pa ní ẹkùn àríwá Gaza àmọ́ BBC kò lè fìdí èyí múlẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé nǹkan tí àwọn ṣe báyìí ni láti tú àwọn alákatakítí Hamas ká ní gúúsù àti ààrin gbùgùn Gaza.

Orílẹ̀ èdè Israel ti ṣekúpa ènìyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ní Palestine láti ìgbà tí ogun ti bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Keje, oṣù Kẹwàá ọdún 2023 gẹ́gẹ́ bí ohun tí iléeṣẹ́ ètò ìlera tí Hamas ń tukọ̀ rẹ̀ ṣe wí.

Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Keje, oṣù Kìíní ọdún 2024 ni iléeṣẹ́ náà tún ṣàlàyé pé ènìyàn 113 ló tún pàdánù ẹ̀mí láàárín ọjọ́ kan.

Láti ìgbà tí ogun ti bẹ̀rẹ̀ láàárín Israel àti Hamas ni ẹkùn Gaza kò ti rí imú mí mọ́, tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó lé ní mílíọ̀nù méjì tó ń gbé agbègbè náà ti di aláìnílé lórí mọ́.

Israel bẹ̀rẹ̀ ogun pẹ̀lú Hamas lẹ́yìn tí ikọ̀ náà ju àdó olóró sí gúúsù Israel níbi tí ènìyàn tó lé ní ẹgbẹ̀fà (1,200), tí ọ̀pọ̀ wọn jẹ́ ará ìlú ti pàdánù ẹ̀mí wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bákan náà ni Hamas tún jí àwọn ènìyàn tó lé ní 240 tó jẹ́ ọmọ Israel gbé tí wọ́n sì fi wọ́n sí àhámọ́.

Àwọn ènìyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún ló ṣì wà ní àhámọ́ Hamas lẹ́yìn tí wọ́n tú àwọn kan sílẹ̀ nígbà tí àwọn ikọ̀ méjéèjì fẹnukò láti dáwọ́ ogun dúró fún ọjọ́ mẹ́fà nínú oṣù Kọkànlá.

Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, akọ̀wé ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Antony Blinken ní òun ń bẹ̀rù kí ogun náà má tàn ju bí ó ṣe yẹ lọ lkyìn tí Hezbollah ju àdó olóró sí Israel látàrí àti gbẹ̀san bí Israel ṣe pa adarí ikọ̀ Hamas kan sí Beirut lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun tó kọjá.

Ní orílẹ̀ èdè Greece ni Blinken ti sọ̀rọ̀ náà lásìkò àbẹ̀wò rẹ̀ sí ẹkùn ìlà oòrùn. Lẹ́yìn náà ló gbéra lọ sí Jordan níbi tó ti ṣèpàdé pẹ̀lú Ọba Abdullah kó tọ mórílé Qatar.

Ọba Abdullah sọ fún Blinken pé Amẹ́ríkà nílò láti bá Israel sọ̀rọ̀ kí wọ́n fòpin sí ogun tí wọ́n ń kó ja Gaza nítorí àbọ̀ ogun yìí kò ní dára rárá.

Olóòtú ìjọba Israel, Benjamin Netanyahu lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní Israel kò ní sinmi àyàfi tí àwọn bá pa ikọ̀ Hamas rẹ́ pátápátá, tí àwọn gba gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè àwọn tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀ àti tí àwọn bá ri dájú pé Gaza kò jẹ́ ohun ìbẹ̀rù fún àwọn mọ́.

“A ní láti fi gbogbo nǹkan sí ẹ̀gbẹ́ ná... ó dìgbà tí a bá borí,” Netanyahu sọ nínú àtẹ̀jáde kan.

Nínú ìròyìn míì, ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ìròyìn Al Jazeera tẹ̀ka Gaza, Wael al-Dahdouh ti pàdánù àkọ́bí ọmọkùnrin rẹ̀, Hamza al-Dahdouh àti akọ̀ròyìn mìíràn, Mustafa Thuraya sínú ìkọlù Israel ní gúúsù Gaza.