Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Kwara fún ìjọba ní gbèdéke ọjọ́ mẹ́rìnla

Oríṣun àwòrán, NLC
Ẹgbẹ osisẹ Ipinlẹ Kwara fun ijọba Kwara ni gbedeke ọjọ merinla lati dahun gbogbo ibeere won tabi ki wọn bẹrẹ iyanselodi.
Ipinu ẹgbẹ osisẹ naa waye ni ibi ipade igbimọ alasẹ ẹgbẹ osisẹ (NLC) ati (TUC) ni olu Ile ẹgbẹ osisẹ Ipinle Kwara to wa ladugbo lajọrin Ilorin olu Ilu ipinle Kwara.
Egbe osise Ipinle ọhun ni awọn fun ijọba ni gbedeke ọjọ mẹrin ati pe ti ijọba ko ba da awọn lohun leyin gbedeke ọjọ mẹrinla yii, awon yoo yoo bẹrẹ iyanselodi.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo BBC Yoruba pẹlu akowe ẹgbẹ osise Ile ise Radio, ona, ati asa ni ipinle Kwara, RATAWU, Comrade Yusuf Mubarak to jẹ ọkan lara awọn adari ẹgbẹ osisẹ ni Kwara sọ pe ipinu naa o sẹyin awon ibere awon
Mubarak ni o pọn dandan ki ijọba ṣamuṣẹ gbogbo adehun ti wọn ba ẹgbẹ òṣìṣẹ́ ṣe ti wọn ko ba fẹ ri pipọn ojú àwọn òṣìṣẹ́.
Ẹ o ranti pe ninu oṣù kejìlá ọdun 2023 ni àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ rédíò àti telifisan gunle ìyanṣẹ́lódì onikilọ lati fi pe àkíyèsí ijọba si awon ìbéèrè wọn.
Lara awọn nǹkan ti awọn òṣìṣẹ́ ń bèèrè fún ni alekun owó oṣù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.











