Iléẹjọ́ ní kí Bàbá àti ọmọ rẹ ọkùnrin lọ máa gba atẹ́gùn lọ́gbà ẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn fífi tipátipá bá ọmọ obìnrin rẹ̀ lòpọ̀

aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ileẹjọ mọlẹbi to n jokoo niluu Ibadan ti pasẹ pe ki Michael Ayinde, ẹni ọdun mọkanlelaadọta ati ọmọ rẹ ọkunrin, Abiola, ẹni ọdun mọkandinlogun lọ ma gba atẹgun lọgba

Ẹsun pe o fipa ba ọmọ rẹ obìnrin ni wọn fi kan Baba, tí ọmọ rẹ ọkùnrin naa si fipa ba ọmọ iya ati baba rẹ ni ajọsepọ niluu Ibadan.

Nigba to n gbe sọrọ, Adajọ Magistrate, O. O. Ogunkanmi kọ lati gba ẹbẹ awọn afurasi naa, to si pa lasẹ pe ki awọn afurasi naa lọ maa gba atẹgun lọgba ẹwọn Abolongo niluu Oyo.

Awọn afurasi mejeeji, Baba ati ọmọ ni wọn fẹsun kan pe wọn wu iwa yii ni ile wọn ni agbegbe Agboti Osan ni Alakia niluu Ibadan.

Ogunkanmi ni fífi Baba ati ọmọ si ahamọ yoo fun ileẹjọ ni anfani lati duro fun imọran lati ọwọ ajọ DPP nípinlẹ Oyo.

O wa sun Igbẹjọ naa si ọjọ kọkanlelogun oṣu kejì.

Ọlọpaa to ṣe iwadi ẹsun naa, Gbemisola Adedeji sọ fun ileẹjọ pe lati odun 2021 si ọdun 2023 ni Abiola Ayinde to jẹ ẹgbọn si ọmọ bìnrin, ẹni ọdun mẹtadinlogun to jẹ aburo rẹ lopọ ni tipatipa.

Adedeji ni Abiola tun fun aburo rẹ loyun, ti Baba wọn naa, Michael na n fi tipa tipa ba ọmọ naa lopọ.